MC Edo Pikin
Gbadamosi Agbonjor Jonathan, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí MC Edo Pikin, jẹ́ apanilẹ́rìnín ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà . Ó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ihievbe, ìlú tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Edo ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní ọdún 2021, MC Edo Pikin gba àmì-ẹ̀yẹ ti The Humor Award (THA) fún ìsọ̀rí ti Apanilẹ́rìnín ní ọdún náà.
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apanilẹ́rìnín
àtúnṣeẸ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gbàdámásí Bernard Koboko ni ó gbà á níyànjú láti múṣẹ́ apanilẹ́rìnín lọ́kúnkúndùn ní ọdún 2014.
Edo Pickin ni olùdásílẹ̀ Every Package Entertainment. Lára àwọn àwàdà rẹ̀ tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ni Edo Pikin Undiluted. Ó sì ti ṣe àwàdà ní Voltage-of-hype, Bovi's Naughty by Nature àti Supernova Live Concert.
Ní ọdún 2020, ó ṣe ìlanilọ́yẹ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 .
Ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeMC Edo Pikin ní ìyàwó kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lily, tí wọ́n sì bí ọmọ méjì.
Àwọn àmi-ẹ̀yẹ rẹ̀
àtúnṣeỌdún | Àmì ẹ̀ye | Ẹ̀ka | Àbájáde | Ref. |
---|---|---|---|---|
2021 | The Humor Awards | Won |