Kudirat Kekere-Ekun
Kudirat Motonmori Olatokunbo tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Kudirat Kekere-Ekun CFRCFR (ọjọ́ ìbí: ọjọ́ keje oṣù karùn-ún ọdún 1958) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jẹ́ adájọ́ ilé-ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1][2]
Kudirat Motonmori Olatokunbo | |
---|---|
Justice of the Supreme Court of Nigeria | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga July 2013 | |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 7 Oṣù Kàrún 1958 Lagos State, Nigeria |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Kìí ṣe olóṣèlú |
Ẹ̀tò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeA bí Kekere Ekun ní ọjọ́ keje oṣù karùn-ún ọdún 1958 ní ìlú London, United Kingdom. [3] Ní ọdún 1980, ó gba òye (bachelor's degree) nípa òfin ní Yunifásítì Èkó àti pé ó gba ilé-ìgbìmọ̀ (Nigeria Bar ) ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ọdún 1981, lẹ́hìn tí ó ti jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ òfin Nàìjíríà ṣáájú kí ó tó lọ sí 'London School of Economics' níbití ó ti gba òye másítà ní Òfin ní oṣù kọkànlá ọdún 1983. [4][5]
Àmì ẹ̀yẹ rẹ̀
àtúnṣeNí oṣù kẹwàá ọdún 2022, olá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan ti Alákoso ti Àṣẹ ti ìjọba àpapọ̀ (CFR) ni a fún un ní láti ọ̀dọ̀ Ààrẹ Muhammadu Buhari. [6]
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amòfin
àtúnṣeKudirat darapọ̀ mọ́ ètò ìdájọ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó gẹ́gẹ́ bí Adájọ́ Àgbà kejì, ó sì di ipò adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ náà. Ó sìn gẹ́gẹ́ bí Alága Ìgbìmọ̀ Ìjà jilè àti Ìbọn, (Zone II, Ikeja) láàrín oṣù kọkànlá ọdún 1996 sí oṣù karùn-ún ọdún 1999.[7] Wọ́n yàn án sí ìjókòó ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní Nàìjíríà lọ́dún 2004 kí wọ́n tó yàn án gẹ́gẹ́ bí Adajọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù lọ ti Nàìjíríà ní oṣù keje ọdún 2013.
Àwọn ìtọ́kaí
àtúnṣe- ↑ "SANs, lawyers hail Justice Kekere-Ekun’s elevation to Supreme Court". Vanguard News. Retrieved 2 May 2015.
- ↑ "NGP KYG: Justice K.M.O Kekere-Ekun". nigeriagovernance.org. Retrieved 2 May 2015.
- ↑ "Senate confirms Justice Kekere-Ekun as Justice of Supreme Court". nigeriatrends.com. Archived from the original on 1 July 2019. Retrieved 2 May 2015.
- ↑ "Another First for Justice Kudirat Kekere-Ekun, Articles - THISDAY LIVE". thisdaylive.com. Retrieved 2 May 2015.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Latestnigeriannews. "CJN charges new SCourt justice, Kekere-Ekun on integrity". Latest Nigerian News. Retrieved 2 May 2015.
- ↑ "FULL LIST: 2022 National Honours Award Recipients The Nation Newspaper" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-10-09. Retrieved 2022-10-26.
- ↑ Rilwan. "Judiciary... a tale of powerplay, politics and miscarried justice (2) - The Nation". The Nation. Retrieved 2 May 2015.