Judith Audu

Òṣéré orí ìtàgé

Judith Emike Audu-Foght tí a mọ̀ nídi iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Judith Audu, jẹ́ òṣèré fiimu ará Nàìjíríà, afẹwàṣiṣẹ́, àti olùgbéré-jáde. Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Mofẹ́ nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí Nàìjíríà kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Emerald, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Joseph Benjamin, Carol King, Lilian Esoro àti Fẹ́mi Branch.[1] Ó tún gbajúmọ̀ púpọ̀ fún àwọn iṣẹ́ takuntakun rẹ̀ nípa gbígbéréjáde. Lára wọn ni Just Not Married, Flipped àti The Sessions. Ní ọdún 2019, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwon 100 tí YNAIJA yàn gẹ́gẹ́ bi àwọn tó ní ipa jùlọ nínu fiimu Ìlu Nàìjíríà.[2]

Judith Audu
Ọjọ́ìbíJudith Emike Audu
Ojo, Ipinle Eko, Naijiria
Ọmọ orílẹ̀-èdèNaijiria
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Lagos
Iṣẹ́Osere, Olugberejade, Awose
Ìgbà iṣẹ́2004; 2010–lowolowo
Parents
  • Audu Ali Audu (father)
  • Gift Salamatu Audu (mother)

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

A bí Audu ní Ìlú àwzọn Navy ní Ọ̀jọ́ọ̀, ní Ìlú Èkò sí bàbá tí n ṣe òṣìṣẹ Navy kan[3] tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Audu Ali Audu àti ìyá tí òun jẹ́ Gift Salamatu Audu. Ìya rẹ̀ jẹ́ oníṣòwò àti aládàni ilé ìtajà oúnjẹ.[3] Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé ìtajà oúnjẹ bẹ́ẹ̀, ó sì tún ṣiṣẹ́ ìpèsè àwọn oun ìyálò fún ìnáwó. Judith ní àwọn alájọbí méjì tí wọ́n ṣe arákùnrin Franklin Audu tí n ṣe ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àti arákùnrin àbúrò kan Abdulmalik Audu. Òun ni ọmọ ẹ̀kejì àti ọmọbìnrin kan ṣoṣo ti àwọn òbi rẹ̀. Ó wá láti agbégbé Auchi ti Ìpínlẹ̀ EdóNàìjíríà.

Audu lọ sí Ilé-ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ Navy Town,[4] Ọ̀jọ́ọ̀, láti ọdún 1988 sí 1993. Lẹ́hìn náà ló lọ sí Ilé-ìwé girama ti Navy Town bakan náà láti 1993 sí 1999, níbi tí ó ti gbájúmọ́ àwọn iṣẹ́ Arts. Lẹ́hìn náà ló lọ sí ilé-ìwé gíga kan tí ó wà ní Badagry ní ọdún 2001 tó sì gba oyè-ẹ̀kọ́, èyí tí ó lò láti wọ ilé-ìwé gíga University of Lagos ní ọdún 2002.

Ní ọdún 2005, Audu gba oyè-ẹ̀kọ́ B.A nínu ède Faranse láti Yunifásitì ti Èkó.[5] Lẹ́hìn tí ó parí àgùnbánirọ̀ (NYSC) rè ní Ìpínlẹ̀ Kebbi ní ọdún 2007, Ó padà sí Yunifásitì tí Èkó láti lépa oyè gíga nínu ìmọ ọ̀rọ̀ ìlú àti ti káríayé láti ọdún 2008 sí 2010.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe