Joseph Harden
Joseph Harden (ọdún 1824 sí ọdún 1864) jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọmọ orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀ Áfríkà àti Amẹ́ríkà tí ó jẹ́ wípé ní ìhà Ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ni ó ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Harden ni olùdásílẹ̀ ìjọ Batísì Àkọ́kọ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkó, òun ni ó sì jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ìwé Batísì ni Ìpínlẹ̀ Èkó.
Ayé Rẹ̀
àtúnṣeA bí Harden gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ni òmìnira sí àwọn òbí tó mọ oko ẹrú, onígbàgbọ́ Mẹ́tọ́dístì ni bàbá rẹ̀ wọ́n sì ṣe ìrìbọmi fún Harden gẹ́gẹ́ bí ara Mẹ́tọ́dístì kí ó tó lọ sí ìjọ Batísì ti ìhà Gúúsù. Lẹ́yìn tó kúrò, ó di ará Ìjọ Batísì Áfríkà tí Òpópónà Saratoga ní Baltimore. [1]
Nígbà tí Àgọ́àjọ ti Batísì Ìhà Gúúsù Southern Baptist Convention dá Foreign Mission Board sílẹ̀ láti ṣe agbátẹrù àwọn iṣẹ́ ìwàásù orí pápá, wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ ilé ìwàásù orí pápá ní Ṣáínà àti ní Ìhà Ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà West Africa, nítorí àwọn ẹni tó jẹ́ ẹrú tẹ́lẹ̀ tọ́ wà ní Làìbéríà Liberia àwọn Batísì rò pé ó jẹ́ ibi tó dára láti máa yí àwọn ọmọ Áfríkà sí ẹ̀sìn Krìstẹ́nì. Harden, ọmọ Ìjọ Batísì ní Maryland ni àwọn ìgbìmọ̀ tí ń darí iṣẹ́ ìwàásù orí pápá yàn láti kó lọ Làìbéríà fún iṣẹ́ ìwàásù orí pápá.[2][1]
Ìrírí Harden àkọ́kọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ ìwàásù orí pápá ní Ìhà Ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà jẹ́ èyí tí ń bani lọ́kàn jẹ̀, ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ àti ọmọ rẹ̀ kú láàárín ọdún kan tí wọ́n dé etí Làìbéríà. Ó fẹ́ ìyàwó kejì, ọmọbìnrin Làìbéríà kan èyí tí ó kú nígbà tó ń bímọ.[1] Àmọ́, ó ṣe tán láti ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ rẹ̀. Ní Làìbéríà, ó bá John Day dọ̀rẹ́, ẹni tó wà lákóso iṣẹ́ ìwàásù orí pápá Batísì, ó sì máa ń wà pẹ̀lú ọ̀dọ́mọkùnrin kan oníwàásù láti Amẹ́ríkà, William Clark, ẹni tó ń lọ lọ́nà rẹ̀ sí Ìjàyè àti James Churchill Vaughan tó kó pa nínú ìdàgbàsókè Ìjọ ti Eko.
Iṣẹ́ gbé Harden lọ sí Èkó ni ọdún 1855,ní àkókò yẹn àwọn oníṣẹ́ránṣẹ́ orí pápá méjì ti Batísì Ìhà Gúúsù ti síwájú rẹ̀ débẹ̀, ìyẹn Thomas Bowen àti William H. Clark ti wà ní Ọ̀yọ́, tí wọ́n gbìyànjú láti wọlé sí àárín àwọn ará Ìjàyè. Ṣùgbọ́n, Èkó ni Harden ti ṣe ìfìlọ́lẹ̀ ilé fún àwọn oníwàásù orí pápá, wọ́n kọ́ ilé náà láti ara bamboo Ó sì lọ ògbufọ̀ láti wàásù ọ̀rọ̀ rẹ̀.[3] Ilé náà ní àkọ́kọ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Harden padà ṣí kíláàsì ìkọ́ni èyí tó di Ilé Ìwé Batísì. Ó gbé Sarah Marsh níyàwó, ẹni tó padà kó ipá pàtàkì nínú ìdíróṣíṣí Àgọ́àjọ Batísì ti Nàìjíríà ní Ìpínlẹ̀ Èkó. [4]
Àwọn Ìtọ́kási
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Lindsay, Lisa A. (22 December 2016). Atlantic bonds : a nineteenth-century odyssey from America to Africa. Chapel Hill. pp. 102–104, 140. ISBN 978-1-4696-3113-4. OCLC 967938956. https://www.worldcat.org/oclc/967938956.
- ↑ "History Highlights". Archived from the original on 2020-09-29. Retrieved 2020-08-20.
- ↑ Bowen, T. J. (1969) (in English). Central Africa. Adventures and missionary labors in several countries in the interior of Africa, from 1849 to 1856.. New York: Negro Universities Press. pp. 182. ISBN 978-0-8371-1540-5. OCLC 324231. https://www.worldcat.org/oclc/324231.
- ↑ "Our History". FBC Lagos Island (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-08-21.