Kady Traoré (tí wọ́n bí ní 18 Oṣù Kẹẹ̀ta Ọdún 1979) jẹ́ òṣèrébìnrin, olùdarí erè àti agbéréjáde ọmọ orílẹ̀-èdè Bùrkínà Fasò.

Kady Traoré
Ọjọ́ìbí18 Oṣù Kẹta 1979 (1979-03-18) (ọmọ ọdún 45)
Bobo-Dioulasso
Orílẹ̀-èdèBurkinabé
Iṣẹ́Actress, film director, producer
Ìgbà iṣẹ́1998-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Ìlú Bobo-Dioulasso ni wọ́n bí Traoré sí ní ọdún 1979.[1] Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ISIS (Higher Institute of Image and Sound) ní ìlú Ouagadougou.[2]

Ó ṣe àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi òṣèré ní ọdún 1998, pẹ̀lú kíkópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù alátìgbà-dègbà tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ A nous la vie, èyí tí Toussaint Tiendrébéogo darí. Ní ọdún 2001, Traoré kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù kan tí Issouf Tapsob ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Les jeunes branchés. Ní ọdún yìí kan náà, ó kópa nínu eré Gomtiogo.[3] Ní ọdún 2008, ó kó ipa Timy gẹ́gẹ́ bi ìbátan Ousmane, ẹnití ó n ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú ọlọ́pàá Inspector Marc, nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Super flics.[4]

Ní ọdún 2014, Traoré ṣe adarí eré táa pe àkọ́lé rẹ̀ ní A vendre, èyí tí n ṣe àkọ́kọ́ fíìmù gígùn rẹ̀.[5] Eré náà sọ ìtàn ọkùnrin kan tí ó n wá oníbàárà láti ta àwọn dúkìá rẹ̀ fún títí ó fi pàdé àwọn tọkọtaya kan tí ó sì lọ yó ìfẹ́ ìyàwó náà.[6] Traoré tún darí eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Conflit conjugal ní ọdún 2017, èyítí ó jẹ́ ọ̀kan nínu fíìmù méjì tí ó. gba àmì-ẹ̀yẹ ti Succès Cinema Burkina Faso níbi ayẹyẹ Panafrican Film and Television Festival of Ouagadougou.[7] Ní ọdún 2018, Traoré darí eré Prejuge, èyítí ó jẹ́ gbígbé jáde látàrí owó ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ Ouaga Film Lab.[8] Ó jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ agbéréjáde kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Athena Films.[9]

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Traoré ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú akọrin kan tí wọ́n mọ̀ nídi iṣẹ́ rẹ̀ sí Smockey (tí àbísọ rẹ̀ jẹ́ Serge Martin Bambara) ní 31 Oṣù Kínní Ọdún 2008.[10] Àwọn méjéèjì ti ní àwọn ọmọ méjì.[11]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe

Àwọn eré tí ó ti kópa gẹ́gẹ́ bi òṣèré

àtúnṣe
  • 1998 : A nous la vie (TV series)
  • 2001 : Les jeunes branchés (TV series)
  • 2001 : Gomtiogo
  • 2004 : Traque à Ouaga
  • 2005 : Dossier brûlant
  • 2005 : Code phénix
  • 2006 : L’or des Younga
  • 2008 : Super flics as Timy (TV series)
  • 2014 : Waga love as Sandra (TV series)

Àwọn eré tí ó ti kópa gẹ́gẹ́ bi olùdarí

àtúnṣe
  • 2014 : A vendre
  • 2017 : Conflit conjugal
  • 2018 : Prejuge
  • 2019 : Femme au Foyer (TV series)

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Kady Traore". Africultures (in French). Retrieved 1 November 2020. 
  2. Sawadogo, Parfait (27 May 2019). "CINEMA : Kady TRAORÉ, Réalisatrice Talentueuse Et Chevronnée Du Burkina.". Infos Culture du Faso (in French). Retrieved 1 November 2020. 
  3. Sawadogo, Parfait (27 May 2019). "CINEMA : Kady TRAORÉ, Réalisatrice Talentueuse Et Chevronnée Du Burkina.". Infos Culture du Faso (in French). Retrieved 1 November 2020. 
  4. "« Superflics », une série télé burkinabè aux couleurs locales" (in French). 23 February 2009. https://www.nouvelobs.com/rue89/rue89-rue89-culture/20090223.RUE8651/superflics-une-serie-tele-burkinabe-aux-couleurs-locales.html#. Retrieved 1 November 2020. 
  5. "Kady Traore". Africultures (in French). Retrieved 1 November 2020. 
  6. "KADY TRAORE S’ESSAIE AU CINEMA". Afriyelba. 29 November 2014. Retrieved 1 November 2020. 
  7. "Succès Cinéma Burkina Faso, récompense la popularité de deux films burkinabè.". Dikou Afrika. 1 June 2018. http://dikouafrica.com/2018/06/01/succes-cinema-burkina-faso-recompense-la-popularite-de-deux-films-burkinabe/. Retrieved 1 November 2020. 
  8. "JCC 2018 : Le projet de film de Kady Traoré séduit" (in French). Burkina 24. 9 November 2019. https://www.burkina24.com/2018/11/09/jcc-2018-le-projet-de-film-de-kady-traore-seduit/. Retrieved 1 November 2020. 
  9. Sawadogo, Parfait (27 May 2019). "CINEMA : Kady TRAORÉ, Réalisatrice Talentueuse Et Chevronnée Du Burkina.". Infos Culture du Faso (in French). Retrieved 1 November 2020. 
  10. "Mariage de Smockey et de Kady : Le rappeur et l’actrice pour la vie". Lefaso.net (in French). 11 February 2008. Retrieved 1 November 2020. 
  11. Sawadogo, Parfait (27 May 2019). "CINEMA : Kady TRAORÉ, Réalisatrice Talentueuse Et Chevronnée Du Burkina.". Infos Culture du Faso (in French). Retrieved 1 November 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe