Liu Yandong (Àdàkọ:Zh; tí wọ́n bí ní ọjọ́ méjìlélógún oṣù kọkànlá ọdún 1945 nẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè China tí ó ti fìgbà kan tẹ́lẹ̀ rí jẹ́ igbákejì olórí orílẹ̀-èdè China tẹ́lẹ̀ rí, ó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Politburo of the Communist Party of China láàrín ọdún 2007 sí 2017, ó sì tún jẹ́ àbójútó ní Ìpínlẹ̀ kan ní orílẹ̀-èdè China, ba kan náà ni ó tún adarí fún ilé-iṣẹ́ United Front Work Department lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Comminuty láàrín ọdún 2002 sí 2007. Liu ni ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé-ẹ̀kọ́ Tsinghua University, ni ó sì ti ń ṣiṣẹ́ ribiribi fún ilé-ẹ̀kọ́ náà gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ jáde lábẹ́ ẹgbẹ́ 'Communist Youth League Hu Jintao, fúndí èyí, ìwé ìròyìn kan tilẹ̀ ṣe àpèjúwe Liu gẹ́gẹ́ bí "Tuanpai" ní èdè China, tàbí "Youth League clique" ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Liu ni wọ́n tún mọ̀ gẹ́gẹ́ bí gbajú-gbajà obìnrin olóṣèlú lẹ́yìn tí arabìnrin Wu Yi, ti fẹ̀yìn tí gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú ní orílẹ̀-èdè China.[1]

Liu Yandong
刘延东
Liu Yandong in 2016
Vice Premier of the People's Republic of China
In office
March 16, 2013 – March 19, 2018
Serving with Zhang Gaoli, Wang Yang, Ma Kai
PremierLi Keqiang
State Councilor of the People's Republic of China
In office
March 17, 2008 – March 16, 2013
Serving with Liang Guanglie, Ma Kai, Meng Jianzhu, Dai Bingguo
PremierWen Jiabao
Head of the United Front Work Department of the Central Committee
In office
December 2002 – December 2007
General SecretaryHu Jintao
AsíwájúWang Zhaoguo
Arọ́pòDu Qinglin
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí22 Oṣù Kọkànlá 1945 (1945-11-22) (ọmọ ọdún 79)
Nantong, Jiangsu
Ọmọorílẹ̀-èdèChinese
Ẹgbẹ́ olóṣèlúCommunist Party of China
Alma materTsinghua University
Liu Yandong with the President of Israel Reuven Rivlin March, 2016
Liu Yandong
Simplified Chinese 刘延东
Traditional Chinese 劉延東


Ibẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ olóṣèlú

àtúnṣe

Liu Yandong ni wọ́n bí ní agbègbè Nantong, ní Jiangsu tí ó jẹ́ olú-ìlú fún orílẹ̀-èdè China nígbà náà. Bàbá rẹ̀ Liu Ruilong ni ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn olùdásílẹ̀ 14th Army of the Reds, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n dá sílẹ̀ láti fi ìjìjà-n-gbara. Àwọn ènìyàn ma ń bu ọlá fún Yandong látàrí wípé bàbá rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn tí awọ́n ja ìjàngbara fún orílẹ̀-èdè èdè China, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n ma ń tọ́ka sí Liu gẹ́gẹ́ bí princeling. Liu wọ ilé ẹ̀kọ́ Tsinghua University ní ọdún 1964,tí ó sì kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ọdún 1970 gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìṣègùn. Ní àsìkò tí ó wà ní akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́, ó wà lára àwọn tí wọ́n kọ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìṣèlú. Lẹ́yìn tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè, ó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣíṣẹ́ gẹ́gẹ́ onímọ̀ ìpoògùn ní ìlú Tangshan. Ní ọdún 1980, wọ́n gbe lọ láti lọ ṣiṣẹ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú kan ní ìlú Beijing, wọ́n sì fi ṣe ìgbá kejì olórí ẹgbẹ́ ọ̀hún ní ọdún 1981, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣiṣẹ́ fún ẹgbẹ́ Communist Youth League ní ọdún 1982 níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ kan Wang Zhaoguo, Hu Jintao, àti Song Defu. Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Youth League fún odidi ọdún mẹ́sàn an gbáko. She worked at the Youth League for nine years. During this time she served as Chairwoman of the All-China Youth Federation.

Nígbà tí ó di inú osù kẹta 9d7n 1991, Liu bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú United Front Work Department gẹ́gẹ́ bí igbá kejì akọ̀wé àgbà. Ẹnu ìṣeẹ́ yí ni ó wà tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ọ̀mọ̀wé àti ọ̀jọ̀gbọ́n ní ilé ẹ̀kọ́ Renmin University àti Jilin University.

Iṣẹ́ rẹ̀ ní United Front Work

àtúnṣe

Láàrín ọdún 2002 sí 2007, ó ṣiṣẹ́ ngẹ́gẹ́ bí adarí United Front Work, wọ́n sì yàn an sípò igbá kejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú Chinese People's Political Consultative Conference. Látàrí wípé ó ti ṣíṣe pẹ̀lú akọ̀wé àgbà àgbà ẹgbẹ́ náà, ìyẹn Hu Jintao, ati ipa ribiribi tí ó ti kò nínú Communist Youth League, ó wọ inú ẹgbẹ́ òṣèlú Politburo of the Communist Party of China ní ọdún 2007. Dídara pọ̀ tí ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ yí ni wọ́n ti ń fojú sùn ún wípé ó lè di igbákejì aṣojú ẹkùn rẹ̀. Liu ni ó ẹ́ obìnrin olóṣèlú kan ṣoṣo tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ jùlọ tí ó sì ṣe é ṣe kí ó de ipò Politburo tí ó jẹ́ ipò ìṣèlú tí ó ga jùlọ nílẹ̀ China. Ní àsìkò ìdìbò, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí igbákejì sí ipò State Council, lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú . Oun náà tún ni wọ́n fi ṣe ìgbà kejì alága Beijing Organizing Committee for the Olympic Games.

Ìgbé ayé rẹ̀

àtúnṣe

Liu ṣe ìgbéyàwó ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹrin ọdún 2009, ilé-ẹ̀kọ́ Stony Brook University fi amì-ẹ̀yẹ Doctor of Laws da arabìnrin Liu lọ́lá.

Ẹ tún lè wo

àtúnṣe

Àwọn itọ́ka sí

àtúnṣe

Àwọn Ìtàkùn ìjásóde

àtúnṣe


Àdàkọ:S-ppoÀdàkọ:S-endÀdàkọ:17th Politburo of the Communist Party of ChinaÀdàkọ:18th Politburo of the Communist Party of ChinaÀdàkọ:12th State CouncilÀdàkọ:Vice Premiers of the People's Republic of ChinaÀdàkọ:State councillorsÀdàkọ:CPPCC Vice-ChairpersonsÀdàkọ:Authority control
Preceded by
Wang Zhaoguo
Head of the CPC Central Committee United Front Work Department
2002–2007
Succeeded by
Du Qinglin