National Council of Nigeria and the Cameroons

Ẹgbẹ́ òṣèlú National Council of Nigeria and the Cameroons (NCNC) tí wọ́n padà yí orúkọ rẹ̀ padà sí National Convention of Nigerian Citizens, ni ó jẹ́ ìkan nínú àwọn ẹgbẹ́ ìṣèlú tí wọ́n jìjà-n-gbara fún òmìnira orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kúrò lọ́wọ́ àwọn òyìnbó Gẹ̀ẹ́sì àmúnisìn láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1944 sí ọdún 1966. [1].

National Council of Nigeria and the Cameroons
ChairmanHerbert Macaulay
Akọ̀wé ÀgbàNnamdi Azikiwe
Ìdásílẹ̀1944 (1944)
Ìtúká16 Oṣù Kínní 1966 (1966-01-16)
IbùjúkòóLagos
Ọ̀rọ̀àbáBig tent
Nigerian nationalism
Social justice
Ipò olóṣèlúCentre
Ìṣèlú ilẹ̀ Nigeria

Ìpìlẹ̀ ẹgbẹ́ náà

àtúnṣe

Ẹgbẹ́ ìṣèlú National Council of Nigeria and the Cameroons ni ó jẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú tí ó tàn dé apá Cameroon ní nkan bí ọdún 1945 nígbà náà ṣáájú kí ó tó di ilẹ̀ olómìnira. Ilẹ̀ Kamẹrúùnú ni ó jẹ́ ìlúẹ̀ tí ó wà ní abẹ́ ìṣàkóso àwọn àmúnisìn Germany. Àjọ United Nations ti gba ilẹ̀ Cameroon kúrò lábẹ́ ìṣàkóso Germany ṣáájú kí wọ́n tó ja ogun agbáyé kínní pẹ̀lú ilẹ̀ Germany tí ó jẹ́ pẹpẹ agbára agbáyé nígbà náà. Àjọ UN wá pín àwọn ilẹ̀ bí Cameroon sábẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè míràn tí wọ́n jagun àjàṣẹ́tẹ̀ lórí ilẹ̀ Germany kí Won ma ṣakóso wọn látàrí ìfọkantán tí àjọ UN ní wi àwọn ìlú náà. Wọ́n fa ilẹ̀ Cameroon lé ilẹ̀ ọba Gẹ̀ẹ́sì àti Faranse lọ́wọ́. Lásìkò yí, ilẹ̀ Cameroon méjì ni ó wà lábẹ́ ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì. Nígbà tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ati akitiyan ìgbòmìnira lọ́wó àwọn àmúnisìn Gẹ̀ẹ́sì ní ọdún 1960, wọ́n pe àwọn olùgbé ilẹ̀ Cameroon láti mọ̀ ibi tí wọ́n fẹ́ tẹ̀ sí, bóyá wọ́n yóò darapọ̀ mọ́ Nàìjíríà láti jìjà òmìnira tàbí kí wọ́n wà lábẹ́ ìṣàkóso àwọn Faranse. Àwọn olùgbé Cameroon tí wọ́n wà ní apá gúsù ilẹ̀ Cameroon bá àwọn Faranse lọ nígbà tí àwọn tí wọ́n wà ní apá àríwá Cameroon bá ilẹ̀ Nàìjíríà tí òun náà wà ní abẹ́ akóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ. Báyí ni wọ́n ṣe da ẹgbẹ́ NCNC kalẹ̀ ní ọdún 1944 láti ọwọ́ alàgbà [2] by Herbert Macaulay. Mcauley ni ó kọ́kọ́ jẹ́ ààrẹ akọ́kọ́ tí Nnamdi Azikiwe sì jẹ́ akọ̀wé akọ́kọ́ fún ẹgbẹ́ náà. O. E. Udofia, Nigerian Political Parties: Ẹgbẹ́ ìṣèlú NCNC ní àwọn ẹlẹ́gbẹ́-jẹgbẹ́ tí wọ́n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ yii láti sọ ọ́ di ẹgbẹ́ ìṣèlú gidi. Ẹgbẹ́ NCNC lásìkò yí jẹ́ ẹgbẹ́ tí ṣetán láti bójútó ìgbòmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn aláwọ̀ funfun àmúnisìn. Ẹgbẹ́ náà gba àwọn ẹgbẹ́ mìíràn bíi ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn, ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ ati ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́. Lẹ́yìn èyí ni Dr. Nnamdi Azikiwe di ààrẹ ẹlẹ́keji nígbà tí<ref name=":1" > Dr. M.I. Okpara, di Ààrẹ ẹlẹ́kẹta lẹ́yìn náà. Alagbaa Dr. Azikiwe ni ó kọ́kọ́ di Ààrẹ àdìbòyàn akọọ́kọ́ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ẹgbẹ́ ìṣèlú NCNC ni a lè pè ní ẹgbẹ́ ìṣèlú kẹta tó lààmì-laaka ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà náà lẹ́yìn ẹgbẹ́ ìṣèlú Nigerian National Democratic Party ati ẹgbẹ́ ìṣèlú Nigerian Youth Movement tí olóyè Eyo Ita ẹni tí ó jẹ́ igbákejì Ààrẹ ẹgbẹ́ NCNC tẹ́lẹ̀ kí ó tó kúrò níbẹ̀ lọ da ẹgbẹ́ ìṣèlú tìrẹẹ̀ tí ó pe ní National Independence Party.Àwọn ẹ̀yà Igbo ni wọ́n ni ẹgbẹ́ ìṣèlú NCNC .[1]


Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Lloyd, Peter C. (1955). "The Development of Political Parties in Western Nigeria" (in en). American Political Science Review 49 (3): 693–707. doi:10.2307/1951433. ISSN 0003-0554. JSTOR 1951433. https://www.cambridge.org/core/product/identifier/S0003055400066314/type/journal_article. 
  2. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Ilega