Ndagi Abdullahi jẹ́ olùkọ́àgbà ní Nàìjíríà, òǹkọ̀wé, àti Alága (CEO) KinNupe Newspaper. Abdullahi jẹ́ ọmọ Nupe ní èdá àti pé ó ti kópa nínú kíkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àròkọ nípa àṣà àti àgbékalẹ̀ ayé àwọn Nupé.

Ọnà ìgbé ayé

àtúnṣe

Wón bí Ndagi Abdullahi ní ọjọ́ kẹjọ, Oṣù Kejìlá, ọdún 1972 ní Ṣọ̀kọ́tọ́, sí àwọn òbí tó jẹ́ ọmọ Nupe láti Bida. Ó gba ẹ̀kọ́ ilé-ékó́ ìpìlẹ̀ àti girama rẹ̀ ní Minna, Ìpínlẹ̀ Niger, lẹ́yìn náà ló tẹ̀síwájú sí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ní òkèèrè.[1]

Abdullahi, tí ó kọ́kọ́ kọ́ ìṣẹ́ dókítà, ṣe ayípadà sí ìṣẹ́ òǹkọ̀wé. Ó ti lo tó ọ̀gbọ́n ọdún nínú ìkọ̀wé, ìwádìí, àti kíkọ́ ní gbogbo àbùjá àwọn ìtàn ìran àti àṣà Nupe. Ó ti kọ́ àwọn ìwé tó lé ní ọgọ́rùn ún mẹ́tà (300), púpọ̀ nínú wọn ni wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 2021, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìtàn Nupé, èdè, àti bẹ̀bẹ̀lọ́.[1]

Ó jẹ́ Alága Nupe Cultural and Resource Centre (NCRC), ilé-iṣẹ́ ìwádìí Nupe gíga kan tó wà ní Ìpínlẹ̀ Niger, tí Alhaji Yahaya Abubakar, tí ó jẹ́ Etsu kẹtàlá, dá sílẹ̀.[2]

Ní ọdún 2021, ọbá aláṣẹ Alhaji Dr. Yahaya Abubakar, tí ó jẹ́ Etsu Nupe fí Abdullahi jẹ́ Amana Nupe.[3]

Nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe
  • (2021). Aminu: The African Ancestry of Prophet Muhammad.[4]
  • (2021). Oduduwa Was Nupe: How the Yoruba People Originated from Nupe.[5]
  • (2021). Nupe Zam: Pre-Colonial Histories of Nupe Tribal Sections.[6]
  • (2021). Gbarazhi: Histories of Some Emirates and Towns in KinNupe.[7]
  • (2021). Edu State: The Case of a Homeland State for the Nupe Nation[8]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 "Ndagi Abdullahi". Minna City of Literature. 22 September 2023. 
  2. Oji Onoko (30 March 2014). "Nigeria: Nupe as Epicentre of Nigerian Arts". All Africa Stories. 
  3. "Turbaning Ceremony Of Eminent Persons At Bida Emirate In Niger State". yemiosinbajo.ng. 4 December 2021. 
  4. Ndagi, Abdullahi (2021). Aminu: The African Ancestry of Prophet Muhammad. KDP Print US. ISBN 979-85163869-9-2. 
  5. Ndagi, Abdullahi (2021). Oduduwa Was Nupe: How the Yoruba People Originated from Nupe. KDP Print US. ISBN 979-85027219-8-1. 
  6. Ndagi, Abdullahi (2021). Nupe Zam: Pre-Colonial Histories of Nupe Tribal Sections. KDP Print US. ISBN 979-85051652-9-4. 
  7. Ndagi, Abdullahi (2021). Gbarazhi: Histories of Some Emirates and Towns in KinNupe. KDP Print US. ISBN 979-85047451-8-3. 
  8. Ndagi, Abdullahi (2021). Edu State: The Case of a Homeland State for the Nupe Nation. KDP Print US. ISBN 979-85037320-8-5.