Kamorudeen Adekunle Adedibu

Olóṣèlú Nàìjíríà

Àdàkọ:Use Nigerian English

Kamorudeen Adekunle Adedibu
Senator for Oyo South
In office
29 May 2007 – 29 May 2011
AsíwájúAbiola Ajimobi
Arọ́pòOlufemi Lanlehin
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíOyo State, Nigeria

Kamorudeen Adekunle Adedibu Yo-Kamorudeen Adekunle Adedibu.ogg Listen jé sínátọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìdìbò gúúsù Ọ̀yọ́ fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó dé orí ipò ní ọjọ́ 29 oṣù kaàrún ni ọdún 2007. Ó jé ọmọ ẹgbẹ́ alábùradà People's Democratic Party (PDP).[1]

Adedibu jé ọmọ bíbí inú àgbà olóṣèlú kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Lamidi Adedibu.[2] Lẹ́yìn tí ó dé orí àga àwọn aṣòfin àgbà, wọ́n fi jẹ alága ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé-iṣẹ́ (committees on industry), ìgbìmọ̀ ìṣọ̀kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ará ìlú àti ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀jọba (Federal character & Inter-Goverment affairs), ìgbàni-síṣẹ́ (Employment), òṣìṣẹ́ àti àbájáde iṣẹ́ (Labour & productivity), ètò ìdáàbòbò àti àwọn ọmọ ogun (Defence & Army), pẹ̀lú ètò ìròyìn àti ọ̀nà ìbániṣọ̀rọ̀ (Information and Media).[1] Ní ààrin ṣáà àgbéyẹ̀wò àwọn sínátọ̀ ní oṣù kaàrún, ọdún 2009, ìwé ìròyìn ThisDay jé kí a mọ̀ pé ó ṣe àtìlẹyìn fún àbá òfin ìdàgbàsókè àti ìdàsílẹ̀ ilé-iṣẹ́ (Nigeria Industrial Development Authority Establishment Bill), ó sì tún ṣe àtìlẹyìn fún àwọn àbá mìíràn.[3] Nínú ìfòròwánilẹ́nuwò oṣù kaàrún ọdún 2009, ó fi àìdùnnú nípa ipò tí orílẹ̀-èdè rẹ wà, tó sì ń ṣọ́ pé onírúurú ìṣòro ní ó sí kù tí yóò dojú kọ. Ó fẹ̀sùn àìsòótọ́ àti àìní àfojúsùn kàn àwọn àgbà òṣèlú.[2]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 "Sen. Kamorudeen A. Adedibu". National Assembly of Nigeria. Archived from the original on 2016-03-03. Retrieved 2010-06-13.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. 2.0 2.1 "There is No Democracy to Celebrate - Adedibu". Daily Independent. 29 May 2009. Retrieved 2010-06-13. 
  3. "An Improved Senate, But Some Uninspiring Senators...". ThisDay. 24 May 2009. Retrieved 2010-06-13.