Munkoyo
Munkoyo [1][2][3] tàbí ibwatu[4] jẹ́ ohun mímu tí ó gbajúgbajà ní ìgbèríko Zambia. Ó jẹ́ ohun mímu tí a máa ń fún tí a ṣe láti ara àsáró àgbàdo àti Rhynchosia venulosa gígún (ní ìbílẹ̀ tí a mọ̀ sí munkoyo) gbòǹgbò.[5] Àpòpọ̀ yìí máa wá di ṣíṣè.[6] Ó lè wá di mímu ní ẹsẹ̀kesẹ̀ lẹ́yìn ṣíṣe tàbí fífi sílẹ̀ láti tọró fún ọjọ́ díẹ̀. Wọ́n sábàá máa ń pè é ní "ọtí dídùn" ní Zambians. Ó tún di rírí ní àwọn orílẹ̀-èdè ààrin gbùngbùn ilẹ̀ Áfíríkà bí Congo níbi tí wọ́n ti ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ohun mímu níbi ayẹyẹ ìbílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí ohun mímu lásán.
Munkoyo ni ó di mímọ̀ pé ó ní ipa ìlera tí ó dára, àti ṣíṣe àlékún ìlera àti vitamin B.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ìlera
àtúnṣeNí gbígba gbòǹgbò munkoyo, àwọn olùwágbòǹgbò kan tún máa ń wú àwọn gbòǹgbò tó ní májèlé. Èyí ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn di èrò ilé-ìwòsàn.[7] Irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí kan ṣẹlẹ̀ ní Solwezi District, tí ènìyàn mẹ́tàdínlógún di èrò ilé-ìwòsàn tí ènìyàn méjì sì di èrò ọ̀run,[8] àti ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tí ó ṣẹlẹ̀ nítòsí Kitwe èyí tí ó sọ ènìyàn méjìdínlọ́gọ́rùn-ún di èrò ilé-ìwòsàn.[9][6]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Keith Steinkraus (4 May 2018). Handbook of Indigenous Fermented Foods, Revised and Expanded. CRC Press. pp. 528–530. ISBN 978-1-351-44251-0. https://books.google.com/books?id=AUxaDwAAQBAJ&pg=PT528.
- ↑ Everlon Rigobelo (3 October 2012). Probiotics. BoD – Books on Demand. pp. 176–. ISBN 978-953-51-0776-7. https://books.google.com/books?id=ZG2fDwAAQBAJ&pg=PA176.
- ↑ Françoise Malaisse (2010). How to live and survive in Zambezian open forest (Miombo ecoregion). Presses Agronomiques de Gembloux. pp. 289–295. ISBN 978-2-87016-106-7. https://books.google.com/books?id=FcXW4MJUGYkC&pg=PA289.
- ↑ Phiri, Sydney; Schoustra, Sijmen E.; Heuvel, Joost van den; Smid, Eddy J.; Shindano, John; Linnemann, Anita (2019-10-22). "Fermented cereal-based Munkoyo beverage: Processing practices, microbial diversity and aroma compounds" (in en). PLOS ONE 14 (10): e0223501. Bibcode 2019PLoSO..1423501P. doi:10.1371/journal.pone.0223501. ISSN 1932-6203. PMC 6805097. PMID 31639127. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=6805097.
- ↑ Lukwesa Burak (24 December 2018). "World News Today". World News Today (in English). BBC World News. Retrieved 28 May 2024.
- ↑ 6.0 6.1 Jongeling, Coretta (13 November 2019). "Beating malnourishment with traditional drinks". Resource online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 15 July 2024.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedBBCWN2
- ↑ "Zambia: Munkoyo Kills 2, 17 Hospitalised". Retrieved 31 May 2024.
- ↑ Kabaila, Moses. "Times of Zambia | 98 mourners poisoned after drinking munkoyo". Times of Zambia. Retrieved 31 May 2024.