Michelle Dede
Michelle Dede jẹ́ atọ́kùn ètò orí tẹlifíṣọ̀nù Nàìjíríà àti òṣèré. Ó ṣe àjọgbéjáde fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Flower Girl, ó sì tún kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù alátìgbà-dègbà kan, Desperate Housewives Africa àti fíìmù aṣaragágá tí ọduń 2017, What Lies Within.[1]
Michelle Dede | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Michelle Dede Germany |
Orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Ìgbà iṣẹ́ | 2006 – iwoyi |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeA bí Dede ní orílẹ̀-èdè Jẹ́mánì. Ó dàgbà ní ìdílé olókìkí. Bàba rẹ̀ ni Brownson Dede, aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan si orílẹ̀-èdè Ethiopia. Ó ní ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní Ìlú Brasil, ó sì parí ẹ̀kọ́ girama àti ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀ ní Australia àti Ethiopia. Lẹ́hìn náà, ó tẹ̀síwájú sí Ìlú Gẹ̀ẹ́sì láti kẹ́ẹ̀kọ́ Fashion Design áti Marketing ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga American College ní Ìlú Lọ́ndọ̀nù, UK. Ó tún ní oyè-ẹ̀kọ́ gíga nínu ìmọ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láti Ilé-ẹ̀kọ́ yìí kan náà.[2]
Iṣẹ́ ìṣe
àtúnṣeIṣẹ́ òṣèré rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lẹ́hìn tí ó wá fún ìsinmi kan ní Nàìjíríà. Nígbà náà ló di ẹni tó ní ànfààní láti máa ṣiṣẹ́ lágbo eré ìdárayá. Ní ọdún 2006, ó jẹ́ alájọṣe pẹ̀lú Olisa Adibua fún ti àkọ́kọ́ ìkéde ti Big Brother Nigeria, eré tẹlifíṣọ̀nù Nàìjíríà kan tí ó dá lóri eré Big Brother.[2] Lẹ́hìn náà, ó ṣe àjọgbéjáde fíìmù Flower Girl ti ọdún 2013 ṣááju kí ó tó tẹ̀síwájú láti kó ipa Tari Gambadia nínu fíìmù Desperate Housewives Africa. Ó tọ́ka sí Oprah Winfrey gẹ́gẹ́ bi àwòkọ́se rẹ̀ fún iṣẹ́ olùgbàlejò lóri ètò tẹlifíṣọ̀nù [3] Ní ọdún 2017, Dede kópa nínu fíìmù aṣaragágá kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ What Lies Within pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Paul Utomi, Kiki Omeili àti Tọ́pẹ́ Tedela.[4] Ní ọdún 2018, ó tún kópa nínu eré Moms at War.[5]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣe- Flower Girl (2013)
- Desperate Housewives Africa (2015)
- What Lies Within (2017)
- Moms at War (2018)
Ìgbé ayé rẹ̀
àtúnṣeDede jẹ́ ẹ̀jẹ̀ apanilẹ́ẹ̀rín Najite Dede. Ó sì n ṣe aṣojú ìpolówó ojà fún ilé-iṣẹ́ kan tó rí sí ǹkan amúsẹwà, Emmaus Beauty. [6][7]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "‘Don’t be afraid of failure, every rejection is a lesson’ • Leading Ladies Africa speaks to Michelle Dede". YNaija. 18 June 2016. http://ynaija.com/leading-ladies-africa-michelle-dede/. Retrieved 16 July 2016.
- ↑ 2.0 2.1 "Michelle Dede: 9 things you should know about multilingual TV host, actress". Pulse Nigeria. 23 March 2016. Archived from the original on 22 June 2017. https://web.archive.org/web/20170622023012/http://www.pulse.ng/movies/michelle-dede-9-things-you-should-know-about-multilingual-tv-host-actress-id4838132.html. Retrieved 16 July 2016.
- ↑ Francesca Uriri (25 June 2016). "Michelle Dede: Ambitious and compassionate". The Guardian. Archived from the original on 15 November 2018. https://web.archive.org/web/20181115112827/https://m.guardian.ng/guardian-woman/michelle-dede-ambitious-and-compassionate/. Retrieved 16 July 2016.
- ↑ https://dailytimes.ng/entertainment/tope-tedela-produces-first-movie/
- ↑ July 24, 2018 Here's when Omoni Oboli's new film will be released in cinemas Archived 2019-04-24 at the Wayback Machine., Pulse Nigeria
- ↑ "From Feeling Ugly to "I Accept Me" – Michelle Dede tells All". BellaNaija. 25 August 2015. https://www.bellanaija.com/2015/08/from-michelle-dede/. Retrieved 16 July 2016.
- ↑ Taire, Morenike (4 July 2010). ""Our father taught us to respect everyone"â€" Najite & Mitchelle Dede". Vanguard News. Retrieved 16 July 2016.