Julius Àràbà
Julius O. Àràbà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olórin tí ó di orin Jùjú mú tí wọ́n sì gbajúmọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àsìkò tirẹ̀. Òun ati àwọn bí Àkànbí Wright, Victor Ọláìyá jọ jẹ́ olórin jùjú lásìkò náà. Nínú iṣẹ́ orin rẹ̀, ó ṣalábàápàdé Àkànbí Wright tí ó ràn an lọ́wọ́ nípa ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni lórí iṣẹ́ tí ó yàn láàyò. Ẹ̀wẹ̀, Àràbà jẹ́ ẹni tí ó kọ́ ògbóntagì olórin Jùjú Fatai Rolling Dollar níṣẹ́ orin jùjú kíkọ.[1] [2]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "*rare “rolling dollar” *a circus troupe". Vanguard News. 2013-06-21. Retrieved 2019-12-28.
- ↑ "Some Information About Nigeria's Jùjú Music & Five YouTube Examples Of Jùjú Music". pancocojams. 2017-12-05. Retrieved 2019-12-28.