Ministry of Humanitarian Affairs, Disaster Management and Social Development

Àjọ Ministry of Humanitarian Affairs, Disaster Management and Social Development jẹ́ àjọ ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tí ó ń mójútó ìgbáyé-gbádùn, íbójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì àti ígbélárugẹ ní àwùjọ ọmọnìyàn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n dá àjọ náà sílẹ̀ ní ọjọ́ ọjọ́rú ọjọ́ kọnkànlélógún oṣù kẹjọ ọdún 2019, nígbà tí Ààrẹ Muhammadu Buhari kéde rẹ̀ sétí ìgbọ́ gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2]. Àjọ yí ni ó wà lábẹ́ ìṣàkóso Ààrẹ orilẹ̀-èdè Nàìjíríà, nígbà tí Ààrẹ yóò ma yan Mínísítà tí yóò jẹ́ lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí yóò ma darí àjọ náà. Ẹni tí ó jẹ́ adarí ẹ̀ka àjọ yí lásìkò tí a ń ko àpilẹ̀kọ yí ni Dókítà Sadiya Umar Farouq, ẹni tí wọ́n búra wọlé fún ní ọjọ́ kẹrìnlélógún osù kẹjọ ọdún 2019 gẹ́gẹ́ bi Mínísítà. [3][4] [5] nígbà tí Dókítà.(Mrs) Bashir Nura Alkali FCA, FCIT jẹ permanent secretary fún àjọ náà[6].

Ministry of Humanitarian Affairs, Disaster Management and Social Development
Coat of arms of Nigeria
Agency overview
Jurisdiction Government of Nigeria
Headquarters Federal Secretariat Abuja
Minister responsible Sadiya Umar Farouq
Website
fmhds.gov.ng

Awọn ajọ miran ti wọn wa labe FMHADS àtúnṣe

Lara awọn ajo miran ti wọn wa labe ile ise ijọba yi ni: National Commission for Refugees Migrants and Internally Displaced Persons Offices (NCFRMI), National Emergency Management Agency (NEMA), The National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons (NAPTIP), North East Development Commission (NEDC), Sustainable Development Goals (SDG) àti National Social Investments Programmes (N-SIP).

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Nigeria - Federal Ministry of Humanitarian Affairs, Disaster Management and Social Development, FMHDS". socialprotection.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-29. 
  2. Admin. "FMHDS". FMHDS website. 
  3. "Key into FG's empowerment programmes, Farouq begs youths". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-10-25. Retrieved 2022-03-29. 
  4. "Sadiya Farouq: Group lauds Buhari’s appointment of Minister". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-06-11. Retrieved 2022-03-29. 
  5. editor (2019-10-12). "Sadiya Umar-Farouq: The New Super Minister". THISDAYLIVE (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-29. 
  6. Abdullateef, Ismail (2020-09-30). "Nura Alkali Assumes Duty As New PS Humanitarian Affairs Ministry". Federal Ministry of Information and Culture (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-29.