Jayé Kútì
Jayé Kútì (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje, ṣùgbọ́n tí kò jẹ́ kí ọdún rẹ̀ hànde) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò àti oníṣòwò ọmọ bíbí yewa, ayétòrò ní Ẹ̀gbádò Ìlaròó ní ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìròyìn tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ kan gbòde nígbà kan pé ìyàwó gbajúmọ̀ olórin Fújì, Alhaji Wàsíù Àlàbí Pàsúmà, ṣùgbọ́n èyí jìnnà sí òótọ́.[1]
Ìgbà èwe, ẹ̀kọ́ kíkà àti ìgbìyànjú rẹ̀ nínú iṣẹ́ tíátà
àtúnṣeLóòótọ́ ọmọ Yorùbá pọ́ńbélé ni Jayé Kútì, ṣùgbọ́n òkè-oya ní ìlú Kánò ni wọ́n bí i sì, ó sìn bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ kíkà rẹ̀ ní Sunshine Nursery and Primary school, ní ìlú Kánò. Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Federal Polytechnic, Ìlaròó, ìpínlẹ̀ Ògùn níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí nínú Secretarial Administration. Ó tún kàwé ní ifáfitì, University of Lagos, tí ó sìn gba ìwé-ẹ̀rí ìmọ̀ èdè òyìnbó (English Language). Jayé bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò rẹ̀ nígbà tí ó dara pọ̀ mọ́ eré orí ẹ̀rọ tẹlifíṣàn lédè òyìnbó pẹ̀lú gbajúgbajà òṣèré sinimá àgbéléwò, Adébáyọ̀ Sàlámì, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ọ̀gá Bello. Sinimá àgbéléwò tó mú un gbajúmọ̀ ní àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Jayéọlá Ni Mò Ń Jẹ́". [2] [3]
Ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Wàsíù Àlàbí Pàsúmà
àtúnṣeJayé Kútì fúnra rẹ̀ tako ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ tí ó tàn káàkiri pé ìyàwó gbajúgbajà olórin Fújì Alhaji Àlàbí Pàsúmà lòun [2]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Obasanho, Stephanie (2017-05-24). "Nigerian movies superstar ★JAIYE KUTI - What is her life story?". Legit.ng - Nigeria news. Archived from the original on 2019-12-11. Retrieved 2019-12-11.
- ↑ 2.0 2.1 "Jaiye Kuti clears air on relationship with Pasuma - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper. 2019-11-27. Retrieved 2019-12-11.
- ↑ Published (2015-12-15). "Jaiye Kuti, others slam Sydney Talker over controversial comedy skit". Punch Newspapers. Retrieved 2019-12-11.