Lawuyi Ogunniran

Onkọ̀wé
(Àtúnjúwe láti Láwuyì Ògúnníran)

 

Láwuyì Ògúnníran
Ọjọ́ ìbíỌláwuyì Mosọbalájé Ọ̀nàọpẹ́pọ̀ Àyìndé Owólábí Ògúnníran
Àdàkọ:Birth year
Iroko, Oyo State, Nigeria
Ọjọ́ aláìsíSeptember 21, 2020
ÈdèYorùbá
Genreplays

Láwuyì Ògúnníran (5 November 1935 – 21 September 2020) jẹ́ òǹkọ̀wé eré ní Nàìjíríà tó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ní èdè Yorùbá.[1][2] Eré rẹ̀, Eégún Aláré, jẹ́ iṣẹ́ tí gbogbo ayé tẹ́wọ́ gbà, ó sì jẹ́ ìwé tí a nílò fún kíláàsì lítíréṣọ̀ Yorùbá ní ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ girama ní Nàìjíríà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé ẹ̀kọ́ ti jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ láti ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn oríṣiríṣi iṣẹ́ rẹ̀, pẹ̀lú ìwé-ẹ̀kọ́ PhD kan láti ọwọ́ Saudat Adébísí Hamzat ní Yunifásítì ti Ìlọrin, tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ A New Historicist Analysis of Selected Plays of Láwuyì Ògúnníran ati Olú Owólabí.[3] Dúrótoyè Adélékè, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú Ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀dá-édé àti Áfíríkà ní Yunifásítì Ìbàdàn ti tún ṣàyẹ̀wò lórí ‘Shakespearean Fool’ nínú iṣẹ́ Ògúnníran pẹ̀lú eré onítàn mẹ́ta láti ọwọ Adébáyọ̀ Fálétí, Ọláńrewájú Adépọ̀jù àti Afọlábí Ọlábímtán.[4] Àwọn mìíràn ti ṣiṣẹ́ lórí àyẹ̀wò àwọn ewì àti ọ̀nà àsọyé tí òṣèré náà ń lò nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀.

Àwọn Àtẹ̀jáde

àtúnṣe

Ààre-àgò Aríkùyerì [5]

Eégún Aláré [6]

Ọmọ Alátẹ́ Ìlẹ̀kẹ̀ [7]

Ìbàdàn Mesìọ̀gọ̀: Kìnnìún ilẹ̀ Yorùbá (1829–1893) [8]

Ọlọ́run ò màwàda [9]

Àtàrí àjànàku [10]

Igi wọ́rọ́kọ́ [11]

Nibo laye dori ko? [12]

Ọ̀nà kan ò wòjà [13]

Abínúẹni (coauthored with Yẹmí Ọmọ́táyọ̀) [14]

Ààrò Mèta Àtọ̀runwá! [15]

Ìṣe tí Àwọn Yorùbá Ńṣe [16]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Lawuyi Ogunniran, àgbà ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé Eégún Aláré dágbére fáyé!". BBC News Yorùbá. 2020-09-22. Retrieved 2020-09-30. 
  2. Boscolo, Cristina (2009) (in en). Ọdún: Discourses, Strategies, and Power in the Yorùbá Play of Transformation. New York: Rodopi. pp. 24. ISBN 978-90-420-2680-3. https://books.google.com/books?id=9PsbR01ZUTAC&q=lawuyi+ogunniran&pg=PA24. 
  3. "Unilorin bulletin 18th April, 2016". Issuu (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-09-30. 
  4. (in en) Focus on Nigeria: Literature and Culture. https://books.google.com/books?id=lssk82aVJJ0C&q=lawuyi+ogunniran&pg=PA8. 
  5. Ogunniran, Lawuyi (1977) (in yo). Ààre-àgò aríkùyerì. Macmillan Nigeria Publishers. https://books.google.com/books?id=egh3AQAACAAJ. 
  6. Ogunniran, Lawuyi (1972) (in yo). Eégún Aláré. Macmillan Nigeria. https://books.google.com/books?id=lJQ7nQAACAAJ. 
  7. Ògúnníran, Láwuyì (1996) (in Yoruba). Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀. Ibadan, Nigeria: Lolyem Communications. https://www.worldcat.org/oclc/39742459. 
  8. Ogunniran, Lawuyi (2000). Ìbàdàn Mesìọ̀gọ̀: Kìnnìún ilẹ̀ Yorùbá (1829-1893). Ibadan: Vantage. https://www.worldcat.org/oclc/667620284. 
  9. Ogunniran, Lawuyi (1991) (in Yoruba). Ọlọ́run ò màwàda. Ibadan: Frontline Publishers. http://catalog.hathitrust.org/api/volumes/oclc/31742068.html. 
  10. Ogunniran, Lawuyi.. Atari ajanaku.. Ibadan, Nigeria : Evans Brothers, 1987. https://catalog.hathitrust.org/Record/010124145. 
  11. Ogunniran, Lawuyi (1998) (in yo). Igi wọ́rọ́kọ́. Lolyem Communications. https://books.google.com/books?id=wR4kAQAAMAAJ. 
  12. Ọgúnníran, Láwuyì (1980) (in Yoruba). Níbo layé dorí kọ?. Ikeja, Nigeria: Longman Nigeria. https://www.worldcat.org/oclc/33832610. 
  13. Ogunniran, Lawuyi (1991) (in Yoruba). Ọ̀nà kan ò wọjà. Ikeja: Longman Nigeria. https://www.worldcat.org/oclc/31742069. 
  14. Ọmọ́táyọ̀, Yẹmí (1997) (in yo). Abínúẹni. Lolyem Communications. https://books.google.com/books?id=qiYkAQAAMAAJ. 
  15. Ògúnníran, Láwuyi (1993) (in Yoruba). Ààrò Mẹ́ta Àtọ̀runwá!. Ibadan, Nigeria: Vantage Publishers. https://www.worldcat.org/oclc/39782269. 
  16. Ogunniran, Lawuyi. Ìwé Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá. Ibadan: Ibadan University Press.