Masīhuzzamān Khān (1840 – 17 December 1910) fìgbà kan jẹ́ onímọ̀ Mùsùlùmí ti orílẹ̀-èdè India, tó jẹ́ gíwá kejì fún ilé-ìwé Darul Uloom Nadwatul Ulama[1]. Òun ni olùkọ́ fún Mir Laiq Ali Khan àti Mahboob Ali Khan.

Masīhuzzamān Khān
2nd Chancellor of Darul Uloom Nadwatul Ulama
In office
20 July 1903 – 21 April 1905
AsíwájúMuhammad Ali Mungeri
Arọ́pòKhalīlur Raḥmān S
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí1840
Shahjahanpur, Mughal India
Aláìsí17 December 1910(1910-12-17) (ọmọ ọdún 69–70)
Shahjahanpur, British India

Ìtàn ayè Masihuzzaman Khan

àtúnṣe

A bí Masīhuzzamān Khān ní ọdún 1840 (1256 ọdun Hijri AH) ní ìlú Shahjahanpur.[2] Ó gboyè ẹ̀kọ́ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Aḥmad Ali Shahabādi, ó sì lọ sí Hyderabad láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Muḥammad Zamān Khān.[2]

Lẹ́yìn tí ó parí ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀, Khān di olùkọ́ fún Mir Laiq Ali Khan àti Mīr Sa'ādat Ali Khān, tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Mir Turab Ali Khan. Ní Muharram 1293 AH, wọ́n yàn án gẹ́gé bí i olùkọ́ fún Mahboob Ali Khan, tó jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kẹfà Nizam of Hyderabad.[3] Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí i olùdarí gbogbo ọ̀rọ̀ tó ní ṣe pẹ̀lú ètò ẹ̀kọ́ ní Nizam.[3] Lẹ́yìn ikú Mir Turab Ali Khan ní1300 AH, wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ àjọ mìíràn, wọ́n sì yan Khurshīd Jah àti Narendra Prashad gẹ́gẹ́ bí i ọmọ ẹgbẹ́. Wọ́n bínú sí Masīhuzzamān Khān wọ́n sì mú kí ìdínkù wà nínú ipò tó dìmú, wọ́n sì fi ìwé àfẹ̀yìntì-ìfimùni ránṣẹ́ sí i ní ọjọ́ kẹrin, oṣù kìíní, Muharram 1301 AH.[4] Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin, ó padà lọ sí ìlú Shahjahanpur.[4] Khān darapọ̀ mọ́ ìpàdé gbogboogbò, ẹ̀ẹ̀kan-lọ́dún ti Nadwatul Ulama ní́ ọdún 1895 ní ìlú Lucknow, wọ́n sì fi jẹ olùdarí ẹgbẹ́ náà.[5] Wọ́n fi jẹ adarí Nadwatul Ulama fún ọdún mẹ́ta, lẹ́yìn tí Muhammad Ali Mungeri fẹ̀yìntì ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù keje, ọdún 1903.[6][7] Al-Nadwah, èyí tí ń ṣe ìwé àkọsílẹ̀ ti Nadwatul Ulama bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Shahjahanpur, nígbà tí ó jẹ́ adarí.[8] Ó fẹ̀yìntì iṣẹ́ rẹ̀ ní Nadwatul Ulama ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹrin, ọdún1905.[9] Ó kú ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹwàá, ọdún 1910.[10]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe

Bibliography

àtúnṣe
  • al-Hasani, Sayyid Muḥammad (May 2016) (in ur). Sīrat Hadhrat Mawlāna Muḥammad Ali Mungeri: Bāni Nadwatul Ulama (4 ed.). Lucknow: Majlis Sahāfat-o-Nashriyāt, Nadwatul Ulama. OCLC 1202732841. 
  • Khan, Shams Tabrez (2015). "Mawlāna Masīhuzzamān Khān ka daur-e-nizāmat" (in ur). Tārīkh Nadwatul Ulama. 2. Lucknow: Majlis Sahāfat-o-Nashriyāt. pp. 19-39. 
  1. Akhand, Surid (2017-08-17). ""Contributions of Mulims to Indian Subcontinent" by Ali Nadwi". Academia.edu. Retrieved 2023-09-15. 
  2. 2.0 2.1 Khan 2015, p. 19.
  3. 3.0 3.1 Khan 2015, p. 20.
  4. 4.0 4.1 Khan 2015, pp. 21-22.
  5. Khan 2015, p. 27.
  6. Khan 2015, p. 31.
  7. al-Hasani 2016, p. 238.
  8. Khan 2015, p. 35.
  9. Khan 2015, p. 39.
  10. Khan 2015, p. 25.