Ìwé ìròyìn Nigerian Tribune jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé-ìròyìn olójoojúmọ́ tí wọ́n ń tẹ̀ jáde láti ilú Ìbàdàn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Alàgbà Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ni ó dá ìwé ìròyìn yí sílẹ̀ ní ọdún 1949, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn tí ó pẹ́ jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ní àsìkò àmúnisìn, ìwé ìròyìn yí ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀dùn ati alágbàwí fún àwọn àlàkalẹ̀ ètò tí Alàgbà Awólọ́wọ̀ ní lọ́kàn. Ìwé ìròyìn yí tún jẹ́ olùgbèjà fún àwọn ọmọ káàárọ̀-oòjíire (Yorùbá) lásìkò náà tí gbogbo àwọn ẹ̀yà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń palẹ̀mọ́ fún Ìgbómìnira lọ́wọ́ àwọn àmúnisìn.[2] Láti ìgbà tí a ti gba òmìnira ní ọdún 1960 títí di ọdún 1990, gbogbo ìwé ìròyìn olójoojúmọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà ni ó jẹ́ ti ìjọba àyafi àwọn ìwé ìròyìn ti aládàáni bíi: Nigerian Tribune, The Punch, Vanguard ati Guardian ni wọ́n ń tú àsírí àbòsí ìjọba ati àwọn aládàáni gbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìjọba gbójú agan sí wọn. [3] Ààrẹ apàṣẹ wàá ìjọba ológun Ibrahim Babangida fìgbà kan sọ tẹ́lẹ̀ rí wípé: " ìwé ìròyìn tí òun lè kà tí òun yóò sì mú ní ọ̀kúnkúndùn ni ìwé ìròyìn Nigerian Tribune ".[4] Ìwé tí alàgbà Femi Okunrounmu kọ tí ó pè ní Leadership Failure and Nigeria's Fading Hopes tí ó gbé jáde láàrín ọdún 2004 sí 2009, ní ó kún fún àwọn àyọkà àpilẹ̀kọ ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti inú ìwé ìròyìn Nigerian Tribune. Olóòtú agbà ìwé ìròyìn náà tí ó tún jẹ́ alẹ́nu-lọ́rọ̀ láwùjọ kọminú lórí bí ìwà ìmọ̀taraẹni-nìkan ati ìwà àjẹbánu ṣe gogò láàrín àwọn àgbà-ọ̀jẹ̀ olóṣèlú orílẹ̀-èdè yí tí kò sì sí ẹni tó lè dá wọn lẹ́kun rẹ̀ ṣe ń pagidínà ìlọsíwájú àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yí àti gbogbo aláwọ̀ dúdú lápapọ̀.[5] Ní inú oṣù Kejìlá ọdún 2008, Alàgbà Ṣẹ́gun Ọlátúnjí tí ó jẹ́ adarí àgbà ati olóòtú àgbà fún iwé ìròyìn Nigerian Tribune kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ tí olóòtú míràn Rauf Abíọ́dún náà tún kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ látàrí ìṣípopadà tí ó ń bá àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ ìeé ìròyìn náà. Adarí àgbà yán yán Abilékọ HID Awólọ́wọ̀ tí ó tún jẹ́ Ààrẹ pátá pátá fún gbogbo òsìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn Nigerian Tribune African Newspapper Nigerian Ltd, yan Sam Adesua gẹ́gẹ́ bí Alákòóso àgbà àti olóòtú àgbà ìwé ìròyìn yí bákan náà, nígbà tí wọ́n yàn Edward Dickson sí ipò olóòtú lásán. Ìdí abájọ tí àtúntò yí ṣe wáyé ni wípé wọ́n fẹ́ fẹ ìwé ìròyìn náà lójú siwájú si ju bí ó ti wà tẹ́lẹ̀ lọ kí wọ́n sì tún lè máa gbé ìròyìn wọn jáde lọ́nà ìgbàlódé gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwé ìròyìn bíi: The Westerner, The Nation and Nigerian Compass ti ń ṣe. [6] Ní inú oṣù kọkànlá ọdún 2012, ìgbìmọ̀ alákòóso ilé-iṣẹ́ ìròyìn náà panupọ̀ yan Edward Dickson sí ipò Alákòóso àgbà, wọ́n sì fi Debo Abdulai ṣe Olóòtú àgbà, wọ́n fi Ṣínà Ọládẹ̀ìndé ṣe olóòtú fún àwọn ìròyìn ọjọ́ ìsinmin nígbà tí wọ́n fi Lasisi Ọlágúnjú ṣe olóòtú fún àwọn ìròyìn ọjọọjọ́ ẹti ìwé ìròyìn Nigerian Tribune.[citation needed]

Nigerian Tribune
Nigerian Tribune logo.png
TypeDaily newspaper
PublisherAfrican Newspapers of Nigeria Ltd
Editor-in-chiefEdward Dickson
Founded1949
LanguageEnglish
HeadquartersIbadan
Official websitehttp://www.tribuneonlineng.com/

Àwọn ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "About Us". Nigerian Tribune. Archived from the original on 2011-05-20. Retrieved 2011-05-11.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Awolowo, Obafemi (1909-1987) 2004". Encyclopedia of African History. London: Routledge. http://www.credoreference.com/entry/routafricanhistory/awolowo_obafemi_1909_1987. Retrieved 13 May 2011. 
  3. Sriramesh, Krishnamurthy; Verčič, Dejan (2009). The global public relations handbook: theory, research, and practice. Taylor & Francis. ISBN 978-0-415-99514-6. https://books.google.com/books?id=ZbxYDUul-UkC&pg=PA324. 
  4. McNezer Fasehun (29 June 2009). "Nigerian Tribune - a Salute to Awo's Newspapernomics". Daily Independent. Retrieved 13 May 2011. 
  5. Femi Okurounmu (2010). Leadership Failure and Nigeria's Fading Hopes: Being Excerpts from Patriotic Punches a Weekly Column in the Nigerian Tribune from 2004 - 2009. AuthorHouse. ISBN 978-1-4490-8409-7. 
  6. "MEDIA: CHANGE OF BATON AT NIGERIAN TRIBUNE". NBF. 10 January 2009. Retrieved 2011-05-13. 

Àdàkọ:Major Nigerian newspapers