Mo Abudu
Mosunmola Abudu, tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Mo Abudu, tí ó sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ògbóǹtarìgì agbóhùnsáfẹ́fẹ́, ẹlẹ́yinjú àánú, onímọ̀ràn ìṣàkóso àwọn òṣìṣẹ́ àti ẹni tí a mọ̀ mọ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́.[1][2] Forbes fi Mo Abdul hàn gẹ́gẹ́ bíi obìnrin ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó lọ́lá jù lọ ni.[3][4]
Mo Abudu | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 11 Oṣù Kẹ̀sán 1964 London, United Kingdom |
Ẹ̀kọ́ | Ridgeway School MidKent College West Kent College University of Westminster |
Iṣẹ́ | Media proprietor |
Website | ebonylifetv.com |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeA bí Abudu sí Hammersmith ní apá Ìwọ̀-oòrùn ní London.[1] UK ni ó ti ṣe èwe. Ó sì lọ sí Ridgeway School, MidKent College àti West Kent College. Ó gboyè Master's degree nínú Human Resource Management ní London.
Iṣẹ́ tí ó yàn láàyò
àtúnṣeIṣẹ́ rẹ̀ ní EbonyLife TV
àtúnṣeNí ọdún 2006,Abudu bẹ̀rẹ̀ EbonyLife TV,[5][6][7] ètò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ó tàn ká orílẹ̀-èdè tó ju ọkàndínláàádọ́ta lọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti ní UK àti Caribbean.[8] Ó jẹ́ ètò kan lábẹ́ Media and Entertainment City Africa (MEC Africa). EbonyLife TV wà ní Tinapa Resort ní Calabar, Ìpínlẹ̀ Cross Rivers, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ní ọdún 2018, Sony Pictures Television (SPT) kéde àṣẹ̀ṣẹ̀yanjú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ọlọ́dún mẹ́ta pẹ̀lú EbonyLife TV tí ó máa ní ṣe pẹ̀lú gbígbé fíìmù The Dahomey Warriors jáde.[9]
Iṣẹ́ rẹ̀ mìíràn; EbonyLife Films
àtúnṣeAbudu dá EbonyLife Films sílẹ̀. Àkọ́lé fíìmù tí ó kọ́kọ́ gbé jáde ni Fifty. Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ELFIKE ní ọdún 2016 láti gbé fíìmù The Wedding Party jáde.[10]
Moments with Mo
àtúnṣeAbudu jẹ́ olóòtú àti ẹni tó gbé ètò "Moments with Mo" kalẹ̀ tí ó jẹ́ ètò ojoojúmọ́ àkọ́kọ́ tí ó hàn káàkiri ilẹ̀ Adúláwọ̀ lórí afẹ́fẹ́.[11][12]
Ní ọdún kẹwàá ọdún 2009, a ti rí tó igba ìgbà tí ètò tí ó gbé sórí afẹ́fẹ́ hàn lórí afẹ́fẹ́. Àwọn ètò orí afẹ́fẹ́ náà máa ń dá lé lórí ìgbésí ayé ẹ̀dá, ètò-ìlera, àṣà, ètò-òṣèlú, eré-ìdárayá, ìṣe, orin àti ọ̀rọ̀ lórí ìgbéyàwó láàárín ẹ̀yà méjì. Wọ́n ti gbé àwọn olókìkí èèyàn lóríṣiríṣi, Ààrẹ orílẹ̀-èdè àti àwọn èèyàn tó lórúko sórí ètò náà.[1][13]
The Debaters
àtúnṣeAbudu jẹ́ olùdásílẹ̀ àti ẹni tó gbé ètò The Debaters jáde. Ó jẹ́ ètò tí Guaranty Trust Bank ń ṣàkóso nípa ètò ìṣúná. Ọjọ́ kẹta oṣù kẹwàá ọdún 2009 ni wọ́n dá a sílẹ̀. Ètò náà dá lé lórí "fífún ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni ohùn kan" nípa gbígbé ọ̀rọ̀ sísọ lárugẹ.[14]
Àwọn Àṣeyọrí rẹ̀
àtúnṣeForbes Africa fi Abudu hàn bíi obìnrin Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ láti ni Pan-Africa TV channel ní ọdún 2013.[15][16] Wọ́n kà á mọ́ ọkàn lára àwọn obìnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tó lọ́lá jù lọ lórí Global TV láti owó oníròyìn Hollywood ní ọdún 2013.[17] and received the Entrepreneur of the Year award by Women Werk in New York (2014).[18] Ní ọdún 2014, Babcock University dá a lọ́lá pẹ̀lú Honorary Doctor nínú Humane Letters.[19] Ní ọdún 2019, wọ́n dá a lọ́lá pẹ̀lú Médailles d'Honneur ti MIPTV 2019 ní Cannes, ìlú France. Èyí sì jẹ́ kó jẹ́ obìnrin ilẹ̀ Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ tó gba àmì ẹ̀yẹ náà.[20] Bákan náà, wọ́n kà á mọ́ ọkàn lára ọgọ́rùn-ún obìnrin tí ó lọ́lá jù lọ lórí 2020 Powerlist ní UK láti ilẹ̀ Adúláwọ̀.[21]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Smallman, Etan (16 November 2013). "Meet Africa's Oprah: Why Mosunmola 'Mo' Abudu wants to change the world's view of her continent". Independent. Retrieved 17 August 2016.
