Lateef Adédiméjì

Lateef Adédiméjì (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kìíní oṣù kejì ọdún 1986) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré, oǹkọ̀tàn àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn ṣùgbọ́n tí wọ́n bí sí ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Lọ́dún 2013 ni ìràwọ̀ rẹ̀ gbòde kan lẹ́yìn látàrí ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Kudi Klepto", tí Yéwándé Adékọ̀yà ṣe agbátẹrù rẹ̀. Lateef Adédiméjì tí kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó ti ju ọgọ́rùn-ún lọ lẹ́yìn tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn. Ó gbajúmọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ilé iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ Airtel fi fi í ṣe aṣojú wọn.[1] [2]

Lateef Adedimeji
Lateef Adedimeji at AMVCA 2020.jpg
Ọjọ́ìbíAbdullateef Adedimeji
(1986-02-01)1 Oṣù Kejì 1986
Oshodi, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Orúkọ míràn"Crying Machine"
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́
  • Actor
  • Filmmaker
  • Scriptwriter
  • Director
  • Producer
Ìgbà iṣẹ́2007- Present

Ìgbé-ayé àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀Àtúnṣe

Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, wọ́n bí Lateef Adédiméjì ní Ọjọ́ kìíní oṣù kejì ọdún 1986 ni ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn ni.[3] O kàwé gboyè dìgírì nínú ìmọ̀ ìwé ìròyìn, ni ifáfitì Yunifásítì Olabisi Onabanjo.[4]

Àwọn Ìtọ́kasíÀtúnṣe