Khoisan
San tribesman from Namibia
San tribesman from Namibia
Regions with significant populations
Southern Africa
Èdè

Khoisan languages

Ẹ̀sìn

Animist, Muslim[1]

Ẹ̀yà abínibí bíbátan

perhaps Sandawe

Oju=iwe kiini

àtúnṣe

ỌLỌFNSAO OLUKEMI M.

ÀWỌN ẸBÍ ÈDÈ KHOISAN

Ìfáàrà

Ẹbí èdè Khoisan yìí ni ó kéré jù lọ nínú àwọn ẹbí èdè gbogbo tí ó wà ní Áfíríkà. Gẹ́gẹ́ bí Greenberg (1963a) ti sọ, ó ní àwọn ni wọ́n dúró fún èyí tí ó kéré jù lọ nínú èdè Áfíríkà. ÌPÌLẸ̀ ORÚKỌ ÈDÈ YÌÍ A mu orúkọ yìí jáde láti ara orúkọ ẹgbẹ́ Khoi-Khoi ti Gusu ilẹ Afirikà (South Africa) àti ẹgbẹ́ san (Bushmen) ti Namibia. A máa ń lo orúkọ yìí fún Oríṣìíríṣìí àwọn ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́ pé àwọn gan-an ni wọ́n kọ́kọ́ jẹ́ olùgbé ilẹ̀ south Africa kí awọn Bantu tó wá, kí àwọn òyìnbó ilẹ̀ Gẹẹsi (Europe) sì tó kó wọn lẹ́rù. Oríṣìíríṣìí àwọn onímọ̀ ni wọn ti siṣẹ lórí orúkọ yìí – Khoisan.Tan Gùldemann ati Rainer Vossen ṣàlàyé nínú iṣẹ́ rẹ̀ pé Leonardt Schulze 1928 ni o mu orúkọ yìí jáde láti ara Hottentot’ tí o túmọ̀ sí Khoi ti o sì tún túmọ̀ sí ‘person’ (ènìyàn) àti ‘san’ tí ó túmọ̀ sí ‘forager’. Lẹ́yìn èyí ni onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá àṣà, ìgbàgbọ́ àti ìdàgbàsókè ọmọnìyàn, anthropologist Schapera (1930) tún wá fẹ̀ orúkọ yìí lòjù sẹ́yìn nípasẹ̀ ‘Hottentot’àti ‘Bushman’ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà, (racia) àṣà (cultural) àti ìmọ̀ ẹ̀dá èdè. (Linguistic). Àwọn orúmọ̀ mìíràn tí wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kẹta ti wọ́n tún siṣẹ́ lé orúkọ yìí lórí ni Kolnler (1975, 1981) sands (1998) àti Traill (1980, 1986). Wọn pinnu láti lo orúkọ náà Khoisan gẹ́gẹ́ bí olúborí fún àwọn èdè tí kìí ṣe ti Bantù tí kì í sì í ṣe èdè Cushitic. Àwọn onímọ̀ akíọ́lọ́jì fi han wí pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fa ọdún sẹ́yìn ni awọn ènìyàn Khoisan ti fara hàn. Èyí fi han pé lọ́dọ̀ àwọn àgbà láèláè nìkan ni a ti lè máa gbọ́ èdè Khoisan nìkan báyìí. Bí èdè Khoisan tilẹ̀ farajọra nínú ètò ìró, gírámà tirẹ̀ yàtọ̀ gédégbé. Àìsí àkọ́sìlẹ̀ ìtàn àwọn èdè wọ̀nyí mú kí o nira díẹ̀ láti sọ ìfarajọra awọn èdè yìí sí ara àti sí àwọn èdè adúláwọ̀ tí ó kù. Lóde àní, Ilẹ̀ (South Western Africa) gúsu-ìwọ̀ òòrùn Áfíríkà títí dé àginjù kàlàhárì (Kalaharì Desert), láti Angola de South Africa àti ní apákan ilẹ̀ Tanzania nìkan ní wọ́n ti ń sọ èdè Khoisan. Edè Hadza àti Sandawe ní ilẹ̀ Tanzania ni a sáábà máa ń pè ní Khoisan ṣúgbọ̀n wọ́n yàtọ̀ nípa ibùgbé àti ìmọ̀ ẹ̀dá èdè sí ara wọn. A wá lè sọ pé nínú gbogbo èdè àgbáyé, èdè Khoisan wà lára àwọn èdè tí àwọn onímọ́ èdè kò kọbiara sí tí a kò sì kọ́ ẹ̀kọ́ nípa rẹ̀.

