Jibola Dabo

Oṣèrékùnrin ilẹ̀ Nàìjíríà

Jíbọ́lá Dábọ̀ (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹjọ ọdún 1942) jẹ́ gbajúmọ̀ oǹkọ̀wé, Adarí, olóòtú àti òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìlú Ọ̀wọ̀ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó ṣùgbọ́n tí wọ́n bí sí ìlú Èkó lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] [2]

Jíbọ́lá Dábọ̀
Ọjọ́ìbíJíbọ́lá Dábọ̀
August 12
Lagos State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigeria
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Lagos
Iṣẹ́Actor

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́

àtúnṣe

Jíbọ́lá Dábọ̀ dàgbà sí ìlú Èkó, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú.[3] Ìlú Èkó yìí náà ló ti bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ kíkà rẹ̀. Ó kàwé gboyè dìgírì àkọ́kọ́ rẹ̀ ní University of Lagos nínú ìmọ̀ a yàwòrán àtinúdá. Lẹ́yìn èyí, ó fòfẹ̀ẹ̀rẹ̀, ó dèrò ìlú òyìnbó ní Amẹ́ríkà, ibẹ̀ ló ti kàwé gboyè dìgírì kejì ni Columbia State University nínú ìmọ̀ akọròyìn.

Ìgbìyànjú rẹ̀ nínú iṣẹ́ tíátà

àtúnṣe

Láti ìgbà èwe ni Jíbọ́lá Dábọ̀ tí nífẹ̀ẹ́ eré tíátà. Láti ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ló ti ń kópa nínú eré orí ìtàgé. Ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 2006, ó sìn tí kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ti gba àmìn ẹyẹ nídìí iṣẹ́ yìí. [4] [5]

Àtòjọ àwọn sinimá àgbéléwò tí ó ti kópa

àtúnṣe
  • Bloody Carnival
  • My Fantasy
  • Broken Mirror
  • My Game
  • High Blood Pressure
  • Changing Faces
  • Kingdom of Darkness
  • Break Away
  • Game Changer
  • Dirty Secrets (with Tonto Dikeh & Muna Obiekwe).
  • Queen of the World

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Jibola Dabo Biography and Net Worth - Austine Media". Austine Media. 2018-02-05. Archived from the original on 2019-12-03. Retrieved 2019-12-03. 
  2. "Jibola Dabo Biography - MyBioHub". MyBioHub. 2016-05-18. Retrieved 2019-12-03. 
  3. "Actor Jibola Dabo: Biography and Net worth". Ken Information Blog. 2019-06-12. Retrieved 2019-12-03. 
  4. "7 things you probably don't know about actor". Pulse Nigeria. 2015-08-12. Retrieved 2019-12-03. 
  5. "My grey beard is a brand god himself gave me - Veteran actor Jibola Dabo - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2018-12-08. Retrieved 2019-12-03.