Murtala Ramat Mohammed tí a bí ní November 8, 1938February 13, 1976) je olori ijoba Nigeria gege bi ologun lati odun 1975 si 1976. Igba ti awon ologun egbe re fe gba ijoba ni won pa. Ogagun Obasanjo ti o je igbakeji re ni o bo si ori oye gege olori ijoba lati 1976 si 1979.

Murtala Ramat Mohammed
4th Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà
In office
July 29, 1975 – February 13, 1976
AsíwájúYakubu Gowon
Arọ́pòOlusẹgun Ọbasanjọ
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1938-11-08)Oṣù Kọkànlá 8, 1938
Nigeria
AláìsíFebruary 13, 1976(1976-02-13) (ọmọ ọdún 37)
Lagos, Nigeria
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Ẹgbẹ́ olóṣèlú(None)
Abọ ìpọnmi nígbà ayé Ọ̀gágun Muritala Muhammed

Igbesi aye

àtúnṣe

A bí ògágun Murtala Ramat Muhammed ni ojó kéjo, osù kejì odún 1938 (8/2/1938). Olórí ológun ní ó jé. Ó di alákòso ológun orílè èdè Nàígíríà ní 1975 títí di odún Feb 13, 1976 Murtala Mohammed jé elésìn Mùsùlùmí, Hausa ni pèlú láti (òkè oya apá gúúsù. Ó kékò ológun ní British Academy, Sandhurst.

Murtala kò faramó ìjoba ológun Johnson Aguiyi Ironsi tí ó fipá gbà joba ni osù kìíní odún 1966 nínú èyí tí wón pa òpòlopò olórí Nàíjíríà tó jé omo apá gúúsù lónà tó burú jáì! Fún ìdí èyí ó kópà nínú ìfipá - gbà ijòba tó wáyé ni July 21, 1966. Wón fipá gba papakò òfurufú ìkejà; èyí tí wón ti yí orúko rè sí Murtala Mohammed International Airport làti fi yé. Ó kókó fé fi ìfipá gbà ijoba yìí gégé bíi igbésè fún àwon ara gúúsù láti ya kúrò lára Nàíjíríà sùgbón ó da àbá yìí nù nígbèyìn.

 
Inú ọkọ̀ ti wọ́ pa Murtala Mohammed sí


Ìfipá gbajoba yìí ló mú ògagún (lieutenant-colonel) Yakubu Gowon jé alákòso orílè èdè Nàígíríà. Ní July/29/1975 àwon ologun tó jé òdò fi ògágun Murtala je alákoso orílè èdè yìí láti jé kí Nàígíríà padà sí ìjoba alágbádá Democracy. Omo odún méjìdínlógójì ni Murtala Ramat Muhammed nígbà tí àwon ológun fi je alákoso rópò Gowon. Murtala kó pa pàtàkì nínú ogun abélé. Ó jé òkan nínú adarí omo ogun Nàígíríà nígbà tí ogun náà dójú iná tán po. Òun ló fà á tí ikojá òdò oya (River Niger) àwon omo ogun Biyafira Biafra se já sí pàbó. Murtala ò lówó sí bí ìfipá-gbà-joba tó mu gorí oyè.

Lógán tí Murtala gbàjòba, ara ohun tó kókó se ni; ó pa ètò ìkani [[Census]] ti odún 1973 re, eléyìí tó jé pé ó fì jù sí òdò àwon gúúsù nípa ti ànfàní. Ó padà sí ti odún 1963 fún lílò nínú isé.

Murtala Mohammed yo òpòlopò àwon ògá ise ijoba tí ó ti wà níbè láti ìgbà ìjoba Gowon. Ó tún mú kí àwon ará ìlú ni ìgbèkèlé nínú ìjòba alápapò. Ó lé ni egbàárùn (10,000) òsísé ìjoba tí Murtala yo lénu isé nítorí àìsòótó lénu isé, àbètélè, jegúdú-jerá, síse ohun ìní ìjoba básubàsu, àìlèsisé-lónà-tó ye tàbí ojó orí láìfún won ní nkankan. Fífòmó Murtala kan gbogbo isé ìjoba pátápátá, bí àwon olópàá, amòfin, ìgbìmò tó n mójútó ètò ìléra, ológun, àti Unifásitì. Àwon olórí isé ìjòba kan ni wón tún fi èsùn jegúdú jerá kàn, tí wón sì báwon dé ilé ejó. Murtala tún fó egbàárùn owo-ogun sí wéwé. Ó fún àwon alágbádá ni méjìlá nínú ipò méèdógbòn ti amojútó ìgbìmò isé ìjoba. Ìjoba àpapò gba àkóso ilé isé ìròyìn méjì tí ó tóbi jù lo lórílè èdé yìí. Ó jé kí gbígbé ìròyìn jade wa làbé ìjoba àpapò nìkan. Murtala mú gbogbo Yunifasiti tó wà lábé ìjoba ìpínlè sí abé àkoso ìjoba àpapò.

Mélòó lafé kà nínú eyín adépèlé ni òrò àwon ohun ribi-ribi tí Murtala gbése nígbà ti re. Ara won tún ni dídá ìpínlè méje mó méjìlá tó wà tèlé láti di mókàndínlógún. Murtala se àtúnyèwò ètò ìdàgbàsókè elekéta orílè èdè. Ó rí ìgbówólórí (inflation) gégé bí ìdàmú nlá tó n se jàmbá fún òrò ajé e wa. Fún ìdí èyí, ó pinnu láti dín owó tó wà lode pàápàá èyí tí wón n ná le isé ìjoba lórí ku. Ó tún gba àwon onísé àdáni níyànjú láti máa sesé tí àwon òsìsé gbogbo-o-gbo ti je gàba lé lórí. Murtala tún se àtúnyèwò òye ise ìtójú ìlú tó ní se pèlú ìlú mìíràn tí àwon egbé ìlú tí ó n sèdá epo ròbì lágbàáyé (OPEC). Ó jé kí Nàíjíríà je ohun kìíní tí ó kà sí nípa ti ànfàní àti iye tí wón dálé epo ròbì.

Láìrò télè, ògágun Murtala dèrò òrun ni ojó ketàlá osù kejì, odún 1976. Wón da lónà nínú mótò rè, nígbà tí òun ti mósálásí bò nínú ìfipá-gbà-joba tí ó jé ìjákulè nígbèyìn. Owó te àwon òlòtè tó pa á, sùgbón kì lé tó pa òsìkà ohun rere á tí bà jé. Murtala Ramat Mohammed ti fayé sílè. Èpa kò bóró mó. Ká tó rérin ó digbó, ká tó rèfon ó dò dàn, ká tó réye bí òkín Murtala Ramat Mohammed ìyén di gbére.