Muhammed Bello

Olóṣèlú


Muhammed Bello jẹ sultani tí ṣòkòtò èlékejì[1] Ha-Muhammadu Bello.ogg pronunciation (Lárúbáwá: محمد بلو‎) tí ó lọ ìjọba láàrin 1817 títí dá 1837. Ó jẹ́ olùkọ́we ìtàn, ewì àti ẹ̀kọ́ ìwé ẹsin isilaamu. Ó jẹ́ ọmọ àti oluranlowo àkókò fún Usman dán fodio. oludasile ilẹ̀ Kálìfù ṣòkòtò àti sultani àkókò[2]. Ni àkókò ìjọba rẹ, ó jẹ̀ki ìtànkálẹ̀ Islam túbọ̀ gbòòrò ni gbógbo àgbègbe, ẹ̀kọ́ fún àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin lọ ní déédéé, àti ìdásílè àwọn ile-ẹjọ́ àwọn mùsùlùmí. O kú ní oṣù kẹwàá ọjọ́ 25, ọdún 1837, ẹni tí ó rọ́pò rẹ ni Abu Bakr Atiku lẹ́yìn náà ọmọ rẹ, Aliyu Babba [3].

Muhammed Bello
Sarkin Musulmi (Commander of the Faithful)
Orí-ìtẹ́1817-1837
Ọjọ́ìbí3 November 1781
Aláìsí25 October 1837
Ibi tó kú síwurno
AṣájúUsman dán fodio
Arọ́pọ̀Abu Bakr Atiku, brother:
Aliyu Babba, son.
ẸbíajọbaSokoto Caliphate
BàbáUsman dan Fodio

Igbesi aye ibẹrẹ àtúnṣe

O wá láti ìdílé Torodbe tí wọn jẹ Lárúbáwá apá kan àti apá kan Fulani gẹgẹbi Abdullahi dan Fodio, Àbúrò Usman dan Fodio tí sọ. wọn sọ pé àwọn tán mo Lárúbáwá ni pàse Uqba, Ṣugbọn Bello fí kún pé kò dá òhun lójú bóyá Uqba ọmọ Nafi ní, Uqba ọmọ Yasir ni tàbí Uqba ọmọ Amir[4].Uqba tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ fẹ́ obìnrin fulani kàn tí a ń pè ní Bajjumangbu nípasẹ̀ rẹ ni Torodbe tí Usman dan Fodio tí sọkalẹ[5]. Kálìfù Mohammed Bello kọ̀ sì inú ìwé rẹ Infaq Al-Mansur wípé ìran rẹ wà láti ipase ojisẹ Mohammed látàra ìyà màmá rẹ tí à n pè ní Hawwa (Ìyá Usman Dán Fodio), Alhaji Muhammadu junaidu, waziri ṣòkòtò, ọmọwe ìtàn fulani fí ìdí ọrọ shaykh Abdullahi ọmọ fodio múlẹ̀, eleyii tó sọ wípé ìdílé Dan Fodio jẹ́ apákan Lárúbáwá àti apákan Fulani, nígbà tí Ahmadu Bello nínú ìwé ìtàn ayé rẹ tí ó kọ lẹ́yìn òmìnira fi ìdí ọ̀rọ̀ tí Kálìfù Muhammadu Bello sọ wípé wọn wá láti ilé Lárúbáwá látàra ìyá Usman dan Fodio, ìwé ìtàn fihàn pé ìdílé Shehu dan Fodio jẹ apákan Lárúbáwá àti apákan fulani tí àṣà wọn Fárápẹ haúsá àti pé à lè ṣe àpèjúwe wọn bí Lárúbáwá haúsá-fulani. Ṣáájú ibẹrẹ jihad 1804, ẹ̀ka fulani kò ṣe pàtàkì fún Toronkawa (Torodbe),àwọn ìwé wọn ṣe àfihàn aìdánilójú tí wọn ní sì ìtumò ibasepo tó wà láàrin Torodbe àti Fulani. Wó yà èdè tí Fulbe àti ọpọlọpọ àṣà nígba ti wọn dúró lórí ìdánimọ òtọ́tọ́.[6]. Àwọn ìdílé Toronkawa ní àkọ́kọ́ gbà àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti gbógbó àwùjọ sudani, pápá àwọn ènìyàn tálákà. Àwọn àlùfáà Toronkawa jẹ́ àkójọ àwọn ènìyàn tí ìpilẹ̀ṣẹ̀ wón jẹ́ fula, Wolof, mande, hausa àti Berber. Àmọ́n wọn sọ èdè fula, wọn ṣègbéyàwó sí àwọn ìdílé Fulbe, wọ́n sì di ẹgbẹ́ àwọn ọ̀mọ̀wé Fulbe.[7]

