Nizamuddin Asir Adrawi
Nizāmuddīn Asīr Adrawi (tí a sì mọ̀ sí Asīr Adrawi; láti ọdún 1926 títí dé ọjọ́ ogún oṣù karùn-ún ọdún 2021) jẹ́ onímọ̀ ìjìnlè mùsùlùmí ti ilẹ̀ India, ò sí tún jẹ́ òǹkọ̀wé ìtàn nípa ìgbésí ayé ẹni àti òǹkọ̀wé nínú èdè Urdu. Ó ṣe ìdásílẹ̀ Madrassa Darus Salam ni ìlú Adari, ó sì tún jẹ́ adarí Jamiat Ulama-e-Hind ní Lucknow láti ọdún 1974 títí dé ọdún 1978.
Mawlānā Nizāmuddīn Asīr Adrawi | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1926 Adari, United Provinces, British India (today Mau district, Uttar Pradesh, India) |
Aláìsí | 20 May 2021 Adari, Uttar Pradesh, India | (ọmọ ọdún 94–95)
Iléẹ̀kọ́ gíga | |
Notable work | Tarikh Jamiat Ulema-e-Hind|Tehreek-e-Azadi aur Musalman| Karwan-e-Rafta |
Movement | Deobandi |
Ìtàn ìgbésíayé
àtúnṣeNizāmuddīn Asīr Adrawi (tí a sì mọ̀ sí Asīr Adrawi; láti ọdún 1926 títí dé ọjọ́ ogún oṣù karùn-ún ọdún 2020) jẹ́ onímọ̀ ìjìnlè mùsùlùmí ti ilẹ̀ India, ò sí tún jẹ́ òǹkọ̀wé ìtàn nípa ìgbésí ayé ẹni àti òǹkọ̀wé nínú èdè Urdu. Ó ṣe ìdásílẹ̀ Madrassa Darus Salam ni Adari tí ó ti jẹ́ adarí ipò Jamiat Ulama-e-Hind ní Lucknow láti ọdún 1974 títí dé ọdún 1978.
Asir fìgbà kan jẹ́ olóòtú Tarjuman olóṣoosù mẹ́ta, ó sì kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé fún un. Òun tún ni òǹkọ̀wé Al-Jamiat ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti Al-Jamiat ti Jamiat Ulama-e-Hind olójoojúmọ́. Ó kọ àwọn ìtàn kéékèèké àti àwọn ìtàn akọni bíi Itna, Do LāsheiN, Nashīb-o-Farāz and Aetirāf-e-Shikast.
Asir kú ní ọjọ́ ogún, oṣù karùn-ún, ọdún 2021 ní Adari, Mau, ní Uttar Pradesh. Arshad Madani fi ìkẹ́dùn rẹ̀ hàn, ó sì ní pé "ikú Asir Adrawi jẹ́ ìpàdánù tí ò ṣe é dá padà."[1]
Iṣẹ́ lítíreṣọ̀ rẹ́
àtúnṣeAsir kọ ìtàn ìgbésíayé àwọn ènìyàn bíi Muhammad Qasim Nanautawi, Mahmud Hasan Deobandi, Imamuddin Punjabi, Rahmatullah Kairanawi, Rashid Ahmad Gangohi àti Hussain Ahmed Madani. Ó ṣe àgékùrú apá mẹ́rẹ̀rin Tarikh-e-Islam tí Muinuddin Ahmad Nadwi kọ sí apá márùn-ún tó kéré. Ìwé rẹ̀ Tahrik-i-azadi aur Musalman, wà lára àwọn àkóónú iṣẹ́ fún Darul Uloom Deoband àti àwọn ilé-ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Islam lóríṣiríṣi.
A
Afkār-e-Aalam
- Afkār-e-Aalam
- Dārulʻulūm Devband, iḥyā-yi Islām kī ʻaẓīm taḥrīk
- Fun asma-ur-Rijal
- Maʼās̲ir-i Shaik̲h̲ulislām (Biography of Hussain Ahmed Madani)
- Tafāsīr mai Isrā'īli Riwāyāt
- Tārīkh Jamiat Ulema-e-Hind
- Tārīkh-e-Tabri ka tehqīqi jayzah
- Urdu sharah Dīvān-i Mutanabbī
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "مولانا نظام الدین اسیر ادروی کا انتقال ناقابلِ تلافی خسارہ:مولانا ارشدمدنی" (in ur). Qindeel Online. 20 May 2021. https://qindeelonline.com/moulana-nizamuddin-aseer-adrawi-ka-inteqal-na-qabile-talafi/.
- ↑ Nayab Hasan. "مولانا نظام الدین اسیر ادروی:اسیرِ علم و قلم". Qindeel Online. https://qindeelonline.com/maulana-nizam-aseer-adrawi-aseere-elmu-qalam/.
- ↑ Syed Inaamul Hasan (21 May 2021). "مولانا اسیر ادروی: ایک تعارف" (in ur). Baseerat Online. https://www.baseeratonline.com/146963.
- ↑ "Books authored by Maulana Nizamuddin Asir Adrawi". viaf.org. Virtual International Authority File. Retrieved 27 May 2020.