Maji-da Abdi
Maji-da Abdi (tí a bí ní 25 Oṣù Kẹẹ̀wá Ọdún 1970) jẹ́ olùdarì ere àti agbéréjáde ọmọ orílẹ̀-èdè Ethiópíà.
Maji-da Abdi | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 25 Oṣù Kẹ̀wá 1970 Dire Dawa, Ethiopia |
Orílẹ̀-èdè | Ethiopian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Western Ontario |
Iṣẹ́ | Film director, film producer |
Ìgbà iṣẹ́ | 2001-present |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeA bí Abdi ní ìlú Dire Dawa ṣùgbọ́n ó gbé ní ìlú Addis Ababa títí tí ó fi pé ọmọ ọdún mẹ́rin. Lẹ́hìn ìfipáyí ètò ìjọba tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1974, ìyá rẹ̀, tí ó ti pínyà pẹ̀lú bàbá rẹ̀, sá lọ sí ìlú Nairobi ní orílẹ̀-èdè Kẹ́nyà pẹ̀lú rẹ̀. Abdi parí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama rẹ̀ ní Kẹ́nyà.[1] Nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún 17, ó kó lọ sí Kánádà pẹ̀lú ẹbí rẹ̀, níbití ó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣòwò ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga University of Western Ontario.[2] Ó rí ararẹ̀ yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n fẹ́ láti wá iṣẹ́ sí Wall Street lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́ wọn. Lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́ Abdi, ó ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún gẹ̀gẹ̀ bi oníṣẹ́ ìròyìn àti bíi agbéréjáde.[3]
Ní àwọn ọdún 1990, Abdi pàdé Bernardo Bertolucci ní ìlú Nepal, ẹnití ó n gbé ìgbésẹ̀ lọ́wọ́ láti gbé eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Little Buddha jáde. Ó pinnu láti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ níbi ìṣètò náà.[4] Ní ọdún 2001, Abdi padà sí orílẹ̀-èdè Ethiópíà ó sì darí àkọ́kọ́ fíìmù rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The River That Divides, tó n ṣe àyẹ̀wò ìgbésí ayé àwọn obìnrin Ethiópíà ní àkókò ogun Eritrean–Ethiopian.[5] Fíìmù náà gba àmì-ẹ̀ye fún ti fíìmù tó dá lóri ẹ̀tọ́ ọmọènìyàn.[6]
Abdi tún ṣiṣẹ́ agbéréjáde. Ní ọdún 2001, ó gbé fíìmù oníṣókí kan jáde táa pe àkọ́lé rẹ̀ ní The Father látọwọ́ Ermias Woldeamlak. Abdi ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Abderrahmane Sissako gẹ́gẹ́ bi agbéréjáde àti aṣàpẹrẹ aṣọ níbi àwọn fíìmù rẹ̀ tí àkọ́lé wọn ń ṣe Waiting for Happiness (2003) àti Bamako (2006). Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀-onígbẹ̀ẹ́jọ́ fún fíìmù oníṣókí níbi ayẹyẹ àjọ̀dún <i>Cannes Film Festival</i> ti ọdún 2013.[7] Ó ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú Sissako.[8]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ "Maji-da Abdi". Women Make Movies. Retrieved 9 October 2020.
- ↑ "Maji-da Abdi". Allocine (in French). Retrieved 9 October 2020.
- ↑ "Maji-da Abdi". Cannes Film Festival. Retrieved 9 October 2020.