Mokalik jẹ́ fíìmù apanilẹ́rìn-ín ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jẹ́ elédè méjì tí a gbé jáde ní ọdún 2019. Kúnlé Afọláyan ni olùdarí àti ẹni tí ó gbé fíìmù yìí jáde. Fíìmù náà ṣe àfihàn Toni Afolayan tí ó ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe tí ó jẹ́ olú ẹ̀dá ìtàn lọ́kùnrin pẹ̀lú Fẹ́mi Adébáyọ̀. Fíìmù náà jáde ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2019, ó sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà àwọn ará ìlú, kò ṣàìní àríwísí àwọn èèyàn.[2][3] Àwọn Netflix ṣe ìtẹ́wọ́gbà fíìmù yìí ni osù Keje ọdún 2019, wọ́n sì ṣe àfihàn rẹ̀ ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹsàn-án, ọdún 2019.[4][5] Fíìmù náà ti wà lára àwọn fíìmù abẹ́ "Made in Africa" ní oṣù karùn-ún ọdún 2020 láti ọwọ́ Netflix tí wọ́n sì máa ṣe àgbéjáde rẹ̀.[6][7] A tún yan fíìmù náà gẹ́gẹ́ bíi fíìmù tó dára jù lọ ní 2019 Durban International Film Festival. A sì tún ṣe àfihàn fíìmù yìí ní film festivals lóríṣiríṣi.

Mokalik
AdaríKúnlé Afọláyan
Olùgbékalẹ̀Kúnlé Afọláyan
Àwọn òṣèréToni Afolayan
Fẹ́mi Adébáyọ̀
Tobi Bakare
OrinKentoxygen Egunjobi
Ilé-iṣẹ́ fíìmùGolden Effects Pictures/Africa Magic
OlùpínFilmOne
Déètì àgbéjáde
  • 31 Oṣù Kàrún 2019 (2019-05-31)
Àkókò99 minutes
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèEnglish
Yoruba
Owó àrígbàwọlé₦46.9million[1]

Àwọn Akópa

àtúnṣe

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "TTop 20 films of 2019". Cinema Exhibitors Association of Nigeria. 
  2. "Movie Review: Kunle Afolayan’s ‘Mokalik’ thrives on memory, not viewer satisfaction" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-11-24. Retrieved 2020-05-06. 
  3. "Box Office: Nigerian moviegoers spent N636 million in July but less than N20 million went to Nollywood". www.pulse.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-08-06. Retrieved 2020-05-06. 
  4. editor (2019-08-23). "Kunle Afolayan's Mokalik, October 1, Now on Netflix". THISDAYLIVE (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-06. 
  5. "Netflix acquires Kunle Afolayan’s ‘Mokalik’, others". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-06. 
  6. "Netflix highlights 100+ African titles in new 'Made in Africa' collection". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-05-05. Retrieved 2020-05-06. 
  7. Lotz, Brendyn (2020-05-04). "Netflix celebrates Africa Day with Made in Africa collection". htxt.africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-06.