ÌPÒ TÍ ÈDÈ YÌÍ WÀ

Èdè Khoisan yìí gẹ́gẹ́ bí a ti sọ síwájú ń dín kù síi lójoojúmọ́ ni. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ń di ohun ìgbàgbé. Ohun tí ó fa èyí ni pé àwọn tí wọ́n ń sọ àmúlùmálà èdè Khoisan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè mìíràn tí ó gbilẹ̀ ní agbègbè wọn; wọ́n sì dẹ́kun kíkọ́ àwọn ọmọ wọn ní èdè abínibí wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn èdè wọ̀nyí ni kò ní àkọ́silẹ̀ kankan tí ó sì fíhàn pé sísọnù tí àwọn èdè wọ̀nyí sọnù, kò lè ní àtúnṣe. Ó jẹ́ ohun tí ó nira díẹ̀ láti sọ pé iye àwọn ènìyàn kan pàtó ni wọ́n ń sọ èdè Khoisan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí àwọn Òyìnbó tó gòkè bọ̀, a kò sì mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo àkókò tí àwọn Òyìnbó ń ṣètò ìjọba, bẹ́ẹ̀ sì tún ni pé ìwọ̀nba la lè sọ mọ nípa ohun ti ó ń ṣẹlẹ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n àkọsílẹ̀ fi hàn pé, ní bíì ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, iye nọ́nbà tí wọ́n kọ sílẹ̀ kò ṣeé tẹ̀lé mọ́; àkọsílẹ̀ sọ wí pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà Igba (120,000 – 200,000) ni wọn, ṣùgbọ́n èyí ti di ohun àfìsẹ́yìn bí eégún fí aṣọ. Wọn kò tó bẹ́ẹ̀ mọ́. Díẹ̀ lára àwọn èdè khoisan àti iye àwọn tí wọ́n ń sọ ọ́.


EDE, IYE ÀWỌN TI Ń SỌ, ILÚ,

Sandare, 40, 000, Tanzania

Haillom (San), 16,000, Namibia,

Name (Khoekhoegowab) 233,701 Namibia, Botswana, South Africa

Suua , 6,000, Botswana

Tsoa. 5,000, Botswana

//Ani , 1,000, Botswana

Gana, 2,000, Botswana

Kxoe 10,000, Namibia, Angola, Botswana South Africa, Zambia

//Gwi, 2,500 , Botswana

Naro, 14,000, Botswana, Namibia =Ikx’aull’ein 2,000, Namibia, Botswana

Kung-Ekoka, 6,900, Botswana, Angola, South Africa.

Oju-iwe keji

àtúnṣe

IHUN EDE KHOISAN

ÈTÒ ÌRÓ

Àwọn èdè Khoisan kò ṣàì ní ìfarajọra nínú ètò ìrò. Ó dá yàtọ̀ gédégbè sí àwọn èdè ilẹ̀ Áfíríkà yòókù, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè tí ó nira.

FAWẸLI

Ọ̀pọ̀ àwọn èdè Khoisan wònyí ni ó ń lo fáwẹ́lì márùn ún - /i/, /e/, /a/, /o/, /u/ tí a sì lè pè pẹ̀lú àwọn oríṣìí àbùdá wọ̀nyìí bíi, ìránmú, (nasalization) ìfi káà-ọ̀fun-pè (pharyngealization) ati oríṣìí àmúyẹ ohùn bíi mímí ohun (breathy voice) ati dídún ohùn (Creaky voice) tí yóò sì mú bí i oríṣìí ìró fáwẹ́lì bí i ogójì jáde.

KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ:-

(Clicks) kílíìkì

Kílíìkì ni a ń pe àwọn kọ́ńsónáǹtì wọn; títí kan àwọn àfeyínpè (dential), àfèrìgìpè, (alveolar), afàjàfèrìgìpè (alveo-palatal), afẹ̀gbẹ́-ẹnu-pè (lateral) àti kílíìkì afètèpè (bilabial Chick). Sandawe àti àwọn Hadza tí ilẹ̀ Tanzania ń lo àfeyínpè (dental ) afèrìgìpè (alveolar) àti kílíìkì afẹ̀gbé-ẹnu-pè (lateral clicks). Pẹ̀lú gbogbo àhesọ ọ̀rọ̀ títí di àkókò yìí orísun kílíìkì èdè Khoisan kò tíì yéni.

Àpẹẹrẹ:-

- Kiliiki Àfeyínpè – A máa ń pe èyí nípa gbígbé ahọ́n sí ẹ̀yìn ẹyín iwájú. “tsk”

- Kílíìkì Afèrìgìpè – Ó máa ń dún bí ìgbà tí a bá ṣí ìdérí ìgò nípa gbígbé ahọ́n sí ẹ̀yìn eyín iwájú.

- Kílíìkì Afàjàfàrìgìpè – Ó máa ń dún nípa gbígbé ahọ́n sílẹ̀ kúrò lára àjà ẹnu.

- Kílíìkì Afègbẹ́-ẹnu-pè – ó máa ń dùn gẹ́gẹ́ bí ìró ti à ń lò lédè Gẹ̀ẹ́sì láti mú kí ẹsin kánjú.

- Kílíìkì Afètépè máa ń dún nípa kíkanra ètè méjèèjì, tí a sì tún sí i sílẹ̀ ní kíá, gẹ́gẹ́ bí ìró ìfẹnukonu ni èyí ṣe máa ń dún.

Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kílíìkì wọ̀nyí ló lè ní Kíkùnyùn-ùn, (Voicing) ríránmú (nasality), “aspiration” ati “ejection”. Láti le mú kí á ní àgbéjáde oríṣìíríṣìí kílíìkì. Àwọn orísìíríṣìí kílíìkì wọnyi ló mú kí èdè Khoisan yàtọ̀. Àpẹẹrẹ nínú èdè Nama, Ogún ni kílíìkì tí wọ́n ń lò nígbà tí wọ́n n lo mẹ́tàlélógọ́rin nínú ède Kxoe tí ó jẹ́ ọ̀kan lára èdè Khoisan. Ní àfíkún, àádọ́rùn-ún ònírúrú kóńsónáǹtì kílíìkì ni wọ́n n lo ni Gwi tí òhun náà jẹ́ ọ̀kan lára èdè Khosian wọ̀nyí. Àpẹẹrẹ Kílíìki Nama

SÍLÉBÙ

Gbogbo àwọn kóńsónáǹtì Kílíìkì àti èyí tí kìí ṣe kílíìkì ló máa ń fara hàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tí fáwẹ́lì sì máa ń tẹ̀lé e. Ìwọ̀nba kóńsónáǹtì bí àpẹẹrẹ /b/, /m/, /n/, /r/, àti /l/ ló lè jẹ yọ láàrín fáwẹ́lì, díẹ̀ sì lè farahàn ní ẹ̀yìn ọ̀rọ̀.

ÌRÓ OHÙN

Àwọn èdè Khosan máa ń sàfihàn oríṣìíríṣìí ìró ohùn, bí àpẹẹrẹ, Jul’hoan ní ipele ohun àárún oríṣìí mẹ́rùn, ó sì ní ipele ohun òkè kan.

GIRAMA

Ọ̀rọ̀ àti ìhun gbólóhùn àwọn èdè Khoisan yàtọ̀ síra láàrin ara wọn.

