Nneka

Akọrin obìnrin
(Àtúnjúwe láti Nneka (singer))

Nneka Lucia Egbunna, a bii ni ọjọ́ kẹrìnlelogun, Ọdún 1980. O jẹ olorin àdàlú ilẹ Nàìjíríà àti jamaní Hip/Soul. Á máa ṣe àkọọlè irúfẹ́ orin yìí àti kíkọ orin náà

Nneka
At Cargo, London, 2009
At Cargo, London, 2009
Background information
Orúkọ àbísọNneka Lucia Egbuna
Ọjọ́ìbí24 Oṣù Kejìlá 1980 (1980-12-24) (ọmọ ọdún 43)
Ìbẹ̀rẹ̀Warri, Nigeria
Irú orinSoul, Hip hop, R&B, Afrobeat, Reggae, Jangle pop
Occupation(s)Singer, Songwriter
Instrumentsguitar, drum
Years active2004-present
LabelsYo Mama's Recording Co./Epic Records/Decon Records


Ìgbé- Ayé Ẹ

àtúnṣe

Nneka tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Anambra tíí ṣe ẹ̀yà ìgbò tí ìyá a rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Jamani. A bí Nneka bẹ́ẹ̀ la tọ dàgbà nílùú Warri tíí ṣe agbègbè Del,ta lórílẹ̀ èdè Naìjíríà. Ó lọ ilé –ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti ilé iṣé awórin-túnrin-rọ nípìnlẹ́ Delta, Ó tẹ́ síwájú nípa lílọ ile-ìwé Girama ti ilé –iṣẹ́ ifọpo orilẹ-èdè Nàìjíríà . Nneka gba ìmọ̀ orin kíkọ́ lóòórọ̀ ayé ẹ̀ nílé ìwé ẹ̀ àti nínú ẹgbẹ́ akọrin ti ilé ìjọsìn. Nígbà tí ó tàtaré bọ́ sí orílẹ̀ èdè Jámánì nílùú Hamburg lẹ́ni ọmọ ọdún méjìdínlógún, ó mú orin gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ajẹ́ pẹ̀lú ìkẹ́kọ̀ọ́ gboyé nínú ìmọ̀ àṣà àti ìṣe ènìyàn. Ní báyìí, orílẹ́-èdè Nàìjíríà àti Hamburg ni ó fi ṣe ibùgbé.

Orin Gẹ́gẹ́ bí Iṣẹ́ Ajé

àtúnṣe

Làti ọdún 2003 ni Nneka ti ń ṣíṣé pọ̀ pẹlu alátò orin hip-hop tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ DJ Farhot tíí tún ṣe agbórin jáde tí ó fi ilẹ̀ Hamburg ṣe ibùgbé. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀ –wẹ́wẹ́ olórin ó kọ́kọ́ jẹ it wọ́gbà àwọn ènìyàn ní ọdún 2004 nígbà tí ó kópa nínú ìṣíde ijó-jíjó kan pẹ̀lúu gbajúgbajà akọrin Reggae tí ń jẹ́ Ṣean Paul nílùú Hamburg. Lẹ́yìn tí orúkọ rẹ̀ ti tàn kálé-káko Nneka ri àǹfàní àti kà àwo rẹ̀ àkọ́kọ́ sílẹ̀ .Lẹ́yin tí ó gbé àwo náà tí ó là á jáde tí ó pe àkọ́lé e rẹ̀ ni “The Uncomfortable Truth” pẹ̀lú ilé iṣẹ agbó rinjáde Yo Mama’s ,níbi ìgbé –kiri orin ẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ̀ ló ti kọrin pẹ̀lú atrice Bart Williams nínú oṣù kẹrin, Odún 2005, ní àwọn ìlú bíi Germany, Austria àti Switzerland.

Ó parí àkáálẹ̀ orin rẹ̀ àkọ́kọ́ ni àsìkò ọ̀gbẹlẹ̀ (Ẹrùn) tí ó pe àkọ́lé ẹ̀ ni “ Victim of Truth”, títà àwo náà wáyé ni orílẹ̀-èdè Jamáni, Gẹ̀ẹ́sì Faranse, Netherland, Nàìjíríà àti Japan.

