Mercy Chinwo jẹ́ gbajúmọ̀ Òṣèrébìnrin, akọrin ajíyìnrere àti akọ̀wé orin ọmọ Nàìjíríà. Òun ló gbàmìn ẹ̀yẹ ìdíje Nigerian Idol abala kejì ti ọdún 2012.[1]

Mercy Chinwo
Nnenda
Fáìlì:Mercy chinwo.JPG
Background information
Orúkọ àbísọMercy Chinwo
Ọjọ́ìbí5 Oṣù Kẹ̀sán 1990 (1990-09-05) (ọmọ ọdún 34)
Port Harcourt, Ìpínlẹ̀ Rivers, Nigeria
Irú orinOrin ajíyìnrere ẹ̀sìn ọmọ lẹ́yìn Jésù
Occupation(s)Olórin, akọ̀wé orin, Òṣèrébìnrin
InstrumentsVocals
Years active2012 di àsìkò yìí
LabelsEeZee Conceptz

Ìgbésí ayé àti iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Mercy Nnenda Chinwo lọ́jọ́ karùn-ún oṣù kẹsàn-án ọdún 1990 ní Port Harcourt, Ìpínlẹ̀ Rivers. Ó jẹ́ ọmọ kẹrin nínú ẹbí rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin lọ́mọdẹ́, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ akọrin nílé ìjọsìn wọn.[2]

Mercy Chinwo gbé orin rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde lọ́dún 2015,ti o pè ní "Testimony", lẹ́yìn náà, ó gbé orin mìíràn tí ó pè ní "Igwe" jáde lọ́dún tó tẹ̀lé.[3] In 2017, Mercy Chinwo signed to Gospel Music Label EeZee Conceptz.[4]

Eré tíátà

àtúnṣe

Lẹ́yìn ọdún kan tí ó borí ìdíje Nigerian Idol, ó kópa àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí Òṣèrébìnrin nínú sinimá àgbéléwò tí Yvonne Nelson tí ó pè ní House of Gold, àwọn tí wọ́n jọ kópa ni: Yvonne Nelson, Majid Michel, Omawumi àti àwọn mìíràn.[5]

Àṣeyọrí

àtúnṣe
  • Lọ́dún 2018, Mercy Chinwo gba àmìn-ẹ̀yẹ olórin ajíyìnrere to dára jù, (Best Gospel Artiste at the CLIMAX Awards 2018).[6]
  • Lọ́dún 2019, gba àmìn-ẹ̀yẹ mẹta gẹ́gẹ́ bí olórin ajíyìnrere to dára jù, olórin obìnrin tó dára jù Lọ́dún náà àti orin rẹ̀, Excess Love gẹ́gẹ́ bí orin tó dára jù Lọ́dún náà níbi ìdíje àkọ́kọ́ Africa Gospel Awards Festival (AGAFEST 2019). [7][8]

Àpapọ̀ iṣẹ́ orin rẹ̀

àtúnṣe

Àwo orin

àtúnṣe
  • The Cross My Gaze (2018)
  • Satisfied (2020)

Orin àdágbéjáde

àtúnṣe
  • Testimony (2015)
  • Igwe (2016)
  • Excess Love (2018)
  • Omekanaya (2018)
  • No More Pain (2018)
  • Chinedum (2018)
  • Power Belongs to Jesus (2019)
  • Äkamdinelu (2019)
  • Oh Jesus! (2019)
  • Obinasom (2020)
  • Kosi (2020)
  • Tasted of your power (2020)
  • Na you dey reign(2020)

Sinimá àgbéléwò

àtúnṣe
List of television and film credits
Ọdún Àkọlé Ẹ̀dá-ìtàn
2013 House of Gold Lucia

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "How Mercy Chinwo won Nigerian Idols". Vanguard News. 9 April 2012. Retrieved 9 June 2019. 
  2. Onyike, Samuel. "Mercy Chinwo Biography, Songs, Age, Husband, Networth and Career". Thrill Ng. Retrieved 9 July 2020. 
  3. Media, D. O. D. (2019-11-12). "Gospel Artiste of the Week: MERCY CHINWO". Daughters Of Destiny TV (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-24. 
  4. "Mercy Chinwo gets signed to EeZee Conceptz Record Label | Gospotainment.com". gospotainment.com. Retrieved 9 June 2019. 
  5. "House of Gold Full Cast & Crew - nlist nlist | Nollywood, Nigerian Movies & Casting". nlist.ng. Retrieved 9 June 2019. 
  6. "Mercy Chinwo receives First Award". Lighteousness Entertainment News. 23 August 2018. Retrieved 9 June 2019. 
  7. "Africa Gospel Awards 2019: Full list of nominees". Music In Africa. 14 January 2019. Retrieved 9 June 2019. 
  8. "AGAFEST 2019 Awards – Photos, event review and full list of winners". WorshippersGh. 4 April 2019. Retrieved 9 June 2019.