Káàdì ìpọwó
ATM card jẹ́ káàdì oníke kan tí a ma ń gbà láti Ilé Ìfowópamọ́ tí àwọn oníbárà ilé-ìfowópamọ́ ma ń lò láti gbowó wọn lẹ́nu ẹ̀rọ ìpọwó láì wọ inú gbọ̀gan ilé-ìfowópamọ́ gangan tí wọ́n da sílẹ̀ ní inẹ̀rẹ̀ ọdún 2010. Ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn lágbàáyé, wọ́n ma ń lo káàdì ìsanwó láti fi rà tàbí di owó. Ránṣẹ́ sí ẹlòmíràn.
Ìrísí rẹ̀
àtúnṣeKáàdì ìsanwó ni ó rí pélébé bíi káàdì ìléwọ́ ìdánimọ̀, tàbí káàdì ajuwe-ẹni tí ó ní àwọn èròjà bíi ẹ̀mú àti irinṣẹ́ chip tí ó ní àwọn nọ́mbà ara-ọ̀tọ̀ tí ó dúró fún ààbò bíi déètì tí káàdì náà yóò dópin ati àwọn mìíràn. Orísiríṣi orúkọ ni wọ́n ń pe káàdì yí, lára rẹ̀ ni : bank card, MAC (money access card), client card, key card or cash card, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí a bá ti lo káàdì ìsanwó yí láti fi gbowó lẹ́nu ẹ̀rọ ìpọwó, ilé ìfowó-pamọ́ níye tí wọn yóò fàyọ nínú àpò ìfowó-pamọ́ oníbárà tí ó ni káàdì náà.
Ìtan rẹ̀
àtúnṣeWọ́n kọ́kọ́ ṣe ìgbéjáde káàdì ìpọwó ní inú ọdún 1967 ní agbègbè Barclays ní ìlú London.[1]
Àwọn itọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Jarunee Wonglimpiyara, Strategies of Competition in the Bank Card Business (2005), p. 1-3.