Lauren Liebenberg

(Àtúnjúwe láti Lauren liebenberg)

{Use dmy dates|date=February 2014}}

Lauren Liebenberg
Ọjọ́ ìbí3 Oṣù Kẹjọ 1972 (1972-08-03) (ọmọ ọdún 52)[1]
Zimbabwe
Iṣẹ́Writer
Ọmọ orílẹ̀-èdèSouth African
Notable worksThe Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam The West Rand Jive Cats Boxing Club Cry Baby

Lauren Liebenberg (a bii ni ojo keta, osu ogun,odun 1972) jẹ́ òǹkọ̀we omo orile ede South Africa tí wọ́n bí sí Zimbabwe . Ìwe rẹ̀ àkọ́kọ́ ti akori re n jeThe Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam gba àmi ìdánimọ̀ ti Orange Prize for Fiction ní ọduń 2008.[2] Àwọn ìwé re tí ó kọ lẹ́yin ti akoko rẹ̀ ni;The West Rand Jive Cats Boxing Club àti Cry Baby, náà ni awon lameeto ti se agbeyewo re káàkiri àgbáyé.[citation needed]

Ìpìlẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Liebenberg ni Rhodesia sugbon gegebi omode láti kékeré ni ó ti fi ilu Zimbabwe silẹ lọ sí ilẹ olòmìnira ti South Africa; eléyìí tí wọ́n jọ pín ààlà . Ó lọ sí Brescia House; èyi tí ó jẹ́ ilé-eko ijo Aguda fún àwọn obìrin ni Johannesburg. Lẹ́yìn tí ó kẹ́kọ̀ọ́-gboyè kín-ní ní University of South Africa, ó gbé ní orílẹ̀-ède England fún ọdún díẹ̀, kí ó tó padà sí South Africa, níbití ó ti kẹ́kọ̀ọ́-gboyè ní ilé-ìwe akọ́nilókòòwò ti University of the Witwatersrand níbití ó ti gba ìwe-ẹ̀ri masita digiri (MBA). Ó ṣiṣẹ́ ni ilé-ìfowopamọ́ adánilókòwo;tí ó sì ṣe àtẹ̀jáde ní ẹ̀ka ètò ìṣúná owó, àti ị̀we atọ́ka tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́The Electronic Financial Markets of the Future; tí ó ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀ ní ọdún 2002. [3][4][5][6]

Ìwe rẹ̀ àkọ́kọ́ The Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam tí ó jẹ́ lára ìrírí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọmọdé ní Rhodesia ni ́ àkókò Rhodesian Bush War, gba ìfiyèsí púpọ̀ láti ọ̀dọ àwọn lámèétọ́ nígbàti wọ́n ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀ ní ọdún 2008. The Guardian ṣe àpèjúwe rẹ̀ ni "ayanilẹ́nu lóòtọ́ " tí ó sì tẹ̀síwájú láti sọ pé "Rhodesia súyọ bíi ilẹ̀ tútù ní ojú ènìyaǹ kúrò nínu ayé òórùn wá... gẹ́gẹ́ bíi ọkàn rírọ̀ ọmọdé... tí kìí dánilẹ́jọ́ ... aláìlágbèé-sọ́kàn, amúnibínú tị́ ó ṣe àjèjì ... tí ó múnilọ́kàn".[7]Financial Times ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi "ìwe kín-ní ajọmárò tí ó sọ nípa àìlègbèra-ẹni níjà ọdọ́mọdé Áfírikà ní ilẹ̀ aláwọ̀-funfun.The Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam Archived 2011-09-01 at the Wayback Machine.

  1. Interview with Lauren Liebenberg by Amanda Patterson Archived 25 September 2010 at the Wayback Machine. Writers Write. 25 June 2008.
  2. "Novelist who faced trial in Turkey makes long list for Orange Prize", The Independent, 18 March 2008.
  3. Liebenberg, Lauren (2002) (in en-gb). The Electronic Financial Markets of the Future. doi:10.1057/9781403946065. ISBN 978-1-349-43314-8. 
  4. An Evocative Debut from Lauren Liebenberg Archived 4 January 2011 at the Wayback Machine. Penguin. 7 April 2008
  5. The Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam Orange Prize. Retrieved on 6 November 2010
  6. Lauren Liebenberg, author of The Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam, in conversation with Janet van Eeden Archived 27 September 2011 at the Wayback Machine. Litnet. 14 May 2008
  7. Danger in the veld The Guardian. 5 April 2008