Mọ́skò
Mọsko ni olú-ìlú Rọ́síà. Ìlú nlá ni. Orí odò Moskva ni ó wà. Odún 1918 ni ó di olú-ìlú USSR nígbà tí wón gbé olú-ìlú yìí kúrò ní Leningrad. Moscow ni ìlú tí ó tóbi jù ní Rósíà. Oun ni ó wà ní ipò kefà tí a bá ní kí á ka àwon ìlú tí ó tóbi ní ilé-ayé. Ìlú tí ó léwà ni Moscow. Uspenki Cathedral tí ó wà ní ibè ni wón ti máa n dé àwon tsar (àwon olùdarí Rósíà) lade láyé àtijó. Ibè náà ni Arkhangelski tí wón ti n sin wón wà. Ilé-isé àti Ilé-èko pò ní ibè Lára àwon ilé-èkó ibè ni. Lomonosov University tí ó jé University ìjoba wa ni ibe. Orí òkè Lenin ni wón kó o sí òun sì ni University tí ó tóbi jù ní Rósíà. Ibè náà ni USSR Academy of Sciences wa. Mùsíómù, ilé-ìkàwé àti tíátà wà níbè. Àwon Bolshoi Theatre and Ballet, the State Symphony Ochestra àti the State Folk Dance Company tí ó wà ni Moscow gbayì gan-an ni.
Mọsko | |
---|---|
Area | |
• Total | 1,081 km2 (417 sq mi) |
Population | |
• Total | 12,382,754 |
Wikimedia Commons ní àwọn amóunmáwòrán bíbátan mọ́: Mọ́skò |
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |