Mariam al-Mahdi
Mariam al-Sadiq al-Mahdi (Lárúbáwá: مريم الصادق المهدي; tí a bí ní ọdún 1965) jẹ́ olóṣèlú ọmo orílẹ̀ èdè Sudan, adarí ẹgbẹ́ òṣèlú National Umma, àti mínísítà fún ètò àwọn orílẹ̀ ède láti ọjọ́ kọkànlá oṣù kejì ọdún 2021 títí di ìgbà tí ó kọ̀wé fiṣẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ kejìlélógun ọdún kọkànlá 2021. Òun ni ọmọbìnrin Sadiq al-Mahdi, mínísítà àgbà tẹ́lẹ̀ rí fún orílẹ̀ ède Sudan.[1]
Mariam al-Mahdi | |
---|---|
مريم الصادق المهدي | |
Foreign Minister of Sudan | |
In office 11 February 2021 – 22 November 2021 | |
Alákóso Àgbà | Abdalla Hamdok |
Asíwájú | Omer Ismail (acting) |
Arọ́pò | Ali al-Sadiq Ali |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 1965 (ọmọ ọdún 58–59) Omdurman, Sudan |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | National Umma Party |
Bàbá | Sadiq al-Mahdi |
Alma mater | University of Jordan |
Ìpìlẹ̀
àtúnṣeA bí al-Mahdi sí Omdurman ní ọdún 1965. Ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Umma, ó padà di adarí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà.[1] Ó pa àmì ẹyẹ àkọ́kọ́ rẹ̀ nínú ìmọ̀ Dókítà òyìnbó ní Yunifásítì tí Jordan ní ọdún 1991, kí ó tó tẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ Dókítà àwọn ọmọdé ní Liverpool School of Tropical Medicine ní ọdún 1995.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "Mariam Al Mahdi: Revolutionary 'Kandake' as Sudan's Top Diplomat". eng.majalla.com.