Muhammed Bello jẹ ọmọ bíbí ìyàwó kẹrin tí Usman dan Fodio,ẹni tí à mó sì Hauwa tàbí Inna Garka, ní ọdún 1781[8] gẹgẹbi àwọn ọmọ ìyà rẹ, o kópa nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí bàbá rẹ̀ dárí ni degel títí tí ìdílé àti díẹ́ nínu àwọn ọmọ-ẹhin fi wá ní ìgbèkùn ní ọdún 1804. Ní ọdún 1809, Bello ṣe okùnfà idasile ṣòkòtò tí ó di olú ìlú pàtàkì fún bàbá rè láti ṣẹ́gun ilé hausa ni ogún Fulani (1804-1810)[8].

Púpọ̀ nínú àwọn ọmọ àbúrò àti ẹ̀gbọ́n rẹ yà àkókò pàtàkì sì akitiyan ẹ̀kọ́ tí ó sì sọ wón di gbajúmọ́. Lára wọn ní àbúrò rẹ Nana Asma'u, akéwì àti olùkọ́,[9] àti Abu Bakr Atiku, tí ó rọ́pò rẹ bí sultan[10].

Àdàkọ:S-end

Ita ìjápọ àtúnṣe

Àwọn Itọ́kasí àtúnṣe

  1. Wilks,Ivor. Wangara, Akan, and Portuguese in the Fifteenth and Sixteenth Centuries (1997). Bakewell, Peter. ed. Mines of Silver and Gold in the Americas. Aldershot: Variorum, Ashgate Publishing Limited. pp. 17. 
  2. "Log In - Oxford Islamic Studies Online". www.oxfordislamicstudies.com. Retrieved 2020-05-26. 
  3. "History Atlas". www.historyatlas.com. Archived from the original on 2023-10-03. Retrieved 2020-05-26. 
  4. Gwandu, Abubaker Aliu (1977) Abdullahi b. fodio as a Muslim jurist(Doctoral thesis). Durham University
  5. Abubakar, Aliyu (2005). The Torankawa Danfodio Family. Kano,Nigeria: Fero Publishers. 
  6. Ajayi, Jacob F. Ade (1989). Africa in the Nineteenth Century Until the 1880s. University of California Press. ISBN 978-0-520-03917-9. https://books.google.com/books?id=sMpMuJalFKoC&pg=PA541. Retrieved 2013-02-13. 
  7. Ajayi, Jacob F. Ade (1989). Africa in the Nineteenth Century Until the 1880s. University of California Press. ISBN 978-0-520-03917-9. https://books.google.com/books?id=sMpMuJalFKoC&pg=PA541. Retrieved 2013-02-13. 
  8. 8.0 8.1 Boyd, Jean (1986). Mahdi Adamu. ed. Pastoralists of the West African Savanna. Manchester, UK: International African Institute. 
  9. John H. Hanson (2012). Elias Kifon. ed. The Wiley-Blackwell Companion to African Religion. West Sussex: Blackwell. pp. 365–376. 
  10. Mikaberidze, Alexander (2011). Conflict and Conquest in the Islamic World. Santa Barbara, CA: ABC-CLIO. 

Àdàkọ:Authority control

Preceded by
Usman dan Fodio
2nd Sokoto Caliph
1815–1837
Succeeded by
Abu Bakr Atiku