Ìṣẹ̀-Èkìtì

(Àtúnjúwe láti Ise-Ekiti)

Ise-Ekiti

Ìṣẹ̀-Èkìtì
Country Nigeria
StateEkiti State

Iṣẹ́ yìí dá lórí àyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka-èdè tí à ń sọ ní ìpínlẹ̀ Èkìtì. Láti ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ yìí, tíọ́rì onídàrọ́ ni a lò. Ìpín mẹ́rin ni a pín iṣẹ́ yìí sí. Ní orí kìn-ín-ní ni a ti sọ ìtàn orírun Ìṣẹ̀-Èkìtì. A sọ èrèdí iṣẹ́ yìí, ọgbọ́n ìwádìí tí a lò àti àyẹ̀wò iṣẹ́ tí ó wà nílẹ̀. Bákan náà, a sọ tíọ́rì tí a lò fún iṣẹ́ yìí.

Ní orí kejì ni a ti ṣe àlàyé lórí àwọn ìró inú ẹ̀ka-èdè ìṣẹ̀-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. Bíi ìró kónsónáǹtì, ìró fáwẹ́lì, ìró ohùn, iṣẹ́ ohùn, sílébù àti oríṣiríṣi. sílébù tí a lè rí nínú ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. Ní orí kẹ́ta àpilẹ̀ko yìí ni a ti ṣàyẹ̀wo nípa ìgbésẹ̣̀ fonọ́lọ́jì tí ó wà nínú ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. A wo ìpàrójẹ, àrànmọ́ àti àǹkóò fáwẹ́lì.

Ní orí kẹ́rin iṣẹ́ yìí ni a ti gbìyànjú láti wo àwọn ìyàtọ̀ àti ìjọra tí ó wà láàrin fonọ́lọ́ji ẹ̀ka-èdè Ìsè-Èkìtì àti ti olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Àgbálọgbábọ̀ iṣẹ́ yìí dá lé àwọn tuntun tí ó jáde nínú ìwádìí ti a ṣe a si tọ́ka sí àwọn ibi tí a lérò pé iṣẹ́ kù sí.

  • M.G. Fátóyè, (2003), Àyèwò Fónolojì Ẹ̀ka Èdè Ìsè Èkìtì.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria.