Jimi Ṣolanke

Akéwì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Jìmí Ṣólàńkẹ́ tí wọ́n bí ní oṣù Keje ọdún 1942 (July 1942 - 5 Oṣù Kejì 2024), jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, eléré-oníṣe, olórin ìbílẹ̀, akéwì àti oǹkọ̀tàn omọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Ṣólàńkẹ́ kàwé gboyè ní Ifáfitì Ìbàdàn níbí tí ó ti gbàwé ẹ̀rí Dípúlọ́mà nínú eré oníṣe.[2]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré

àtúnṣe

Lẹ́yín tó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Ìbàdàn, ó lọ sì ìlú Amẹ́ríkà níbí tí ó ti dá ẹgbẹ́ òṣèré oníṣe sílẹ̀ tí ó pè ní 'Gbé African Review' tí àfojúsùn wọn sì dá lórí àṣà ilẹ̀ Yorùbá. Gbogbo àwọn ẹgbẹ́ yí ni wọ́n ma ń wọ aṣọ ìbílẹ̀ Yorùbá, tí eọ́n sì ma ń ṣeré ní àwọn Ilé-ẹ̀kọ́ àwọn adúláwọ̀ nìkan. Ìlú Kalifọ́níà ni ó ti ń ṣe iṣẹ́ òníọ̀tàn rẹ̀. Àwọn àjọ oníròyìn CNN ma ń pè é ní Onítàn, master of teller). [3] Ó padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú mẹ́ta nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì bá Ilé iṣẹ́ alohùn-máwòrán Nigerian Television Authority NTA, ní ọdún 1986. Ó sábà ma ń jẹ́ olú ẹ̀dá ìtàn nínú ọ̀pọ̀ eré-oníṣe ti Ọlá Balógun bá gbé jáde. Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ikọ̀ tí wọ́n ṣe eré Kongi's Harvest iwe ìtàn tí Wọlé Sóyinká kọ. [4]

Àwọn eré tó ti kópa

àtúnṣe
  • Kongi's Harvest [5]
  • Ṣàngó (1997)

Awọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. PeoplePill. "Biography, Life, Family, Career, Facts, Information". PeoplePill. Retrieved 2020-01-04. 
  2. "Jimi Solanke". Africainterviews. 2015-01-05. Retrieved 2020-01-04. 
  3. Published (2015-12-15). "Wife". Punch Newspapers. Retrieved 2020-01-04. 
  4. "Artistes now earn millions for poor performances —Jimi Solanke". Vanguard News. 2018-05-03. Retrieved 2020-01-04. 
  5. "Jimi Solanke: A Man of Authentic Artistry". THISDAYLIVE. 2018-04-15. Retrieved 2020-01-04.