Mahamat Idriss
Mahamat Idriss (ne Koundja Ouya, ọjọ.ketadinlogun Keje ọdun 1942 – ọjọ keta Oṣu Kẹwa Ọdun 1987) jẹ olufoifo giga ti ti orilẹ-ede Chad.
Iṣẹ-ṣiṣe
àtúnṣeṢaaju ominira orilẹ-ede Chad ni ọjọ kankanla Oṣu Kẹjọ ọdun 1960 o dije fun orile edè Faranse, ti o bori aṣaju orilẹ-ede Faranse ni ọdun 1960 ati 1961. [1] O tun pari ni ipo kejila ni ere Olimpiiki 1960 lakoko ti o nsoju orilẹ-ede Faranse. [2]
Fun Chad o pari ni ipo kẹsan ni ere Olimpiiki 1964 . O tun jẹ ipo ti o dara julọ ti orilẹ-ede Chad lailai ni ere ìdíje Olympic. Lori Track and Field News ni ipo agbaye lododun Idriss gbe ipo kẹsan ni ọdun 1961, kẹwa ni ọdun 1964 ati kẹjọ ni ọdun 1966.
Fifo ti ara ẹni ti o dara julọ jẹ mita 2.17, ti o waye ni Oṣu Kẹrin ọdun 1966 ni Fort-Lamy . Eyi tun jẹ ami eyé ti orilẹ-ede Chad, botilẹjẹpe o ti dọgba pelu Paul Ngadjadoum ati Mathias Ngadjadoum ni ọdun 1993 ati 1996 lẹsẹsẹ.
Awọn itọkasi
àtúnṣe- ↑ French Championships - GBR Athletics
- ↑ Men High Jump Olympic Games Rome 1960