Marjorie Lee Browne (September 9, 1914 – October 19, 1979) ó jẹ́ olùkọ́ ẹ̀kọ́ -ìṣírò. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ará Amẹ́ríkà-Adúláwọ̀ tó ti gba oyè ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ Dókítà ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ìṣirò.

Marjorie Lee Browne
Fáìlì:Marjorie Lee Browne.jpg
Ọjọ́ìbí(1914-09-09)Oṣù Kẹ̀sán 9, 1914
Atlanta, Georgia
AláìsíOctober 19, 1979(1979-10-19) (ọmọ ọdún 65)
Durham, North Carolina
Orílẹ̀-èdèAmerican
Iléẹ̀kọ́ gígaHoward University (BS)
University of Michigan (PhD)

Early life and educati Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé Rẹ̀ àti Ètò-Ẹ̀kọ́

àtúnṣe

Marjorie Lee Browne jẹ́ gbajúmọ̀ onímọ̀ ẹ̀kọ́-ìṣírò, ní ọdún 1949, ó di obìnrin kẹta tó jẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà-Adúláwọ̀ kẹta tó gba oyè ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ Dókítà nínú iṣẹ́ tó yàn láàyò. Oṣù kẹsàn-án, Ọjọ kẹsàn-án, ọdún 1914 ni a bí Browne, ní ìlú Memphis, Tennessee, àwọn òbí rẹ̀ ni Mary Taylor Lee àti Lawrence Johnson Lee. Bàbá rẹ̀, ẹni tó jẹ́ akọ̀wé ilé-iṣẹ́ reluwé ni ó tún fẹ́ ìyàwó mìíràn lẹ́yìn ikú tà kọ́kọ́, nígbà tí Browne jẹ́ ọmọ ọdún méjì. Òun àti ìyàwó rẹ̀ kejì, Lottie, olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́, ó gba ọmọ rẹ̀ ní ìyànjú láti kọjú mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ tó peregedé. Browne lọ sí ilé - ẹ̀kọ́ gírámà LeMoyne High School, ilé-ẹ̀kọ́ aládàáni tí a bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ogun àgbáyé, ilé-ẹ̀kọ́ Mẹ́tọ́díìsì. Nígbà ẹ̀kọ́ rẹ̀ yìí, ó gba àmì-ẹ̀yẹ "Memphis City Women's Tennis Singles Championship" NÍ ọdún 1929, lẹ́yìn ọdún méjì ni ó jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ LeMoyne High School.

Ó lọ sí Howard University, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣirò. Ó kẹ́kọ̀ọó gboyè ní ọdún 1935.[1] Lẹ́yìn tó gba ìwé-ẹ̀rí yìí, ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ fún ìgbà díẹ̀, ní àwọn ilé-ìwé bí i Gilbert Academy, ní New Orleans.[1]

  • Patricia Clark Kenschaft, "Black Men and Women in Mathematical Research," Journal of Black Studies, vol. 18, no. 2 (December 1987), pp. 170–190.
  • Scott W. Williams, "Black Women in the Mathematical Sciences," (SUNY Buffalo Math Dept.)
  • E. Fogg, C. Davis, and J. Sutton, "Profile of Marjorie Lee Browne." Retrieved from the World Wide Web, Agnes Scott College's "Biographies of Women Mathematicians" Web Site on 28 July 2004.
  • "MiSciNet's Ancestors of Science, Marjorie Lee Browne," Science, September 10, 2004.
  • Charlene Morrow and Teri Perl (eds), Notable Women in Mathematics, a Biographical Dictionary, Greenwood Press, 1998. pp. 17–21.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe