Markaz Agége
Markaz Agége jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ ẹ̀sin Mùsùlùmí àti Lárúbáwá tí ó fìdí kalẹ̀ sí Ìlú Agége ní ìpínlẹ̀ Èkó. Wọ́n kọ́kọ́ dá Ilé-ẹ̀kọ́ yí silẹ̀ ní ọdún 1952, ní ìlú Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn, ṣáájú kí wọ́n tó gbe wá sí ìlú Agége lábẹ́ àṣẹ Olùdásílẹ̀ rẹ̀ olóògbé Sheik Adam Abdulahi Al-Ilory ní ọdún 1954. Ilé-ẹ̀kọ́ yí kì í ṣàtìlẹyìn, tàbí ṣe ìgbélárugẹ fún ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí olóṣèlú kan kan bí ó ti wulẹ̀ kí ó mọ.[1]
Èròngbà Ilé-ẹ̀kọ́ náà
àtúnṣeÈrò ọkàn Olùdásílẹ̀ Ilé-ẹ̀kọ́ yí ni láti mú ìdàgbàsókè, ìṣe àmúyẹ Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó sòódó sínú ẹ̀sìn Islam, títan ìmọ́lẹ̀ sí ẹ̀sìn Mùsùlùmí káàkiri orílẹ̀-èdè àgbáyé, kíkọ́ àti kíkópa awọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn àti èdè Lárúbáwá nínú ìdíje, ìpéjọpọ̀(confrences), àti ìṣèwádí ìmọ̀ ní àwùjọ àgbáyé pátá. Ẹ̀wẹ̀, wọ́n tún lérò láti kọ́ àwọn ènìyàn àwùjọ ní ìmọ nípa ẹ̀sìn Mùsùlùmí, kí wọ́n si ṣí wọn lójú nípa ohun tí ó ta kókó tàbí rújú nínú ẹ̀sìn náà fún àwọn ènìyàn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí kárí, pàá pàá jùlọ láti lè kọ́ni nípa ètò Ìṣèlú, ọrọ̀-aje, ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ìgbé ayé lọ́kọ-láyà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní ìlànà ẹ̀sìn Islam, nípa ṣiṣẹ́ ìṣítí ìta gbangba àtìgbà dégbà. [2]
Ètò ẹ̀kọ́ wọn
àtúnṣeIlé-ẹ̀kọ́ yìí ń ṣàmúlò ìlànà ẹ̀kọ́ ti àwọn Gẹ́ẹ̀sì nínú ìkọ́ni àti ìkẹ́kọ̀ọ́. Oríṣiríṣi iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n ní tí wọ́n fi ń kọmọ pẹ̀lú àwọn Olùkọ.[3]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "ABOUT MORKAZ". INSTITUTE OF ARABIC AND ISLAMIC TRAINING CENTER (MORKAZ). Retrieved 2019-12-14.
- ↑ "WELCOME TO MARKAZ RADIO". WELCOME TO MARKAZ RADIO. 2018-11-05. Archived from the original on 2019-12-23. Retrieved 2019-12-14.
- ↑ "Your favorite newspapers and magazines.". PressReader.com. 2018-03-23. Retrieved 2019-12-14.