Joseph Benjamin

Òṣéré orí ìtàgé

Joseph Benjamin jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, model, olóòtú ètò orí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó di ìlú-mòọ́ká látàrí Ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ́lú àjọ MTN pẹ̀lú bí ó ṣe wà lára àwọn olùfilọ́ọ́lẹ̀ ètò ati fíforin dáni lára yá MTN Project Fame fún àwọn ọ̀dọ́ . Ó ti kópa nínú àwọn eré bíi: Tango With Me, Mr. and Mrs., àti Murder at Prime Suites.[1][2] Ó gba amì-ẹ̀yẹ ti oyè kùnrin tó peregedé jùlọ fún ní ú amì-ẹ̀yẹ 2012 African Film Awards.[3] Fún ipa rẹ̀ nínú eré Married but Living Single, ni ó mu tí ó tún fi gba amì-ẹ̀yẹ ti 2012 Best of Nollywood Awards.[4]Ní ọdún 2012, Benjamin tún gba amì-ẹ̀yẹ òṣèré kùnrin tó léwájú jùlọ nínú amì-ẹ̀yẹ ti 2012 Nollywood Movies Awards.

Joseph Benjamin
Joseph Benjamin
Ọjọ́ìbí9 Oṣù Kọkànlá 1976 (1976-11-09) (ọmọ ọdún 48)
Benue State, Nigeria
Iṣẹ́Actor, model, TV presenter, voice-over artist
Ìgbà iṣẹ́1995–present

Ìgbé ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Benjamin ní ọjọ́ kẹsàn án oṣù kọkànlá ọdún 1976. Bàbá rẹ̀ jẹ́ ọmọ bí Ìpínlẹ̀ Kogí nígbà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ìpínlẹ̀ Anambra. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Benue nígbà tí ó ka ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Óní ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà nínú ìlò ẹ̀rọ kọ̀mpútà , ó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Mass Communication. Ó ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 2004, ó sì bí ọmọ méjì kí òun àti ìyàwó rẹ̀ tó pínyà. [5]

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Benjamin ṣe eré rẹ̀ akọ́kọ́ tí y pè ní Crossroads, ní ọdún 1995, òun pẹ̀lú Ramsey Nouah àti Sandra Achums. Ben ti kọ́kọ́ kópa nínú ètò kan ní orí érọ amóhù-máwòrán ti NTA tí wọ́n pè ní Tales by Moonlight nígbà tí ó wà ní 9mọ ọdún méjìlá. [6]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré Nollywood àti TV

àtúnṣe

Benjamin ti kòpa lórí àwọn ètò ọlọ́kan-ò-jọkan lórí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán bíi Edge of Paradise. Tango With Me . Ó sì tún ti kópa nínú eré orí rédíò pẹ̀lú.[7]

Ó kópa bí ọ̀tẹlẹ̀múyẹ̀ nínú eré Murder at Prime Suites (MAPS). Lára àwọn eré mìíràn tí ó ti kópa ni: Dark Side, Married but Living Single, àti Mr. and Mrs.[2][8]

Wọ́n yàn án fún amì-ẹ̀yẹ Golden Actor nínú Golden Movie Awards, èyí tí ó wáyé ní 21 May 2015. Lára àwọn òṣèré tí wọ́n tún jọ yàn fún ipò àmì-ẹ̀yẹ yí ni: Gbenga Tityloye, John Dumelo, Adjetey Anang àti Blossom Chukwujekwu.[9][10][11]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

