National Mirror
National Mirror jẹ́ ìwé-ìròyìn ojoojúmọ́ lórílẹ̀-èdè Nigeria.[1] Ọmọba Emeka Obasi ní ó dá ìwé-ìròyìn National Mirror sílẹ̀ lọ́dún 2006. Lára àwọn abala ìwé-ìròyìn náà ni Daily Mirror, Saturday Mirror àti Sunday Mirror.[2]. Nígbà tí ó di ọdún 2008, Agbẹjọ́rò Jimoh Ibrahim ra ìpín-ìdókòwò ilé-isé National Mirror pátápátá.[3] Lọ́jọ́ karùn-ún, oṣù karùn-ún ọdún 2010, ilé-iṣẹ́ Global Media Mirror Limited, tí ó ń sàtẹ̀jáde National Mirror, ra ilé-iṣẹ́ Newswatch Communications Limited, tí ó ń ṣàtẹ̀jáde ìwé-ìròyìn olóṣooṣù Newswatch.[4]
Type | Daily newspaper |
---|---|
Publisher | Global Media Mirror Limited |
Official website | http://www.nationalmirroronline.net/ |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ John O. Ogbor (2009). Entrepreneurship in Sub-Saharan Africa: A strategic management perspective. AuthorHouse. p. 252. ISBN 1-4389-3392-4. https://books.google.com/books?id=GP6K_cXxZHYC&pg=PA252.
- ↑ "National Mirror". Country Codes. Archived from the original on 14 August 2011. Retrieved 2011-05-14.
- ↑ "imoh Ibrahim Buys National Mirror". Daily Champion. 27 August 2008. Retrieved 2011-05-14.
- ↑ "National Mirror publisher takes over Newswatch". Nigerian Tribune. 6 May 2011. Archived from the original on 29 March 2012. Retrieved 14 May 2011. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)