Linda Ikeji

Onkọ̀wé

Linda Ifeoma Ikeji (tí a bí ní ọjọ́ kọkándínlógún oṣù kẹsàn án ọdún 1980) jẹ́ òǹkọ̀wé, oníṣòwò, òǹkòwé sínú ìwé ìròyìn ti orí ẹ̀ro-ayélujára àti ẹni tí ó ti jẹ́ aláwòṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Linda jẹ́ ìlú mọ̀ọ́ká nítorí ìwé tí ó ma ńkọ sínú ìwé ìròyìn lórí ẹ̀rọ-ayélujára àti wípé àwọn ìwé kíkọ rẹ̀ yí sábà ma ńdá lórí i àríyànjiyàn.

Linda Ikeji

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ àti ẹ̀kọ́

àtúnṣe

Ìkéjì ni wọ́n bí tí wọ́n sì tọ́ dàgbà ní ìdílé Katoliki kan láti Nkwerre, Ipinle Imo, Nigeria . Ó jẹ́ ọmọ tí wọ́n bì ṣèkejì sínú ẹbí yìí. Ìkéjì ti bẹ̀rẹ̀ ìwé kíkọ láti ọmọ ọdún mẹ́wàá. Ó kọ́ ẹ̀kọ́ jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdírì ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún. Nígbàtí ó di ọmọ ọdún méjìdínlógún ni ó fi orúkọ sílẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Èkó níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ lórí èdè gẹ̀ẹ́sì. Nítorí àtiṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn òbí rẹ àti láti ṣe àtìlẹ́yìn fún ara rẹ̀ lórí ẹ̀kọ́ rẹ, Ìkéjì má ńlọ ṣe iṣẹ́ ní àkókò tí kò bá sí ní ẹnu ẹ̀kọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí onídìúró láti gba àlejò, aláwòṣe àti òǹkọ̀wé.[1] Ìkéjì kọ́ ẹ̀kọ́ gboyè ní Yunifásítì ní ọdún 2004. Ní ọdún 2006, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ ìwé sínú ìwé ìròyìn orí ẹ̀rọ ayélujára gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí ó yàn ní ààyò. Ní àkókò yí í, ẹ̀ro ayélujára kò tíì gbinlẹ̀ yíká ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìdí èyí ni ó fi ní láti máa ṣe iṣẹ́ àwọn ìfìwéránṣẹ́ rẹ ní cybercafe.[2]

Àwọn iṣẹ́ tí Linda Ikeji mọ dájúdájú.

àtúnṣe

Ìkéjì bẹ́rẹ́ iṣẹ́ ìwé kíkọ sí orí ẹ̀rọ ayélujára ní ọdún 2006[3]. Ó di ògbóntàrigì nínú òǹkọ̀wé orí ẹ̀rọ ayélujára ní ọdún 2007 nípa lílo sub-domain blogs: www.lindaikejisblog.com[4].

Ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹjọ ọdún 2016, lórí ẹ̀rọ ayélujára rẹ, ó kéde ìdásílẹ̀ ẹ̀rọ amóhùńmáwòrán ti orí ayélujára tirẹ̀ tí ó pè ní ẹ̀rọ tẹlifísànù tí Linda Ìkejì ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbé pẹ̀lú àwọn búrándì mìíràn tí ó ńfi ìdí wọn múlẹ̀. Oríṣiríṣi ètò ni ẹ̀rọ tẹlifóònù Linda Ìkejì má a ń gbé jáde lórí afẹ́fẹ́ tí ó fi mọ́ àfihàn ọ̀rọ̀ sísọ, àwọn eré tẹlifísànù lóríṣiríṣi tí ó fi mọ́ àwọn sinimá. Netiwoki yi ṣe àgbéjáde díẹ̀ nínú àwọn ètò rẹ àti wípé ó tún ra àwọn àkọ̀ọ̀nù tẹlẹfíṣánù. Ikeji tún dáwọ́lé ètò agbóhùn sí afẹ́fẹ́ ti orí i ayélujára. Ibùdó Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ yi ńṣe iṣẹ́ láti ọ́fìsì àwọn ohun ìgbéròhìnjáde ti Linda Ikeji. Lára àwọn ètò o rẹ̀ ni wọ́n ń gbé sí afẹ́fẹ́ lórí i tẹlifísíọ̀nù Linda Ikeji.[5]