àtúnṣe
Year Title Role Notes
1995 Cross Roads
2003 Deadly Misson Dotun
2009 Jungle Ride Akin
2009 Spellbound
2010 Kiss and Tell Iyke with Monalisa Chinda, Desmond Elliot & Nse Ikpe Etim
2010 Kidnap
2010 Tango with Me
2011 Mr. and Mrs. Ken Abbah with Nse Ikpe Etim & Barbara Soky
2011 Courier
2012 Married but Living Single Mike with Funke Akindele & Joke Silva
2012 Stripped
2012 Torn
2012 Unfair
2012 Darkside
2012 Faith
2012 Contract
2013 Murder at Prime Suites
2013 First Cut alongside Lisa Omorodion and Monalisa Chinda
2014 Mum, Dad, meet Sam
2014 Few good Men
2014 Blind Promise
2014 Secret Box
2014 Iyore
2014 Folly
2014 A Few Good Men Wale Feature Film directed by Ejiro Onobrakpor and featuring Déyẹ̀mí Ọ̀kánlàwọ́n
2015 The Grave Dust Jordan with Ramsey Nouah & Joke Silva
2015 Ọmọge Òfegè[12] pẹ̀lú Fẹ́mi Adébáyọ̀ àti Ìrètí Ọ̀sáyẹmí
2016 Rebecca Clifford
2017 Isoken Osaze
2017 Affairs of the Heart Eric
2020 Special Jollof

Àwọn eré orí Amóhù-máwòrán

àtúnṣe
Ọdún Àkọ́lé eré Ipa tí ó kó Notes
1995 Cross Roads
2003 Deadly Mission
2005 Just Me
2005 Travails of Faith
2005-2006 Edge of Paradise
2005-2006 Young, Single and free
2007 Super story Àdàkọ:Which
2007 Bachelors
2007 168 A love Story
2008-2013 Tinsel
2015 Desperate Housewives Africa Chuka Obi

| 2018 || Greenleaf ||Joseph Obi || |-

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "BN Saturday Celebrity Interview: From TV to the Big Screen, Meet Nigeria’s New Heartthrob Joseph Benjamin". Bella Naija. 21 January 2012. Retrieved 2 January 2014. 
  2. 2.0 2.1 "Joseph Benjamin". M.afrinolly.com. Archived from the original on 2 January 2014. Retrieved 2 January 2014. 
  3. http://www.informationng.com/2012/11/joseph-benjamin-wins-african-actor-of-the-year-at-17th-afro-hollywood-awards.html
  4. https://ynaija.com/joseph-benjamin-wins-best-actor-at-the-best-of-nollywood/
  5. "Nollywood actor Joseph Benjamin opens up on separation from wife – Nigeria Today". Zimbio. Archived from the original on 2 January 2014. Retrieved 21 April 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "NOLLYWOOD: Joseph Benjamin Biography (Nigerian Actor)". InformAfrica.com. 22 November 2012. Archived from the original on 2 January 2014. Retrieved 2 January 2014. 
  7. Adeyemo, Adeola (21 January 2012). "BN Saturday Celebrity Interview: From TV to the Big Screen, Meet Nigeria’s New Heartthrob Joseph Benjamin". Bella Naija. Retrieved 21 April 2014. 
  8. "BN Saturday Celebrity Interview: From TV to the Big Screen, Meet Nigeria’s New Heartthrob Joseph Benjamin". Bella Naija. 21 January 2012. Retrieved 2 January 2014. 
  9. "Golden Movie Awards: Nadia Buari, Joseph Benjamin, Yvonne Nelson, others get nominations". 1Push Naija. Ogbodo. Archived from the original on 27 May 2015. Retrieved 23 May 2015. 
  10. "Golden Movie Awards: Nadia Buari, Joseph Benjamin, Yvonne Nelson, others get nominations". Sturvs Nigeria. Sturvs. Archived from the original on 27 May 2015. Retrieved 23 May 2015. 
  11. "Nadia Buari, Joseph Benjamin, Yvonne Nelson, others get nominations". Pulse Nigeria. Gbenga Bada. Archived from the original on 1 July 2017. Retrieved 23 May 2015. 
  12. "Joseph Benjamin Nollywood actor stars in 1st Yoruba movie 'Omoge Ofege'". Pulse Nigeria. Chidumga Izuzu. Archived from the original on 4 March 2016. Retrieved 22 June 2015. 

Ìtàkùn ìjásóde

àtúnṣe

Àdàkọ:Project Fame West Africa Àdàkọ:Authority control