Máyọ̀wá Adégbilé tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù Kẹ̀sán ọdún 1986 jẹ́ gbajúmọ̀ afowóṣàánú ọmọ Nàìjíríà. Ó wà lára àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́ta tí wọ́n yàn mọ́ àwọn akẹgbẹ́ wọn ní Áfíríkà fún àṣeyọrí ìdíje Google lọ́dún 2014. [1] Máyọ̀wá kọ́kọ́ ló ìkànnì YouTube láti ṣe ìkówójọ fún ilé-iṣẹ́ afowóṣàánú rẹ̀, Ashake Foundation, èyí tí ó dá sílẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ àwọn abiyamọ opó, ó máa ń fún wọn ní irinṣẹ́ láti ṣòwò jẹun àti láti rán ebilí wọn lọ́wọ́.[2]

Máyọ̀wá Adégbilé
Mayowa Adegbile in Abuja, Nigeria
Ọjọ́ìbíMáyọ̀wá Abíọ́lá Adégbilé
10 Oṣù Kẹ̀sán 1986 (1986-09-10) (ọmọ ọdún 38)
Nàìjíríà, Èkó
Orílẹ̀-èdèỌmọ Nàìjíríà
Ẹ̀kọ́Enterprise Development Center Lagos Business School Social Sector Management
Iṣẹ́Afowóṣàánú, Olùkọ́
Websiteashakefoundation.org

Ilé-iṣẹ́ afowóṣàánú, Ashake (Foundation)

àtúnṣe

Máyọ̀wá bẹ̀rẹ̀ Ashake Foundation, ilé-iṣẹ́ afowóṣàánú fún àwọn abiyamọ opó lọ́dún 2012 pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ fún méjìlélógún opó àti àwọn ọmọ mẹ́rìndínlógójì, tí ó pèsè ìrànlọ́wọ́ owó àti ohun èlò okowò fún. Èyí tí mú kí púpọ̀ nínú kúrò nínú ìṣẹ́, tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ sìn padà sí ilé-ìwé .[3]

Àwọn àmìn-ẹ̀yẹ

àtúnṣe

Máyọ̀wá gba àmìn-ẹ̀yẹ ti Junior Chamber International lóṣù keje ọdún l 2017, gẹ́gẹ́ bí ọkàn nínú àwọn ọmọdé mẹ́wàá lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n mókè nínú afowóṣàánú adarí ọ̀fẹ́.[4]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe