House of Ga'a

Fíìmù ajẹmọ́tàn ti Nàìjíríà

House of Ga'a (Ilé Ga'a) jẹ́ fíìmú ajẹmọ́tàn ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ọdún 2024, èyí tí olúdarí rẹ̀ jẹ́ Bolanle Austen-Peters, tí Tunde Babalola sì kọ ìtàn náà kalẹ̀. Ó ṣàfihàn àwọn òṣèré bí i Femi Branch, Bimbo Manuel, Stan Nze, Lateef Adedimeji, Mike Afolarin, Toyin Abraham àti Funke Akindele.[1][2]

House of Ga'a
Fáìlì:Official cover art for House of Ga'a movie 2024.jpg
Written byTunde Babalola
Directed byBolanle Austen-Peters
Starring
Country of originNigeria
Original language(s)Yoruba
English
Production
Running time120 minutes[1]
Production company(s)BAP Productions
Release
Original networkNetflix
Original releaseOṣù Keje 26, 2024 (2024-07-26)

Àhunpọ̀ ìtàn

àtúnṣe

Ìtàn náà jẹ́ ajẹmọ́tàn, tó dá lé lórí ìṣẹ̀lè kan tó ṣẹ̀ ní Ọ̀yọ́, ní sẹ́ńtúrì kejìdínlógún. House of Ga'a sọ ìtàn Baṣọ̀run kan tó ṣi agbára lò, tí agbára sì gùn ún débí tó fi ṣìṣe. Látàri ìwà ọ̀kánjúwà rẹ fún agbára, ó gbé ìgbésẹ̀ láti ju àwọn ọba tó yàn án sípò lọ. Ìtàn náà sọ nípa ìdàlẹ̀, àti bí ènìyàn ṣe ṣi agbára lò nínú ìṣèjọba ìbílẹ̀.[3][4]

Àwọn òṣèré tó kópa

àtúnṣe

Orísun:[5][6]

Àgbájáde àti ìtẹ́wọ́gbà

àtúnṣe

Wọ́n ṣàgbéjáde fíìmù yií sí orí Netflix ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù keje, ọdún 2024.[7] Enitan Abdultawab ti Vanguard gbóríyìn fún fíìmù yìí, tó si sọ̀rọ̀ dáadáa nípa àwọn òṣèré tó kópa, ìyàwòrán àti àhunpọ̀ ìtàn náà.[8] Stephen Onu ti Premium Times gbóríyìn fún Femi Branch fún ẹ̀dá ìtàn Baṣọ̀run Gá'à tó ṣe. Onu fi lélẹ̀ pé: "ìṣesí àti ìhùwásí Femi Branch nínú fíìmù yìí ṣe àpejúwe Baṣọ̀run Gá'à , tó jẹ́ alágbára àti onígbèéraga tó padà kàndí nú iyọ̀."[9] Ní àkóótán Onu kọ pé: "Ìtàn yìí dáni lára yá, ó sì tún kọ́ni lọ́gbọ̀n rẹpẹtẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ ìtàn náà lọ́ná tí ó fi máa wùn ènìyàn láti wò."[9]

Chima Ugo ti The Board kọ nípa àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ tó farahà nínú fíìmù yìí. Ó ṣàlàyé pé àwọn ìtàn inú fíìmù yìí ò tọ̀nà pẹ̀lú ìṣẹ̀lè tó ṣè gan-an gan ní Ọ̀yọ́ lásìkò tí Baṣọ̀run Gá'à jẹ oyè yìí.[7]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Ugo, Chima (28 July 2024). "Movie Review: House of Ga'a, a historical error". The Board. Retrieved 7 August 2024. 
  2. Toromade, Samson (3 June 2024). "Bolanle Austen-Peters' Bashorun Ga'a film will stream on Netflix". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 17 July 2024. 
  3. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Chima2
  4. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Toromade2
  5. Adedayo, Adedamola (2024-06-21). "Bolanle Austen-Peters' Period Film "House of Ga'a" Comes To Netflix On July 26th". The Culture Custodian (Est. 2014.) (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-07-17. 
  6. "Netflix's "House of Ga'a" Gets Release Date, Debuts New Stills". Nollywood Reporter (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-07-17. 
  7. 7.0 7.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Chima3
  8. Abdultawab, Enitan (8 August 2024). "Movie Review: Bolanle Austen-Peter's House of Ga'a models history brilliantly". Vanguard. Retrieved 7 August 2024. 
  9. 9.0 9.1 Onu, Stephen (28 July 2024). "MOVIE REVIEW: Bolanle Austen-Peter’s epic film House of Ga'a is simply brilliant". Premium Times. Retrieved 7 August 2024.