National Institute for Policy and Strategic Studies, Kuru
National Institute for Policy and Strategic Studies (NIPSS) ní ìlú Kuru, ní orílẹ̀-èdè Naijiria tí a dá sílẹ̀ ní ọdún 1979, jẹ́ àjọ tó ń rí sí ṣíṣe òfin fún àwọn olùdarí, olórí àwọn ilé-iṣẹ́ àdáni, àwọn olórí ogun, àti àwọn òṣìṣẹ́ ìlú nípò kékeré àti ipò ńlá.[1] Ọ̀pọ̀ àwọn ìgbìmọ̀ aṣòfin etò ní orílẹ̀-èdè Naijiria ti gba ẹ̀kọ́ ní NIPSS.[2] Major General Ogundeko ni olùdarí gbogboogbo àkọ́kọ́ tí NIPSS. Ọ̀jọ̀gbọ́n Tijani Muhammad-Bande (OFR) ni olùdarí gbogboogbo ti NIPSS lọ́lọ́lọ́wọ́. Àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn tó ti gbẹ̀kọ́ ní ilé-ìwé yìí ni; General Ibrahim Babangida, tí ó fìgbà kan rí jẹ́ olóri ìlú Naijiria lábẹ́ ìjọba ológun, Comrade Ajayi Olusegun, tí ó ti fìgbà kan rí jẹ́ olùdarí gbogboogbo ti NIPSS àti Mallam Nuhu Ribadu, tí ó jẹ́ alòdì sí ìwà ìbàjẹ́ nílùú.
Àwọn akẹ́kọ̀ó tó gboyè tó sì ti lààmìlaaka
àtúnṣeDíẹ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ti gboyè ní ilé-ẹ̀kọ́ yìí tó sì ti lààmìlaaka ni;
- Afakriya Gadzama, tí ó fìgbà kan rí jẹ́ olùdarí gbogboogbo ti State Security Service
- Ibrahim Babangida, tí ó fìgbà kan rí jẹ́ olóri ìlú Naijiria lábẹ́ ìjọba ológun
- Ita Ekpeyong, tí ó fìgbà kan rí jẹ́ olùdarí gbogboogbo ti State Security Service
- Lawal Musa Daura, tí oh jẹ́ adelé fún olùdarí gbogboogbo fún State Security Service
- Nuhu Ribadu, tí ó jẹ́ alága ti Economic and Financial Crimes Commission
- Tunji Olurin, olóri Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà kan rí lábẹ́ ìjọba ológun
- Victor Malu, olóyè àwọn ìjọba ológun nígbà kan rí
- Mohammed Badaru Abubakar, gómínà ti Ìpínlẹ̀ Jígàwà.
- Mohammed Dikko Abubakar, Inspector General of Police (Nigeria) IGP ìgbà kan rí
- Aminu Adisa Logun, adarí àwọn òṣìṣẹ́ ti Ipinle Kwara
- Porbeni Festus Bikepre ajagunfẹ̀yìtì ti àwọn ológun òfurufu ní Nàìjíríà
- Emmanuel Osarunwese Ugowe, AIG àwọn ọlọ́pàá nígbà kan rí
- Onuzulike Daniel Okonkwo, olùdarí Federal Ministry of Communications nígbà kan rí
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Crippled Giant: Nigeria since Independence. E.E. Osaghae, C. Hurst & Co. Publishers, 1998, ISBN 1-85065-350-X
- ↑ Foreign Policy Decision-Making in Nigeria. Ufot Bassey Inamete. Published by Susquehanna University Press, 2001, ISBN 1-57591-048-9