Àkójọpọ̀ láti ẹ̀ka agbóhùn sáfẹ́fẹ́ pàápàá jùlọ UK’a Sunday Times pè ní “ọdun tí a fojú fo aṣemáṣe àwo orin jùlọ” tí wọn sì gbe yèwò sí ti àwo orin Launyn Hill tí ó kún fún ọpọlọpọ aṣemáṣe. Lẹ́yìn tí àwo náà bóde pàdé, ó ṣínà ìgbé –iri àti ìkópa nínú ayẹyẹ bí i chiemsee, Reggae Summer, Haarlem (Beuridgings Pop), Den Haag (park pop) àti Saint-Brienc (Art Rock festival) bákan náà ni ni àwọn bíi La Maroquinerie àti New Moring ní ìlú paris, Tivel ní Utrecht, Paradiso nì Amsterdam àti Cargo òun Ulu nílùú London. Bákan náà ló ti ran àwọn akọrin mìràn lọ́ẁ bíi Femi –kuti, Bilai seed àti Gnarls Barkley.

Ní oṣu kejì ọdún 2008,ó gbé àwo rẹ̀ kejì jàde tí ó pè ní "No Longer at Ease”. Ó yọ àkọlé àwo nàá jáde làti inú ìwé ìtàn (Chinua Achebe tí ìwé náà sì fi òye inú orin náà hàn. Ọ̀pọ̀ orin inú àwo náà ni ó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ –òṣèlú, tí ó ń sọ nípa ìṣòro àwọn èyà Gúsù – úsù ilẹ̀ yìí àti àwọn ìwá ọbaàyéjẹ́ mìíràn tí ń wáyé l’ágbègbè abínibí Nneka. No longer at ease” jẹ́ èyí tó so òṣèlú pọ̀ mọ́ ara ẹni nípa pé ó jẹ́ àwònú bọ̀nú orin Soul, hip-hop a[ti Reggae.orin tí ó gbajúmọ̀ jù nínú àwo náà “heartbeat ‘ jẹ́ àdákọ rẹ̀ akọkọ tí ó wọ ikọ orin ilẹ̀ Jamaní aláàdọ́ta àkọ́kọ́,Ní oṣù kẹsan-an 2009 orin náà wọ ikọ orin àdákọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ipò ogún.

Ni oṣu tí ó tẹ̀lẹ́ e, onírúurú ìrìn àjò orin kíkọ sílẹ́ Faransé ítàló, àti orílẹ̀ èdè Potogí ni ó wáyé, ó tún ṣe alátílẹyìn fún Lenny Kravitz nínú ìrìn àjò orin rẹ̀ sílẹ̀ Faransé ni oṣù kẹrin ọdún 2009. Nneka ẹni tí a ti kà mọ àwọn tí ó ṣe é ṣe kí ó gba àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bi ọ̀ǹkọrin nínú ikọ̀ oriṣi mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ilé–iṣẹ́ amohun-máwòran channel o’ṣe agbatẹnu rẹ̀ àmọ́ tí ó jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bí ọ̀ṣèré akọrin aláwọ̀dúdú tí ó dárajú nínú ìdíje MOBO l’ọ]dún 2009.

Ní ìparí ọdún 2009. Beyond Race magazine’s kà mọ́ ikọ̀ aláàdọ́ta àwọn akọrin tí ó ń dide bọ̀ leyìí tí ó mú kí wọn ó gbé àwòrán rẹ̀ sójú ewé àkọ́kọ́ ìwé àtẹ̀jáde kan kan pẹ̀lú àwọn mììran biúi Bodega Girls àti S. cole Bákan náà ni wọ́n ni ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lúu Magasíìnì náà.

Ní oṣù kọkànlá ọdún 2009, Nneka ṣe ìpàtẹ orin rẹ̀ àkọ́kọ́ lọ sọrílẹ̀ èdè USA nibi tí ó ti ṣeré nilùú New York, Vienna, Washington D.C., Boston, Philadelphia, Los Angeles àti San Francisco.

Bákan, náà ni ó jẹ́ ẹni àyẹ́sí pàtàkì níbi ayẹyẹ ‘the Roots Jam, àwo r2 àkọ́kọ́ lórílẹ̀ èdè Améríkà tí ó pé ní ‘ concrete Jungle” ni yóò jáde níjọ́ kejì oṣù kejì ọdún, 2010. Ọ̀kan nínú orin inú àwo rẹ̀ tí ó pé ní “kangpe” ni ó ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ átẹ́wọ́gbà EA sports FIFA 2010 gẹ́gẹ́ bíi orin abẹ́nú fún eré bọ́ọ̀lù orí ẹ̀rọ amóhùn –máwòrán.

