Naira Marley
Naira Marley tí orúkọ àbísọ rẹ̀ gangan ń jẹ́ Azeez Fáṣọlá, tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù karùn-ún ọdún 1994 (9th May 1994) jẹ́ gbajúmọ̀ olórin àti oǹpilẹ̀kọ̀wé-orin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [2]Òun ní Ààrẹ ẹgbẹ́ olólùfẹ́ àgàbàgebè rẹ̀ tí wọ́n ń pè ní "Marlians".[3][4] [5]
Naira Marley | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Azeez Fashola 9 Oṣù Kàrún 1994 Agege, Lagos State, Nigeria |
Iṣẹ́ |
|
Musical career | |
Irú orin | |
Instruments | Vocals |
Years active | 2014–present |
Labels | Marlian Records[1] |
Associated acts | |
Ìgbà èwe àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ré
àtúnṣeWọ́n bí Naira Marley ní ìlú Agége ní Ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Nígbà tí ó wà lọ́mọdún mọ́kànlá ní o dèrò ìlú òyìnbó, ní Peckam, lápá gúúsù London, lórílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì.[6] Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Porlock Hall kí ó tó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Walworth School, níbi tí ó ti gbàwé ẹ̀rí General Certificate of Secondary Education. Naira Marley kàwé gbàwé ẹ̀rí tí ó ga jùlọ nínú ìmọ̀ okoòwò ní ilé-ẹ̀kọ́ Harris Academy ní ìlú Peckam Peckham. Ó tún kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ òfin okoòwò ní ilé-ẹ̀kọ́ giga Crossways College tí wọ́n ń pè ní Christ the King Sixth Form College .[7]
Àtójọ àwọn orin rẹ̀
àtúnṣeOrin alájọkò
àtúnṣe- Gotta Dance (2015)
- Lord of Lamba (2019)
Orin aládàákọ
àtúnṣe- "Issa Goal" (2017)
- "Japa" (2018)
- "Am I A Yahoo Boy" (2019)
- "Opotoyi (Marlians)" (2019)
- "Soapy" (2019)
- "Puta" (2019)
- "Mafo" (2019)
- "Tesumole" (2019)
- "Tingasa" (2019)
Àtòjọ àwọn àmìn-ẹ̀yẹ tí ó gbà àti àwọn tí wọ́n yàn án fún
àtúnṣeỌdún | Àmìn-ẹ̀yẹ | Abala | Olùgbàmìn ẹ̀yẹ | Àbájáde | Ìtọ́kasí |
---|---|---|---|---|---|
2020 | Soundcity MVP Awards | Ààyò àwọn olùwòran | "Soapy" | Gbàá | [8] |
Orin tó dára jù lọ́dún | Wọ́n pèé | ||||
Orin tàkasúfèé tó dára jù | Naira Marley | Wọ́n pèé | |||
2019 | City People Music Awards | Olórin-kùnrin tó dára jù lọ́dún náà | Wọ́n pèé | [9] | |
Orin àdúgbò tó dára jù | "Soapy" | Wọ́n pèé |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Augoye, Jayne (2 January 2020). "Naira Marley floats record label, signs four artistes". Premium Times. https://www.premiumtimesng.com/entertainment/music/370941-naira-marley-floats-record-label-signs-four-artistes.html. Retrieved 12 January 2020.
- ↑ "Naira Marley: Tins you suppose know about Afeez Fashola aka Naira Marley". BBC. 21 May 2019. https://www.bbc.com/pidgin/tori-48347911. Retrieved 12 January 2020.
- ↑ Okanlawon, Taiwo (29 December 2019). "Naira Marley premieres new dance moves in “Tesumole”". P.M. News. https://www.pmnewsnigeria.com/2019/12/29/naira-marley-premieres-new-dance-moves-in-tesumole. Retrieved 12 January 2020.
- ↑ Abraham, Anthony Ada (9 November 2019). "Marlian Movement And Their Crazy Lifestyle". Leadership Newspaper. https://leadership.ng/2019/11/09/marlian-movement-and-their-crazy-lifestyle. Retrieved 12 January 2020.
- ↑ "Naira Marley: VIDEO". 21 May 2020. Archived from the original on 22 July 2021. https://web.archive.org/web/20210722093414/https://mp4hdd.com/. Retrieved 12 January 2020.
- ↑ "Naira Marley, Career, Background, Biography". NotJustOk. Archived from the original on 16 October 2019. https://web.archive.org/web/20191016131036/https://notjustok.com/artists/naira-marley/. Retrieved 12 January 2020.
- ↑ "Naira Marley Net Worth, Biography, Cars, and Lifestyle". PunchyInfo. 12 December 2019. https://punchyinfo.com/naira-marley-net-worth-biography-cars-lifestyle. Retrieved 12 January 2020.
- ↑ Alake, Motolani (12 January 2020). "Davido, Naira Marley, Burna Boy, Rema, Fireboy and the winners at the Soundcity MVP Awards 2020". Pulse NG. https://www.pulse.ng/entertainment/music/davido-naira-marley-burna-boy-rema-fireboy-and-the-winners-at-the-soundcity-mvp/6kfthnn. Retrieved 12 January 2020.
- ↑ "#CityPeopleMusicAwards: Nominees List Out". City People Magazine. 25 October 2019. Retrieved 12 January 2020.