Ọ̀RỌ̀ ORÚKỌ

Ìsọ̀rí mẹ́ta ni ọ̀rọ̀ arúkọ Khoisan pín sí; bí a bá wòó, nípasẹ̀ jẹnda, akọ, abo àti àjọni ni ò pín sí. Nínú Kxoe, fún àpẹẹrẹ, jẹ́ńdà nínú ọ̀rọ̀-orúkọ aláìlẹ́mìí tún máa ń ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìríṣí, bi àpẹẹrẹ, akọ ní í ṣe pẹ̀lú gígùn, tí tò si tóbi, nígbà tí abo ní í ṣe pẹ̀lú nǹken kúkúrú, gbígbòòrò tí kó sì tóbi òríṣìíríṣìí mọ́fíímù ni wọ́n fi ń parí òkọ̀ọ̀kan àwọn jẹ́ńdà wọ̀nyí.

Àpẹẹrẹ láti inú èdè Nama.

Khoisan , English, Yoruba ,

Khoe-b, Man , Ọkùnrin ,

Khoe-s, Woman, Obinrin ,

Oríṣìíríṣìí nọ́mbà mẹ́ta ni wọ́n ní, àwọn ní ẹyọ, oníméjì àti ọ̀pọ̀.

NỌ́MBÀ Apẹẹrẹ lati inu èdè Naro

Male (Akọ), Female (Abo), Common (Ako/Abo)

SG, ba , sa _________ Dual , tsara , sara, Khoara

PL llua dzi na

Ọ̀RỌ̀-ÌṢE

Àbùdá gírámà tí ó sáábà máa ń jẹ yọ nínú àwọn èdè Khoisan ni lílo ọ̀rọ̀-iṣe àkànmónúkọ (verb compound) nígbà tí èdè Gẹ̀ẹ́sì ń lo ọ̀rọ̀ atọ́kùn tàbí ọ̀rọ̀-iṣe kan (single verb) Àpẹẹrẹ

English, Khoisan, Enter go + enter.

Àsìkò (Tense)

Ẹ̀rún ni a máa ń lò láti fi àsìko hàn nínú èdè KhoeKhoe àti nípa lílo àfòrò ẹyin nínú ede Kxoe, Buga ati //Ani Ninú àwọn èdè Kalahari East Kxoe, Àfòmọ́ ẹ̀yìn ló ń fi ìṣẹ̀lẹ̀ ti o ti Koja hàn (Past Tense), ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ tí ó lòdì ati jẹ̀rọ́ndì hàn nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti ti ọjọ́ iwájú ń lo Ẹ̀rún. Bẹ́ẹ̀ náà lọmọ́ sorí nínú èdè Naro, G//ana, G/ui àti ‡Haba.

IBÁ ÌṢẸ̀LẸ̀

Mana nìkan ni ó ń lo ibá ìṣẹ̀lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìṣẹ̀dá (Morphological Category) ó sì ya ibá ìṣẹ̀lẹ̀ aṣetán sọ́tọ̀ sí àìṣetán


IYISODI

Ẹ̀rún tàbí àfòmọ́ ẹ̀yìn ni wọn n lo fún ìyísódì (Khoekhoe tam; G//ana G/ui àti ‡Haba tàmátema) n lò ẹ̀rún fún ìyísódì nígbà tí (kxoe //Am. Buya-bé) n lo afọmọ ẹyin, nígbà mìíràn wọ́n n lo méjèèjì. Ètò Ọ̀rọ̀ Ètò ọ̀rọ̀ tí àwọn èdè Khoisan ti à ń sọ wọ̀nyí máa ń lò ni (Svo-Subject-Verb-Object) Olùwà ọ̀rọ̀-ìṣe àti àbọ̀ tàbí (Sov-Suject-Object-verb).

Ọ̀rọ̀ Èdè (Vocabulary)

Àfihàn ìgbésí ayé àwọn olùṣọ èdè Khoisan ni ọ̀rọ̀-èdè (Vocabulary) wọn jẹ́. Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn olùṣọ èdè wọ̀nyí ń gbé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀dá mìírà, èyí mú kí wọ́n ní àwọn ọ̀rọ̀-èdè tí ó súnmọ́ ọdẹ ṣíṣe, ẹranko, Kóríko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

ÀKỌ́SÍLẸ̀

Ọ̀pọ̀ àwọn èdè wọ̀nyí ni kò ni àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n Nama ati Naro ni àkọsílẹ̀ àti ohun èlò ìkọ́ni. Nama ní pàtàkì ti wà ní àkọsílẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.