Ikeji tún ṣí pẹpẹ orin kan tí a mọ̀ sí orin Linda Ikeji èyí tí ó ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹ rẹ̀ ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kọkànlá ọdún 2016, ṣùgbọ́n eléyì í kò gbèèrú sókè lẹ́hìn oṣù mẹ́ta tí wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹ rẹ̀. Ó ṣe ìfilọ́lẹ̀ pẹpẹ nẹ́tìwọọkì àwùjọ kan tí wọ́n ńpè ní LindaIkejiSocial.com. Ikeji ń ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe kan tí kìí ṣe lórí èrè tí àkórí rẹ ńjẹ́ "Mo fẹ́ kúkú jẹ́ tí ara à mí; Bẹ́ẹ̀kọ́ o ṣeun". Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ tẹlifísìọ́nú HipTV, ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé nípasẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe yìí ni òun fi máá ńṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ bìnrin kékeré tí ó wà ní ọdún mẹ́rìndínlógún sí ọdún má rùndínlọ́gbọ̀n tí wọ́n ní àwọn ìmọ̀ràn ìṣòwò ń lá tí wọ́n sì ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ okòwò. Ó fún wọn ní àpapọ̀ iye owó tí ó tó mílíọ̀nù mẹ́wàá naira ní ìpele àkọ́kọ́ iṣẹ́ náà.

Àwọn oun tí wọn fí dá Linda Ikeji mọ̀

àtúnṣe

Ní oṣù kẹjọ ọdún 2021, ni Forbes Áfíríkà ṣe agbátẹrù fún ayẹyẹ àwọn obìnrin Áfíríkà. Nínú ayẹyẹ náà, Forbes ṣe àlàyé lórí àwọn obìnrin oogún tí wọ́n jẹ́ gbajúmọ̀ jùlọ ní ilẹ̀ Áfíríkà tí ó sì jẹ́ wípé àlàyé yìí ṣe àfihàn àwọn prófáìlì lórí àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ọmọ Nàíjíríà méjì:⁷:

Linda Ikeji ati Chibundu Onuzo[6]. Orúkọ ti Linda Ikeji ni ó pọ̀jù lọ tí àwọn tí ń lo ẹ̀rọ ayélujára ti Google ní ilẹ̀ Nàìjíríà ń wá lòri ẹ̀rọ ayélujára yìí.[7] Ikeji sọ àwọn ìpinnu rẹ̀ fún ọdún tuntun ní ọdún 2020[8].

Ní ọdún 2016, Ikeji kólọ sí ilé e rẹ̀ èyí tí ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù owó náírà kọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ó wá sí ibi ayẹyẹ yìí ní pàtàkì àwọn obìnrin ní ilẹ̀ Nàìjíríà.

Àwọn àwọn akọ̀ròyìn ń ilé iṣẹ́ BBC fi ọ̀rọ̀ wá Ikeji lẹ́nu wò lórí ètò wọn tí wọn ń pè ní Ìfojúsí lórí Áfíríkà. Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yí wáyé lórí afẹ́fẹ́ ní ọ jọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn án ọdún 2012[9].

Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹjọ ọdún 2018, Linda Ikeji wà lára àwọn ènìyàn pàtàkì tí wọ́n mú lá ti inú oríṣiríṣi ẹ̀yà iṣẹ́ àti oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè láti fi àmì ẹ̀yẹ dá wọn lọ́lá. Àmì ẹ̀yẹ ti ọ̀jọ̀gbọ́n láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Trinity International tí ó wà ní ilẹ̀ Georgia ni wọ́n fi dá Linda Ikeji lọ́lá fún àwọn iṣẹ́ rẹ tí ó tayọ nínú ìṣòwò àti ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní Áfírík. Lára àwọn tí wọ́n tún dá lọ́lá ni Steve Egboro ẹni tíí ṣe olùṣe fíìmù àti alákòso ayẹyẹ, ọ̀gá àgbà fún ìwé ìròyìn Daily Times, ọ̀mọ̀wé Fidelis Anosike, ọ̀mọ̀wé Obeahon Ohiwerei, ọ̀gá àgbà ilé ìfowópamọ́ ti keystone, agbẹjọ́rọ̀ olókìkí, Mike Ozekhome àti àwọn díẹ̀ míràn.[10]