Ní oṣù kìíní ọdún 2010, Nneka Farahàn lórí ètò tí a pè ní ‘Late show’ pẹ̀lúu David Letterman ní ìlú New York kí ó tó lóre ọ̀fẹ́ àti gbé rẹ̀ kiri ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ó gbà láti rìrìn –àjò orin kík̀ pẹ̀lúu Nas àti Damian Marley láti le é báwọn gbé àwo orin ‘Distant Relativs “ larugẹ. Ó ti ṣe àtúnkọ orin rẹ̀ tí ó gbajúmọ̀ jù u ni ̂”Heartbeat “ pẹ̀lu Nas tí yóò si di kíkó jáde laipẹ jọjọ. Ó tún gbà láti kópa nínú ayeye ìpàt orin tí a pè ní “Lilith Fair Concert" (2010) pẹ̀lú àwọn aḱrin bí i Tegan àti Sara, Sarah Mcachlan. Kelly Clarkson Jill scott, Erykah Badu, Corrine Barley Rae, Mary J Blige, Rihanna, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí akópa. Yọ́ó tun ṣere bákan náà ni ashington, Raleigh àti Charlotte nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Bẹ́ẹ̀ ló tún kọ orin tí ó fi sorí ìdije b̀ọ́ọ̀lù àgbáyé tí a pé ní 2010 ifa world cup tí ó wáyé nílẹ̀ Gúsù Afíríkà (south Africa) tí ó pé ní “ Viva Africa “. Ó ṣe èyí nítórí tí ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ ìdíje náà nilé aláwọ̀údú.

Ó gba àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí akọrin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó dára júlo níbi ayẹyẹ Nigeria Entertainment Awards 2010 tí ó wáyé ti ó wáyé nílùú New York Lorílẹ̀ èdè Amẹríkà.

Ọ̀nà Ìṣowọ́ Kọrin

àtúnṣe

Bótrilẹ̀ jẹ́ pè Nneka n kọrin ju Ráàpù lọ, ó ní orin hip-hop bi òún fi bẹ̀rẹ̀, òun sí ni óń fún òhun ní ìmísí nígbà tí ó si dárúkọ àwọn olórin bíi Fẹlá-kuti àti Bob Marley, kò ṣàì dárúkọ àwọn olórin Ráàpù ìgbàlódé bí i Mos Def, Talib Kweli àti Larry Hill gẹ̀gẹ̀ bí àwọn ti orin wọ́ nípa lórí ìrìn àjò òhun nínú orin kíkọ. Àwọn orin rẹ̀ a máa ní òye nípa ìtàn àti ayé e rẹ̀ lórílẹ̀ Nàìjíríà àti ìgba rẹ̀ nílùu àwọn aláwọ́ -funfun. Àwọn orin rẹ̀ a tún má a sọ nípa ìjẹgàba àwọn ènìyan péréte lórí ọ̀rọ̀ ajẹ́,ìṣẹ́ àti ogun tí ó sí máa ń kún fún ẹkó ìwá áti ẹsẹ bíbélì nígbà ti àwọn aláwìyè kan nídi iṣẹ́ orin a máa fiwé Erykah Badu, Neneh Cherry àti Floety.

Ìpòngbẹ

àtúnṣe

Orin rẹ̀ tí ó pé ní “Heartbeat” jẹ́ èyi tí ṣarah Matos (Magarida) àti Lourenco Ortiago (Rui) ti kO lọ́pọ̀ ìgbà nínú sáà keje ti orin ilẹ̀ Potogí tí wọn ń pè ní |Moranges comAcucar”.

Awon awo orin to te jade

àtúnṣe
  • 2005: Victim of Truth
  • 2008: No Longer at Ease
  • 2011: Soul Is Heavy

Compilations

àtúnṣe
  • 2005: The Uncomfortable Truth
  • 2005: The Uncomfortable Truth
  • 2006: Beautiful
  • 2006: God of Mercy
  • 2007: Africans
  • 2008: Heartbeat #9 Portugal, #20 UK, #34 Austria, # 49 Germany
  • 2008: Walking
  • 2009: Kangpe

Soundtracks

àtúnṣe
  • 2011: "Beat the World" (Expresse Yourself)