Àdàkọ:Other uses of

Pods at various stages of ripening

Èso Kòkó tàbí Kòkó ( /ˈkəʊ.kəʊ/), ni wọ́n tún ń dà pè ní ẹ̀wà kòkó ( /kəˈk/),[1] ni ohun ọ̀gbìn kan tí ó so sí ara igi tí ìrísí rẹ̀ fẹ́ fara pẹ́ èso Igi Obì. Orúkọ èso yí wá láti inú èdè Spain tí wọ́n pé ní: "cacao", tí àwọn náà mú orúkọ yí láti inú ọ̀rọ̀ "Nahuatl". Ọ̀rọ̀ "cacahautil" yí wọ́n tún ṣe àgbélẹ̀rọ rẹ̀ láti inú gbólóhùn "Mije-Sokean" tí ìpìlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ kakawa.

Ìtàn rẹ̀ àtúnṣe

Igi tàbí èso Kòkó ni ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn Amazon Basin. Àwọn ènìyàn Olmecs àti Mokaya rí wọ́n jẹ́ (Mexico and Central America). Ní n kan bí ẹgbẹ̀rin ọdún (4,000 years) sẹ́yìn, ni wọ́n ti ń jẹ tàbí mu tí wọ́n si ń fi pèsè ohun jíjẹ aládìídùn láàrín àwọn Yutacan pàá pàá jùlọ àwọn Maya.

Àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ń pèsè Kòkó àtúnṣe

Pípèsè Kòkó – 2017
Àwọn Orílẹ̀-èdè (tonnes)
  Côte d'Ivoire
2,034,000
  Ghana
883,652
Àdàkọ:IDN
659,776
  Nàìjíríà
328,263
  Cameroon
295,028
  Brazil
235,809
Àdàkọ:ECU
205,955
World
5,201,108
Source: FAOSTAT of the United Nations[2]

Ní ọdún 2017, iye kòkó tí wọ́n pẹ̀sè láapapọ̀ jẹ́ 5.2 million tonnes, tí orílẹ̀-èdè Ivory Coast léwájú pẹ̀lú ìdá 38%. Àwọn mìíràn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tún pèsè kòkó tún ni: Ghana (17%) àti Indonesia (13%).

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Cacao". Free Dictionary. Retrieved 17 February 2015. 
  2. "Cocoa bean production in 2017, Crops/Regions/World list/Production Quantity (pick lists)". UN Food and Agriculture Organization, Corporate Statistical Database (FAOSTAT). 2018. Retrieved 28 March 2019.