Mohammed Mustapha Namadi
Mohammed Mustapha Namadi jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ́-èdè Nàìjíríà, wọ́n bí i ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹta, ọdún 1959 (March 25, 1959) ní Ìpínlẹ̀ Kano. Ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n (Professor) tí ó sì tún jẹ́ adarí àgbà ní agbo tí a ti ń kọ́ nípa ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ àwùjọ (Dean Faculty of Social Sciences), ní yunifásítì ìjọba àpapọ̀ ti Kashere ní Ìpínlẹ̀ Gombe Nàìjíríà.[1][2] Ó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ kọmísọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́[3] àti Kọmísọ́nà fún ohun ọ̀gbìn àti àwọn àlùmọ́ọ́nì inú ilẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Kano, orílẹ́-èdè Nàìjíríà. Nínú oṣù karùn-ún ọdún 2021, Ààrẹ Muhammadu Buhari yàn án sí àjọ olùdarí ti Ilé-iṣẹ́ àwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ́-èdè Nàìjíríà (Governing Body of the National Senior Citizens Centre).
Mohammed Mustapha Namadi | |
---|---|
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 25 Oṣù Kẹta 1959 Kano State, Nigeria |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressives Congress (APC) |
Alma mater | Bayero University Kano, Florida State University |
Profession | Medical sociologist |
íwọ́n jẹ́ ọmọ tiílẹ́ilẹ-è(he Governing Body of the National Senior Citizens Centre).
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Department of Sociology". Federal University of Kashere. Retrieved 30 September 2023.
- ↑ "Our Staff". Federal University of Kashere. Retrieved 30 September 2023.
- ↑ "Kano Delegation Arrive Wisconsin". New Nigeria. New Nigerian. 2008-10-08. Archived from the original on 2011-07-13. Retrieved 2023-09-30. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)