Mercy Akide

Agbaọ́ọ̀lù ọmọ orílé-éde Nàìjíríà

Mercy Akide Udoh tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1975[1] ní ìlú Port Harcourt, jẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin fún Nàìjíríà tẹ́lẹ̀. [2]

Mercy Akide
Personal information
OrúkọMercy Akide Udoh
Ọjọ́ ìbí26 Oṣù Kẹjọ 1975 (1975-08-26) (ọmọ ọdún 49)
Ibi ọjọ́ibíPort Harcourt, Nigeria
Ìga1.89 m (6 ft 2 in)
Playing positionMidfielder
National team
Àdàkọ:Fbw
† Appearances (Goals).

Ìgbà èwe rẹ̀

àtúnṣe

Mercy bẹ̀rẹ̀ sí ní gbá bọ́ọ̀lù nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún márùn-ún pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin, Seleipiri àti àbúrò rẹ̀ Ipali ní pápá erùpẹ̀ ti Bundu Waterside, lẹ́bàá ọgbà ẹwọ̀nPort Harcourt. Láti ọdún méjìlá ni wọ́n ti rí ẹ̀bùn eré ṣíṣá rẹ̀ ní ilé ìwé Rosary Secondary School, ní Port Harcourt. Ó jẹ́ akópa nínú ìdíje eré sísá ẹlẹ́mìnín gúngùn tí ìwọ̀n mítà ọ̀ọ́dúnrún (400), 800m àti 1500m pẹ̀lú àwọn tó jù ú lọ. Bẹ́ẹ̀ náà, ó pegedé nínú ìdíje ẹyin orí tábìlì, ṣùgbọ́n bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ló ti gbajúmọ̀ jùlọ.

Mercy gba orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ "Ske" lédè abínibí wọn, tí ó túmọ̀ sí ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́ nígbà tí ó máa ń gbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n jù ú lọ. Lára àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ni gbajúmò agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá Chidi Odiah, ẹni tí ó ń gba bọ́ọ̀lù jẹun fún ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá CSKA Moscow tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn àwọn ìgbìyànjú rẹ̀ ní Port Harcourt, Mercy dèrò Èkó láti tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ àti bọ́ọ̀lù gbígbá. Èkó ló ti dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin Àwọn Omidan Jẹ́gẹ́dẹ́ (Jegede Babes) pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọmọbabìnrin Bọ́lá Jẹ́gẹ́dẹ́

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá

àtúnṣe
  • 1988 sí 1990 ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá Garden City Queens (Nàìjíríà)
  • 1991–1994 ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá Jegede Babes (Nàìjíríà)
  • 1995–1998 ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá Ufuoma Babes (Nàìjíríà)
  • 1998–1999 ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá Pelican Stars (Nàìjíríà)
  • 1999–2000 ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá Milligan College/Hampton Roads Piranhas
  • 2001–2002 ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá San Diego Spirit
  • 2003–2006 ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá Hampton Roads Piranhas (W-League) [3]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Mercy Akide - Player Profile - Football". Eurosport. 1975-08-26. Retrieved 2020-11-02. 
  2. "Mercy Akide". SR/Olympic sports. Sports Reference LLC. Archived from the original on 18 April 2020. Retrieved 23 May 2012.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Nigeria - M. Akide - Profile with news, career statistics and history". Soccerway. 2020-11-02. Retrieved 2020-11-02.