Ivie Okujaye
Ivie Okujaye (tí a bí ní Ọjọ́ kẹrìndínlógún Oṣù kaàrún Ọdún 1987) jẹ́ òṣèré orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, olùgbéréjáde, ònkọ̀wé eré, oníjó, akọrin[2][3] àti ajìjàgbara. Ní ọdún 2009, ó jáwé olúborí níbi kíkópa nínu ètò tẹlifíṣọ̀nù ti Amstel Malta Box Office (AMBO). Àwọn èyàn maá n pèé ní little Genevieve nítorí wípé ó fi ojú jọ òṣèré Genevieve Nnaji.[4] Ó gba àmì-ẹ̀yẹ ọ̀dọ́mọdè òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ ti ẹlẹ́kẹẹ̀jọ ti Africa Movie Academy Awards.[5][6]
Ivie Okujaye | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 16 May 1987[1] Ilu Benin | (ọmọ ọdún 37)
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Yunifásítì ìlú Abùjá |
Iṣẹ́ | Osere, akọrin, agberejade, akọwe ere |
Ìgbà iṣẹ́ | 2010–iwoyi |
Ìgbé ayé rẹ̀
àtúnṣeA bí Okujaye ní Ìlú Benin sí ọwọ́ bàbá tí ó jẹ́ ọmọ Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà àti ìyá tí ó jẹ́ Ìpínlẹ̀ Ẹdó. Okujaye ni ìkẹhìn nínu àwọn ọmọ márùn-ún ti òbi rẹ̀. Ó ti sọ nígbàgbogbo pé àwọn òbí òun fẹ́ kí òun kẹ́ẹ̀kọ́ ìṣògùn nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìṣògùn wà nínu ẹbí rẹ̀. Ó lo ọdún mẹ́wàá àkọ́kọ́ ayé rẹ̀ ní Ìlú Benin ṣáàju kí ó tó kó lọ sí ìlú Àbújá. Ó ní ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ilé-ìwé Our Ladies of Apostle Private School, ó sì lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Queen's College ní Ìlú Èkó ṣáàju kí ó tó kọ́ ẹ̀kọ́ Economics ní Yunifásítì ìlú Abùjá.[7][8][9]
Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀
àtúnṣeOkujaye ti n ṣiṣẹ́ fún àìmọye ọdún ní orí ìpele ṣááju ìfihàn àkọ́kọ́ rẹ̀ ní Nollywood. Gẹ́gẹ́bí àlàyé rẹ̀, ìfihàn rẹ̀ ní Amstel Malta Box Office ṣe ìfilélẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣokùn fa ipa àkọ́kọ́ rẹ̀ nínu fíìmù Alero Symphony.[10][11]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Celebrity Birthday: Ivie Okujaye". pulse.ng. Archived from the original on 7 February 2020. Retrieved 16 May 2014.
- ↑ "Ivie Okujaye releases single". modernghana.com. Retrieved 17 April 2014.
- ↑ "Nollywood Actress turns Singer". newsng.com. Archived from the original on 19 April 2014. Retrieved 17 April 2014.
- ↑ "Nollywood Damsels for 2014". dailyindependentnig.com. Retrieved 17 April 2014.
- ↑ "Ivie Okujaye". allafrica.com. Retrieved 17 April 2014.
- ↑ "We'll make 30 million at the Box Office". punchng.com. Archived from the original on 19 April 2014. Retrieved 17 April 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Ivie Okujaye Releases AMBO 5 movie". vanguardngr.com. Retrieved 17 April 2014.
- ↑ "My Romance with Obafemi Martins and More- Ivie Okujaye". Entertainment Express Nigeria. Archived from the original on 19 April 2014. Retrieved 17 April 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "AMBO star veers into music". peoplesdailyng.com. Retrieved 17 April 2014.
- ↑ -%E2%80%9Calero%E2%80%99s-symphony%E2%80%9D/ "AMBO 5 Winner makes Screen debut with Faze" Check
|url=
value (help). bellanaija.com. Retrieved 17 April 2014. - ↑ "A Fresh Face and Talent in Nollywood". leadership.ng. Retrieved 17 April 2014.