Mùsíọ́mu Kanta jẹ́ Mùsíọ́mu ní ìlú Argungu, ní orílẹ̀ èdè Nigeria, tó dẹ̀gbẹ́ kọjú sí ọjà.

Wọ́n kọọ́ ní ọdún 1831, wọ́n sì sọọ́ lórúkọ lẹ́yìn Muhammed Kanta, tí ó tẹ Kebbi Kingdom dó ní ọdún 1515. Tí Yakubu Nabame sì kọọ́, ọba Kebbi, tí ó sì jẹ títí di 1942 tí àwọn aláwọ̀ funfun fi kọ́ ààfin tuntun ní àkókò ìjọba Muhammed Sani. Lẹ́yìn tí ààfin náà ṣófo, ní ọdún 1958, wọ́n ṣíi gẹ́gẹ́ bíi mùsíọ́mù, tí ó ṣàlàyé àránbá tí ó jẹ́ baba ìtàn ti ìpínlẹ̀ Kebbi.

Mùsíọ́mù náà pín sí ìdá mọ́kànlá tí ó sì ní àwọn ohun irinṣẹ́ ogun, tí ó kún fún ògùn, ọ̀pọ̀ ìdàrọ, ọ̀pọ̀ idà,igi, ọ̀pọ̀ òkúta, ọ̀pọ̀ ọfà àti ọ̀pọ̀ àkọ̀, ìbọn àgbélẹ̀rọ àti bákan náà àwọn ìlù fún ìṣàfihàn.[1]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Next Archived 2011-07-21 at the Wayback Machine.