Ọba Ìséyìn
ORÌKÌ OBA ÌSÉYÌN
àtúnṣeOBA ADÉYERÍ LÁTI ENU (PA) ÁLÍMÌ AJÉYEMÍ ILÉ ALUSÈKÈRÈ NÍ ÌLÚ ÒYÓ
Adéyerí omo Alájogun
Adéyerí omo wúràólá
Adéyerí omo wúràólá
Ìyàndá a-báni-sòrò-má-tannìje
Adéyerí omo Alájogun
À n bó’bo, òbó hun
Adéyerí omo alájogun
Òbo kìkì are rè.
A à féná à ní ò jò
A féná tán
Oníkálukú n gbénu ú sá kiri
Àká baba ìrókò
Asawo lode ò febè paní
Adéyení omo Alájogun ònà ìbàdàn la ò gbodò rìn
O n káà koko
Adéyení omo Alájogun
Òjò pa kòkò rè gbìn-gbìn-gbìn
Òjò tí ì bá pa tápà
A dòtúbáté
Adéyení omo Alájogun
Elébùrú ìké
Omo Alájogun
Òbo kìkí are rè.
N ó k’aséyìn oba àrànse
Oyinbó omo Èjìdé àgbé
Gbógun léye
Àsoba jagun
Oyinlolá Oláwóore
Peranborí
Peran bofá
Oláwóore a bèyìn àrò gele-mò-gelé-mò.
Kò se é mú ròdá
Ò se é mú
Gbógunléye
Àsobajagun
Nlé Oláwóore
Baba enìkan ò gbin yánrin
Baba enìkan ò gbin gbòrò
Omo èjìdé Àgbé
Fúnra rè lóhù
Aséyìn Oba àrànse
Oyinlolá Oláwóore
A gbó onísé Oba má mà dúró
Omo èjìdé àgbé tí í gbónísé onjò
Tí í tún fìlà se ge-ge-ge
Oyinlolá
Oláwóore
Àsán-àn-jòmì-eye
Oláwóore
Ekùn-abi-làà-làà-ìjà-layà
Láwóore ekun-abi-làà-làà ìjà-layà
Agbógbe má gbóyàn
Oba Àyínde
Oyinlolá
Láwóore Àbe
Afàdàmò-ragun-jànyìn-jànyìn
Oyinlolá omo Èjìde Àgbé
Dákun má gbéná
Oba àrànse
ohinlolá
Láwóore
Nígbà tí ò sí mó
Aséyìn ò ti è parun
Oyinlolá
Oláwóore
O kan Adégbìté
Sùkú-séré Adégbìté
Omo alálè-òrun
A-jó-kí-de-ó-ró
Baba ori dagogo
Àrán kún lé
Baba odún sàrìnnàkò ààlà yìgì
Ààlà yìgì baba ò dé títí dodún
Omo afòkú sòwò
Àrèmú Arówólóyè
Àbíkú oníjànmón
Baba ládépé
N-n-gb ó gbinrin lówó òtún
Sùkú-mì-séré
Mo se bálágbède òrun ní n lurin
A-jó-kí-de-ó-ró
Baba orí dagogo, n-n-gbó gbinrin
Lówó òsì, Adégbìte
Mo se bálágbèdè-òrun ló n lurin.
A-jó-kíde-á-ró baba orí dagogo
Èmi-ò-tetè-mo-pówó-fá-gùn-má-ràjà-gún-gbe
Arówólóyè
Àbíkú oni jànmó
Baba ládépé
O dèèkínní onísé ìbàdàn dé wón lógun jà ni
Mókín ilé
Arówólóyè Oba èse
Wón ní mo kí séríkí
Mo kí Balógun
Mo kótùn-ún
Mo kósì
O dèèkejì èwèwè
Onísé ará ìbàdàn dé
Wón lógun jà ni mòkín ilé
Arówólóyè
Wón ní wón ó kí séríkí dáadáa
Wón ó kótùn-ún
Wón ó kósì ìbàdàn
O dèèketa èwèwè
Onísé ará ìbàdàn dé
Wón lógun jà ni Mòkín ilé
Arówólóyè
Oba èse
Wón lógun le fún séríkí
Ogún le fún Balógun
Ogun le fótun-ún
Ogun le fósì
Kóso kó kí e má le è kó won
A-jó-kí-dé-ó-ró
Baba orí dagogo
Sèkèrè kó ní e má le è sétè
Tètè kò pé e má le è kójèbú
Arówólóyè
Abíkú onijànmó
Baba ládépé
Járun-járun
Kó máa jáwon lo
Jósèèké jósèèké
Kó pé e má le è kójèbú
Arówólóyè
Abíkú oníjànmó
Baba ládépé
O kan Olúgbilé
Ìgbà tí ò sí mó
Aséyìn ò ti è parun
Olúgbilé
Eléwu oyè
Òmùdún kókò
Oba asàwòlòlò
Oní jànmó alátise
Olúgbilé
Aberan nílé bí ode aperin
Afàlùkò-jèjèè
Jejèé-nílé-oníjànmó
Jejèé-lóde
Olugbile tó tó baba
Láwóore re i se
Aborí esin báá-báá lónà komu
Abìrù esin tìkòtìkò
Lónà ababja
Sèrùbàwón baba Àjíà
Ológòdo ègi
Olúgbilé
Aberun nlé bí ode aperin
Rèwó-rèwó ní e má ti è rèwó mó
Ológòdo egi
Olúgbilé ni bá a bá lo
Emi ni í máa se ní wàye
Mo ní jà mo jùlo
N-n-jù-tòsun-lo
Òmùwè tí n wè lódò òsà
Kó múra kó lè wèé já
Iba mi olúgbilé aláwòye
Òmùdún kókò oba asàwòlòlò
Ìfòròwánilénwò lóri àwon òrò tó ta kókó
Ìbéère: kín ni ìtumò gbólóhùn yìí “A à féná, à ní kò jò?
Ìdáhùn: ìtumò rè ni pé nígbà ti ìnà kò ì jò ni à n dúró, tí iná bá ràn tán ènìyàn ó ho.
Ìbéèrè: kinni ìtúmò omo Alájogun.
Ìdáhùn: omo jagun jagun Ìbéèrè: kín ló fa ‘ona ìbàdàn la ò gbodò rìn?
Ìdáhùn: Nítorí pé ológun jo ni wón.
Ìbéèrè: Abèyìn àrò gelemò-gelemò nkó?
Ìdáhùn: ó jé eni tí í máa n ni eran nílé ní gbogbo ìgbà tí ó sì máa n fi í se àlejò.
Ìbéèrè: kínni ìtumò Ekùn abi làà-làà ìjà layà?
Ìdáhùn: Jagun-jagun tí ó le ni à n pè béè.
Ìbéèrè: ìdí tí e fi n pè é ni Oba àrànse?
Ìdáhùn: Onírànlówó ènìyàn ni ó n jé béè. Ó n ran ènìyàn lówó.
Ìbéèrè: Omo aláte-òrun nkó?
Ìdáhùn: Eégún baba won ni aláte-òrun tí a fi n pè é béè.
Ìbéèrè: kin ni ìtumò àbíkú oni janmo?
Ìdáhùn: E ni tí n dákú.
Ìbéèrè: kín ni ìdí tí a fi so pé ó se ori esin báá-báá Lónà kòmu?
Ìdáhùn: ìdí ni pé kòmu ni oko rè.
Ìbéèrè: òmùdún kókò a sàwòlòlò nkó?
Ìdáhùn: Oba tí ara tè ndán ni eléyìní.