Àwọn Àríyànjinyàn

àtúnṣe

Ikeji ti bá wọn kópa nínú àtẹ̀ránṣé alárìyànjiyàn èyí tí ó pẹ̀lú ìpolongo #SaveMayowa àti nípa àwọn olókìkí bíi Funke Akindele, Richard Mofe Damijo, Djimon Honsou, Wizkid àti Tonto Dikeh[11][12]. Ó tún ṣe àwọn àtẹ̀jáde àríyànjiyàn nípa olóṣèlú. Doyin Okupe ṣe àpàjúwe àwọn àtẹ̀jáde náà bíi àbùkù.[13]

Buloogi Ikeji ni wọ́n tìpa ní ọjọ́ kẹjọ oṣu kẹwàá ọdú 2014 ṣùgbọ́n ẹ̀rọ ayélujára Google dá buloogi yí padà ní alẹ́ ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá ọdún 2014 fún àwọn ìdí tí wọn kò ṣe àláyé wọn. Gégébí Taiwo Kola-Ogunlade, ẹnití ó jẹ́ agbẹnusọ fún Google ní ìla òòrùn Áfíríkà ti sọ, ó ní "A mú rírú òfin ìlànà ní òkúkúndùn nítorí irú àwọn ǹkan báyìí máa ń mú mu ìrẹ̀wẹ̀sì wá nípa ìrírí àwọn tí wọ́n ńlo òpó ayélujára wa. Nígbàtí wọ́n bá ti fi tó wa létí nípa àkòonù tí ó lè rú àwọn òfin iṣẹ́ ẹ wa, a má ń yara kánkán láti ṣe àtúnyẹ̀wò rẹ kí ó sì pinnu bóyá ó lòdì sí àwọn ètò wa, tí a bá ti ṣe ìpinnu pé ó lòdì, a máa yọ ọ́ kúrò lẹ́sèkẹsẹ̀"[14]

Nígbàtí tí Linda ṣe àfihàn pé òún ti lóyún, eléyìí fa àríyànjiyàn látàri bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyáàfin tí wọ́n ń fi Linda Ikeji tí ó maa ń wàásù nípa àìbíkìtà ná à ni ó wá lọ lóyún.[15]

Ní ọdún 2018, olóòtú ìwé ìròyìn ẹ̀rọ ayélujára fún ìwè ìròyìn Punch, John Abayomi, halẹ̀ láti pe Linda Ikeji lẹ́jọ́ fún ìròyìn tí kò tọ̀ tí Linda ń sọ nípa rẹ̀ pé òun John Abayomi ni ó ni Instablog9ja. Abayomi ṣe àlàyé látipasẹ̀ agbẹjọ́rò rẹ tí í ṣe ilé iṣẹ́ agbẹjọ́rò ti Falana tí àkọlé àtẹ̀jáde rẹ̀ si jẹ́ LIB Exclusive: "Pàdé ẹni tí ó ni Instablog9ja John Abayomi". Ó tún sọ wípé àtẹ̀jáde yìí fi ìgbésí ayé òun àti ti mọ̀lẹ́bí òun sínú ewu.[16]

Ìgbésí ayé e rẹ̀.

àtúnṣe

Ikeji sọ pé òun àti bàbá ọmọ òun tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Shlaye Jeremi kìí ṣe aláàṣiṣẹ́pò tí ó dára. Ó sọ nínú buloogi rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìdí tí ìbáṣepọ̀ òun àti bàbá ọmọ rẹ̀, ẹnití ó pàdé ní oṣù kejìlá ọdún 2015 kò ṣe dáńmọ́rán bí ó ti ye.[17]

Àwọn iyì àtí àwọn ẹ̀yẹ.