- ↑ Florence Amagiya (2 August 2014). "Mo Abudu, the pie that made her rich". The Vanguard. http://www.vanguardngr.com/2014/08/mo-abudu-pies-made-rich/. Retrieved 1 April 2015.
- ↑ Funsho Arogundade (9 January 2015). "Mo Abudu Is Forbes Africa's Most Successful Woman". Prime News. http://www.pmnewsnigeria.com/2015/01/09/mo-abudu-is-forbes-africas-most-successful-woman/. Retrieved 31 March 2015.
- ↑ "Africa's Most Successful Women: Mo Abudu". Forbes. 1 January 2015. Retrieved 28 March 2015.
- ↑ "MIPCOM: The 25 Most Powerful Women in Global TV". The Hollywood Reporter. 4 October 2013. http://www.hollywoodreporter.com/lists/mosunmola-abudu-642527. Retrieved 1 March 2014.
- ↑ "Meet the hosts of Moments". DStv. 26 June 2015. Retrieved 17 August 2016.
- ↑ "Nigerian woman launches tv network".
- ↑ Michelle Cohan and Nosmot Gbadamosi. "The Nigerian Media mogul with a global empire". CNN. Retrieved 2017-09-04.
- ↑ Giles, Chris. "Nollywood, Sony Pictures join forces for TV series on all-female African army". CNN. https://edition.cnn.com/2018/03/29/africa/nollywood-hollywood-female-african-tv-show/index.html.
- ↑ "'The Wedding Party' rakes in over N400m in ticket sales" (in en-US). Archived from the original on 2023-04-06. https://web.archive.org/web/20230406153548/https://guardian.ng/life/film/the-wedding-party-rakes-in-over-n400m-in-ticket-sales/.
- ↑ Faul, Michelle (2 July 2013). "'Africa's Oprah' Mo Abudu launches TV network in Nigeria". Thestar.com. Retrieved 17 August 2016.
- ↑ Enengedi Victor (10 June 2013). "ET Exclusive: Mo' Abudu launches N2bn TV channel". Nigerian Entertainment. Net newspapers. p. 1. Archived from the original on 19 April 2014. Retrieved 27 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Grand launch for Mo-ments with Mo". 31 October 2007. Retrieved 31 October 2007.
- ↑ "The Debaters... new on screen". 23 July 2009.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Mo Abudu Africa's queen of talk - Forbes Africa" (in en-US). Forbes Africa. 2013-10-01. https://www.forbesafrica.com/entreprenuers/2013/10/01/mo-abudu-africas-queen-talk/.
- ↑ "[1] Archived 23 August 2013 at Archive.is. The Guardian (Nigeria)
- ↑ "Mosunmola Abudu - MIPCOM: The 25 Most Powerful Women in Global TV" (in en). The Hollywood Reporter. http://www.hollywoodreporter.com/lists/mipcom-25-powerful-women-global-642526/item/mosunmola-abudu-25-powerful-women-642527.
- ↑ "International Women's Day: Mo Abudu wins Entrepreneur of the Year - The Nation Nigeria" (in en-US). The Nation Nigeria. 2014-03-11. http://thenationonlineng.net/international-womens-day-mo-abudu-wins-entrepreneur-of-the-year/.
- ↑ "Mo Abudu Receives Honorary Doctorate from Babcock University - BellaNaija". www.bellanaija.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2017-09-04.
- ↑ "Nigerian media mogul Mo Abudu receives 2019 Médailles d'Honneur at MIPTV - Screen Africa" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-13.
- ↑ Mills, Kelly-Ann (25 October 2019). "Raheem Sterling joins Meghan and Stormzy in top 100 most influential black Brits". mirror. Retrieved 20 April 2020.