àtúnṣe
Àwọn àmì ẹ̀yẹ Ọdún Ẹ̀ka
Nigeria Blog Awards NBA Ọdún 2013 Best Entertainment Blog[18]
Nigerian Broadcasters Merit Awards Ọdún 2013 Website/blog of the year[19]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Linda Ikeji". Legit.ng - Nigeria news. 2021-08-02. Retrieved 2021-08-02. 
  2. Adeniyi, Wale (2015-10-15). "What You Didn’t Know about Linda Ikeji – Africa's Biggest Blogger - TheNews.NG". TheNuews.NG. Archived from the original on 2016-05-03. Retrieved 2021-08-02.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Gist Flare » Home of Entertainment". Gist Flare. 2021-06-09. Retrieved 2022-01-20. 
  4. Taiwo, Ibukun (2015-09-30). "Linda Ikeji finally gets her own domain name". TechCabal. Retrieved 2022-01-20. 
  5. Mirilla, Dennis Da-ala (2018-08-29). "How Nigerian Female Mediaprenuers Are Taking Over The Tech Industry - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Archived from the original on 2022-01-20. Retrieved 2022-01-20. 
  6. "You Want To Become A Blogger? Here Are Beginers Guide Mp3 DOWNLOAD". JessyNaija. 2016-11-24. Archived from the original on 2022-01-20. Retrieved 2022-01-20. 
  7. "You Want To Become A Blogger? Here Are Beginers Guide Mp3 DOWNLOAD". JessyNaija. 2016-11-24. Archived from the original on 2022-01-20. Retrieved 2022-01-20. 
  8. "If I cancel you, you will stay cancelled - Linda Ikeji shares new year resolution Mp3 DOWNLOAD". JessyNaija. 2020-01-22. Archived from the original on 2022-01-20. Retrieved 2022-01-20. 
  9. "Nigerian blogger Linda Ikeji on gossip and news". BBC News. 2012-09-25. Retrieved 2022-01-20. 
  10. Nwanne, Chuks (2018-08-18). "Filmmaker, Egboro bags honorary doctorate degree in Atlanta - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved 2022-01-20. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  11. "RMD Fights Linda Ikeji?Tells Her To Get A Life - nigeriafilms.com". nigeriafilms.com. 2015-02-20. Archived from the original on 2015-02-20. Retrieved 2022-01-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  12. "Wahala ! You Dey Find! Tonto Dikeh Calls Linda Ikeji A Failed Model; Oouch". Gistmania. 2011-09-01. Retrieved 2022-01-20. 
  13. Nomjov, Chris (2015-02-14). "Defamation: Okupe's Lawyers Write Linda Ikeji; Demand Retraction And Published Apology Over False Story". NewsWireNGR. Retrieved 2022-01-20. 
  14. "Google restores Linda Ikeji Blog". Premium Times Nigeria. 2014-10-10. Retrieved 2022-01-20. 
  15. "Linda Ikeji apologises to fans for having child out of wedlock". Premium Times Nigeria. 2018-12-14. Retrieved 2022-01-20. 
  16. "John Abayomi denies ownership of Instablog9ja, threatens to sue Linda Ikeji - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2018-11-17. Archived from the original on 2022-01-20. Retrieved 2022-01-20. 
  17. "My baby Daddy and I are not suitable–Linda Ikeji". Vanguard News. 2018-12-14. Retrieved 2022-01-20. 
  18. "2013 Nigerian Blog Awards winners!". Nigerian Blog Awards. Archived from the original on 19 February 2015. Retrieved 19 February 2015. 
  19. "Here are the Nominees for Nigerian Broadcasters Merit Awards 2013 - Olori Supergal" (in en-US). Olori Supergal. 31 October 2013. Archived from the original on 19 April 2019. https://web.archive.org/web/20190419134117/https://olorisupergal.com/2013/10/31/here-are-the-nominees-for-nigerian-broadcasters-merit-awards-2013/.